Baba Suwe: Aya àkọ́fẹ́ olóògbé ṣàlàyé bí àkókó ìkẹyìn ọkọ́ rẹ̀ ṣe rí

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Aya àkọ́fẹ́ olóògbé ṣàlàyé bí àkókó ìkẹyìn ọkọ́ rẹ̀ ṣe rí

Iku iku alumoutu, ko si ẹni ti ko ni ku, ko si ẹni ti oko baba rẹ ko ni di igboro.

Oju lo pẹ si, o ti pe ọdun kan gbako ti iku mu ọ̀kan gboogi lara awọn oṣere adẹrinpoṣonu lagbo Tiata Yoruba, Baba Suwe lọ.

Babatunde Omidina ti ọpọ mọ si Baba Suwe, ẹni to dagbere faye lasiko aisan ọlọjọ pipẹ ni ọjọ Aje.

Ọjọbọ si ni wọn sin nile rẹ to wa ni Ikorodu nibi ti ọpọ awọn eeyan jankan atawọn osere tiata peju si.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori bi igba ikẹyin ọkọ rẹ se lọ lori idubulẹ aisan, Suwebatu ni oloogbe naa la kaka lati sọrọ fun oun ko to ku.

Amọ o ni se lo n la ẹnu silẹ, ti ọrọ kankan ko jade, titi ti o fi mi kanlẹ.

Suwebatu, ti oun naa jẹ osere tiata ni ọdun 1976 ni oun ati Baba Suwe ti n ba ọrọ ifẹ awọn bọ, ti awọn ko si ja titi ti ọlọjọ fi de.

Bakan naa lo wa n fi omije bẹ gbogbo ẹbi ati awọn eeyan ti ọmọ rẹ, Adebowale ba sẹ nitori fidio kan to gbe sori ayelujara ni kete ti baba rẹ ku, pe ki wọn jọwọ dari jin ọmọ oun.

O ni itara iku baba rẹ lo mu ko se bẹẹ, ki wọn si dakun fi ọwọ wọnu nitori ọmọde lo n se.