Iṣẹ́ fíìmù ló sọ mi di Babaláwo, Wòlíì Ọlọ́run ni mi - Adewale Alebiosu
Oṣere ti ọpọ mọ si ọkan lara awọn ogbontagi Babalawo ninu fiimu Yoruba, Adewale Alebiosu ti sọ pe iwa ti awọn oṣere n hu sira wọn ko dara rara.
Alebiosu ko fi bo rara tori o ni abuku to ti kan oun ti pọ ti ko ṣee fẹnu sọ pẹlu bi oun ti lorukọ to laarin awọn oṣere.
"Bi awọn eeyan ba pe mi sibi eto kan ti wọn rii pe ọkọ ero tabi ọkada lo gbe mi wa, o maa n fọwọ tọ wọn lọkan gaan".
O ni ti wọn ba n sọ ọrọ ohun nigboro ti wọn ro pe oun ko gbọ amọ ti oun gbọ, o maa n mu oju oun kun fun omi rọrọ.
"Igba mii maa wa bẹ Ọlọrun pe oo dẹ ṣaanu mi bi mo ba ṣẹ ọ".
Bakan naa lo ni o tẹ awọn ọkunrin oni tiata lọrun lati maa ko owo fun akẹgbẹ wọn obinrin ju ọkunrin lọ tori wọn a ri igbadun lara obinrin.
"Lati ọdun 1979 ti mo ti bẹrẹ, bi mo ba reeyan ran mi lọwọ ni, kii 'se ibi ti mo wa yii lẹ o ti ba mi{.
Bawo lo ṣe bẹrẹ ere Tiata?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gbajumọ Babalawo ninu fiimu Yoruba ni Adewale Alebiosu amọ ti gbogbo eeyan maa n pe ni "Awo l'Ọyọ".
Ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹu BBC Yoruba, o ṣalaye idi ti awọn eeyan ṣe maa n ro pe Babalawo gaan ni loju aye tabi ki baba rẹ jẹ bẹẹ.
"Igba ti mo ṣetan lọdọ ẹni to kọkọ kọ mi niṣẹ ni mo lọ ba gbajumọ oṣere ti gbogbo eeyan mọ si Lalude, ibẹ ni mo ti bẹrẹ si ni kọ bi wọn ṣe n pa ọfọ".
Bawo lo ṣe jẹ to di Wolii?

Alebiosu ṣalaye pe Musulumi ni baba ati iya to bi oun lọmọ toun funra oun gan tẹlẹ si jẹ ẹlẹsin musulumi.
"Wọn n ṣe ikore ni ṣọọṣi kan ni ti wọn o si rẹni ba wọn lu ilu ni alagba kan wa tọka si mi ladugbo pe oni tiata ni mi o si yẹ ki n le lu ilu".
Alebiosu ni ibi ilu ni inu ile ṣọọṣi ti n yipo loju to si ba ara rẹ nilẹ gẹgẹ bi ẹlẹmii to n jiṣẹ iranṣẹ fawọn eeyan ninu ijọ lọjọ naa.
"Igba ti mo dide ni wọn sọ gbogbo ohun ti mo sọ fun, aṣe mo ti n sọ "bayii ni Oluwa wi."
O sọ bi awọn eeyan ṣe maa n ro pe oun gbona ninu iṣẹ awo amọ to ni ko ri bẹẹ.
'Bí àwọn oṣere ẹgbẹ mi ba ran mi lọwọ ni, o yẹ ki emi naa ti di olowo'

"Ti wọn ba pe mi sode, wọn a rii pe ọkọ ero tabi ọkada lo gbe mi wa, a wa ya wọn lẹnu pe bi mo ṣe to, mi o ni mọto, amọ emi o nifẹ igbe aye "fake".
O ṣalaye pe awọn ti oun kọ niṣẹ gan ti ra ọkọ ti wọn fi n ṣe ẹsẹ rin.
Bakan naa lo sọ idi ti awọn oṣere obinrin fi lowo lọwọ ju awọn ọkunrin lọ.






