Ẹ ṣé ara yín ní òṣùṣú ọwọ̀ tí ẹ bá fẹ́ borí nínú ètò ìdìbò - Buhari sí àwọn adárì APC

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ikilọ fun awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC lati ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ saaju ẹto idibo gbogboogbo, ti wọn ko ba fẹ fi idi rẹmi lọdun 2023.

Buhari ni awọn adari naa gbọdọ rii pe awọn fọwọsowọpọ lati rii pe ẹgbẹ oṣelu APC ṣe aṣeyori lọdun 2023.

O gba imọran yii nigba to ṣe abẹwo si ilu abinibi rẹ ni Daura nipinlẹ Katstina, ti o si wa ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ rẹ, Garba Shehu buwọlu lanaa.

Ninu atẹjade naa, eyi ti akọle rẹ jẹ “Lati bori eto idibo, Aarẹ Buhari pe fun isọkan ẹgbẹ oṣelu APC.” Buhari ni awọn adari ẹgbẹ gbọdọ joko papọ lati rii pe ko si ipinnya ninu ẹgbẹ naa, eyi to le ṣo okunfa lilulẹ APC ninu eto idibo ọdun to n bọ.

O tẹsiwaju pe oun yoo rii pe eto idibo lọ ri irọwọ rọsẹ lai si rogbodiyan rara.

“Eto idibo nipinlẹ Osun, Anambra, Ekiti ati Ondo ti fihan pe ijọbe fẹran alaafia.”