Tinubu ni bàbá mi, àyẹ̀wò DNA wà; mo ni ìwé ẹ̀rí àti àwọn ǹkan míì tí Tinubu sọ ní Chattam House

Oríṣun àwòrán, Chattam House /Twitter
Oludije si ipo aarẹ Naijria lọdun 2023, labẹ asia ẹgbẹ all Progressives Congress, Bola Tinubu ti dahun awọn ahesọ ọrọ to n waye nipa ọjọ ori rẹ, ile ẹkọ to lọ, ati awọn igbeaye rẹ mii gẹgẹ bi oṣiṣẹ nileeọ̀ẹ aladani.
Bola Tinubu sọ nibi ọrọ apilẹkọ rẹ ni Chattam House, lọjọ Aje, ọjọ karun-un, oṣu Kejila, ọdun 2022, pe ko si irọ tabi eeru ninu ọjọ ori ti oun n lo, to fi mọ ile ẹkọ to lọ ati awọn ibi to ti ṣiṣẹ.
Tinubu lọ si Chattham House lati dahun awọn ibeere nipa idibo ọdun 2023, nkan ti yoo ṣe nipa eto aabo ati ọrọ aje, to fi mọ ibaṣepọ pẹlu awọn orilẹ-ede agbaye.
O ni lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 1952 ni wọn bi oun, oun ko si tii ni erongba lati di aarẹ Naijiria nigba naa.
“Gbogbo akọsilẹ nipa mi lo ba ara wọn mu. Mi o paarọ baba to bi mi, Tinubu si ni orukọ idile ti mo ti wa.
“Bi ẹnikẹni ba fẹ ayẹwo DNA mi, ẹ le beere fun.
”Bakan naa lo sọ pe ileeṣẹ Deloitte ti oun ti ṣiṣẹ, ati fasiti ilu Chicago ti oun lọ, jẹri si.
Ẹwẹ, o ni oun kede ni gbangba bayii pe oun ti gba ojulowo iwe ẹri fasiti mii lọwọ wọn, lẹyin ti akọkọ sọ nu.
Lara awọn to tẹle lọ sibi eto naa ni olori ile aṣofin, Femi Gbajabiamila, gomina ipinlẹ Kaduna ati Jigawa, Naisr El-Rufai, Abubakar Badaru, to fi mọ Kayode Fayemi, gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, ati awọn alatilẹyin rẹ mii.
Wó àwọn kókó tí Bola Ahmed Tinubu sọ ní Chattam House
Tinubu sọ pe ẹgbẹ osẹlu APC ti fi ara rẹ han gẹgẹ bi olootọ nipa amojuto idibo.
O ni eto idibo Naijiria ti dara ju bo ṣe wa tẹlẹ lọ lati dun 1999.Bakan naa lo sọ pe lilo imọ erọ lati dibo ati gbe esi jade fihan pe idibo ti ko ni magomago ni yoo waye.
Eto iṣẹ agbẹ Bola Tinubu sọ pe ijọba to wa lode lọwọlọwọ ṣe daada ni ẹka iṣẹ agbẹ nipa yiya awọn agbẹ lowo ati awọn nkan mii.
O ni oun yoo tẹsiwaju ninu rẹ, pẹlu afojusun lori imọ ẹrọ lati mu idagbasoke ba ẹka naa.
Tinubu sọ pe ọna ti oun yoo gba ni lati mu ki irinna ojurin dara si, to fi mọ awọn nkan amayedẹrun mii ati ibi ti awọn agbẹ yoo ma ko ere oko wọn si.
Eto aaboTinubu sọ pe ijọba oun yoo ṣe atunsẹ si ofin lati faaye gba ọlọpaa ipinlẹ, ijọba apapọ ati agbegbe.
O tun ni oun yoo ṣe atungbeyẹwo bi awọn ọmọ ogun ṣe n ṣe iṣẹ wọn, ti oun yoo si ra awọn irinṣẹ fun wọn lati le mojuto ipenija aabo to n ba Naijiria finra

Oríṣun àwòrán, others












