Ohùn kan lójú oorun ló ní kí n gbàdúrà fún Tinubu ní ìhòhò- Olaiya Igwe

Oríṣun àwòrán, Olaiya Igwe
Gbajugbaja oṣerekunrin, Ẹbun Oloyede, ti gbogbo eeyan mọ si Olaiya Igwe, ti sọ pe awọn ẹmi lo paṣẹ fun oun lati gbadura fun Bola Tinubu si ihoho.
Ọjọ diẹ sẹyin ni Olaiya Igwe fi fidio kan sori ayelujara, eyi to ṣafihan bo ṣe n gbadura fun oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Tinubu, ni eti okun lai wọ aṣọ.
Ninu fidio naa to pada fa awuyewuye lori ayelujara, ni Olaiya ti n kawọ adura soke pe Tinubu ni yoo jawe olubori gẹgẹ bi aarẹ Naijiria lọdun 2023.
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo si n bu u pe iwa itiju ati ẹlẹya ni Ọgbẹni Ebun Oloyede hu, nitori bo ṣe gbe fidio ara rẹ jade nitori oloṣelu.
Ṣaaju ni Oloyede ti pada ṣalaye pe oun gbe igbesẹ lati gbadura fun Tinubu, nitori pe oloore oun lo jẹ.
O ni iyawo rẹ, Oluremi Tinubu, doola ẹmi oun nigba kan ti oun dubulẹ aisan, to si sanwo itju oun nile iwosan.
ṣugbọn ninu ifọrọwanilẹnu wo kan to ṣe lori amohunmaworan TVC lowurọ ọjọ Aje, Ebun Oloyede sọ pe oun gbọ́ ohùn kan ninu ẹmi, pe ki oun ṣe eto adura naa.
“Mo jẹ ẹnikan to ni ẹbun ìran, mo si ma n ri awọn eto Ọlọrun fun aye mi ki wọn to ṣẹlẹ̀.”
“Lọjọ kan, oju orun ni mo wa ti mo ti gbọ ohun kan to beere lọwọ mi pe ṣe lootọ ni mo nifẹ Asiwaju bi mo sẹ ma n sọ.
“Mo sọ pe bẹẹni.”
Ẹbun Oloyede ni lẹyin naa ni ohùn naa sọ pe ki oun lọ ṣe awọn nkankan nitori oloore oun (Asiwaju).
O ṣalaye pe oun ro ọrọ naa pe nkan to ṣe e ṣe fun oun ni gẹgẹ bi oṣere, amọ oun tun ro pe o yẹ ki awọn ẹbi oun mọ nipa rẹ.
“Mo tun wa ro o pe nkan ti mo fẹ sẹ yii ko nii ṣe pẹlu ẹnikẹni, a mọ mo le ṣe ohunkohun nitori Asiwaju.”
Lori bi fidio naa ṣe de ori ayelujara, Oloyede sọ pe oun mọọmọ ya fidio eto adura naa ni, nitori ki awọn eeyan le ri fidio naa.
“Mi o si kabamọ ohunkohun ti mo ṣe.”
“Mo ni ominira lati sẹ nkan to ba wu mi, niwọn igba ti ko ba ti pa ẹnikẹni lara.”
Oloyede sọ pe ohun ko le ni ki ẹnikẹni ma ṣe nkan to ba wu wọn, amọ ẹni to ba ṣe e lai gbọ ohùn Ọlọrun bii ti oun yoo kabamọ.
Bakan naa lo ni oun ko fi igbesẹ naa lọ ẹnikẹni ki oun to o ṣe.
“Asiwaju, Dapo abiodun, ati MC Oluomo lo gbe ẹmi mi dani nigba ti mo kọkọ ṣe aisan.
“Ko si si nkan ti mi o le ṣe fun oloore mi.”
Ẹwẹ, Olaiya Igwe sọ pe oriṣiriṣi igba ni oun ti gbọ ohùn lati gbe awọn igbesẹ kan.
Ọgbẹni Oloyede sọ pe nkan ti oun ṣe ko le ni ipa buburu lara iṣẹ oun gẹgẹ bi oṣere, ayafi awọn ti ori wọn ko pé lo le tori nkan bẹẹ ma gbe iṣẹ fun oun.














