Báwo ní àwọn agbébọn ṣe palẹ̀mọ́ àwọn olùjọ́sìn ní Mọ́ṣáláṣí ni Ìpínlẹ̀ Katsina?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn afurasi agbebọn kan ti ṣe ikọlu si mọsalasi ni Funua, nipinlẹ Katsina.

Niṣe ni awọn agbebọn ọhun sina bolẹ fun olùjọsìn lalẹ ọjọ Satide ọsẹ to kọja, ti wọn si palẹmọ wọn nigba ti wọn kirun alẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Katsina, Isah Gambo sọ fun BBC pe imamu mọsalasi ati ọkan lara awọn olùjọsìn farapa sugbọn wọn ti kuro nile wosan lẹyin ti wọn gba itọju.

Isah ni ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu awọn ọmọ ologun orilẹede Naijiria ati awọn fijilante tí n sisẹ pọ lati dola awọn eeyan to wa ni ahamọ awọn ajinigbe.

Eeyan mẹtala ni awọn eeyan to wa ni ahamọ awọn ajinigbe bayi.

O ni awọn n gbinyanju lati ṣawari awọn eeyan naa, ki awọn sì tun fi ẹyin awọn ajinigbe naa balẹ.

#100m ni àwọn ajínigbé tó jí Ọba gbé ní Ondo ń bèèrè fún

Oloso ti Oso Ajowa-Akoko àti aworan awọn ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Family

Lẹ́yìn ọjọ́ méjì àwọn ajínigbé tó jí Ọlọ́ṣọ̀ ti ìlú Oso Ajowa-Akoko, Ọba Clement Jimoh Olukotun gbé ti kàn sí àwọn mọ̀lẹ́bí Kábíyèsí.

Àwọn ẹbí ní Ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà ni àwọn ajínigbé ọ̀hún ń bèèrè fún kí wọ́n tó le tú ọba alayé náà sílẹ̀.

Ní alẹ́, ní nǹkan bíi aago mẹ́wàá kọjá ìṣẹ́jú márùn-ún ọjọ́bọ̀ ni àwọn ajínigbé náà yawọ ààfin tí wọ́n sì jí ọba náà gbé lọ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀gbẹ́ni Gani Muhammed Ajowa sọ fún BBC Yorùbá.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni àwọn ajínigbé náà kàn sí àwọn ẹbí ọba tí wọ́n sì ń bèèrè fún ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà.

Àwọn ẹbí ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ọdẹ ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti ṣe àwárí kábìyésì, kí wọ́n gbà á kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé síbẹ̀ àwọn ń pàrọwà sí àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ran àwọn lọ́wọ́.

“À ń bẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo, àwọn àgbààgbà ní ìjọba ìbílẹ̀ Akoko North-West àti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pátápátá kí wan ràn wá lọ́wọ́.”

“Owó tí àwọn ajínigbé ń béèrè lọ́wọ́ wa ti pọjù, a ò ní adúrú owó bẹ́ẹ̀.”

“A fẹ́ kí kábíyèsí padà sí ààfin ní ayọ̀ àti àláfíà àti ní odidi ni ohun tí à ń fẹ́ fún Ọlọ́ṣọ̀ wa.”

Ìròyìn ní àwọn ará ìlú tu bẹ̀rẹ̀ àkànṣe àdúrà àti ààwẹ̀ láti gbàdúrà fún ìpadàpọ̀ kábíyèsí.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oondo, Funmilayo Odunlami ni àwọn ọlọ́pàá ṣì wà nínú igbó láti mọ ibi tí àwọn ajínigbé ọ̀hún fara pamọ́ sí, kí wọ́n sì dóòlà ẹ̀mí kábíyèsí.

Odunlami ní ìgb]iyànjú ń lọ láti gba kábíyèsí sílẹ̀ láyọ̀ àti àláfíà.