Baba Suwe: Mr Latin kéde bí TAMPAN àtàwọn òṣèré tíátà ṣe tọ́jú Baba Suwe lásìkò àìsàn

Yoruba ni bi ọdẹ ba ku, ọdẹ lo n soro lẹyin ọdẹ.
Se ni awọn ero pe babi sibi eto isinku gbajugbaja osere tiata ati adẹrinposonu nni, Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan tun mọ si Baba Suwe.
Ile rẹ to wa ni ojule Kẹrindinlgbọn, opopona Oluwatimiro, ibudokọ Ewu-Elepe, ni opopona Ijede nilu Ikorod ni ayẹyẹ isinku naa ti waye.
Oniruuru awọn eeyan jankanjankan lo peju sibi eto isinku naa, to fi mọ awọn gbajumọ osere tiata Yoruba lọkunrin ati lobinrin lọpọ yanturu.
- Awuyewuye bẹ́ sílẹ̀ lórí ìlànà ìsìnkú Baba Suwe, àwọn Alfa yarí
- Ìdí rèé ta ṣe fi pósí gbe Baba Suwe tó jẹ́ Mùsùlúmì - Aya rẹ̀ àkọ́fẹ́ ṣàlàyé
- Ẹ wo ẹni tó ń jẹ́ Suwebatu nínú ẹbí Baba Suwe àti ohun tó sọ nípa olóògbé
- Bí ètò ìsìnkú Baba Suwe yóò ṣe lọ rèé, bó ṣe ń wọ ilẹ̀ sùn lónìí
- Mọ̀ si nípa ìtàn ayé Baba Suwe tó ń wọ káà ilẹ̀ sún lónìí
- Bàbá mi máa ń sunkún torí bí kò ṣe le padà ṣeré tíátà mọ́ - Ọmọ Baba Suwe
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- Wo nǹkan mẹ́jọ tí o lè má mọ̀ nípa Baba Suwe tó dolóògbé
Lara awọn eekan osere tiata to peju sibẹ ni Adebayo Salami (Oga Bello), Bolaji Amusan (Mr Latin), Afusat Balogun (Madam Saje) ati Afonja Olaniyi ( Sanyeri).
Awọn yoku ni Femi Adebayo (Jelili Oniso), Yinka Quadri (Masọmọ), Modupe Johnson (Fali Werepe) ati Dejo Tunfulu.

Oríṣun àwòrán, mrlatin1510/Instagram
Nigba to n sọrọ ki wọn to gbe Baba Suwe wọ kaa ilẹ lọ, aarẹ fun ẹgbẹ awọn osere, TAMPAN, Bolaji Amusan, taa mọ si Mr Latin ba BBC Yoruba sọrọ nipa iru eeyan ti Baba Suwe jẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Latin ni eeyan to se ọwọn ati iyebiye ni Baba Suwe laarin awọn osere tiata, ti awọn si nifẹ rẹ gidigidi.
O ni ọrẹ, ẹgbọn ati alajọsisẹpọ awọn ni oloogbe naa, ti awọn si sa ipa awọn lati ri pe o bori aisan to n ba finra, ki ọlọjọ to de.
Iranwọ ta se fun Baba Suwe nigba to wa lori aisan ko lonka, a ko pariwo ni:
Nigba to n salaye oniruuru igbesẹ ti ẹgbẹ osere tiata TAMPAN gbe lati ra ẹmi Baba Suwe pada lasiko to wa lori aarẹ, Latin ni awọn tiraka.
O ni ọpọ iranwọ ti ko ni onka ni ẹgbẹ TAMPAN ti se fun Baba Suwe amọ awọn ko le maa pariwo kiri faraye nipa rẹ ni.
Koda, ki n to di aarẹ fun ẹgbẹ TAMPAN, ni wọn ti n ran Baba Suwe lọwọ lori aisan rẹ, nigba ti emi naa si di aarẹ, mo tẹsiwaju lati maa seranwọ fun.
"Lọdun 2017 ati 2019, TAMPAN se ọpọ iranwọ, ta si gbe igbesẹ lati ra ẹmi oloogbe naa pada nile iwosan.
A gbe owo ribiribi silẹ lati se itọju rẹ, ti ara rẹ si mokun pada.
Koda, ọjọ mẹrindinlgbọn ni Baba Suwe lo nile iwosan ẹkọsẹ fasiti Eko ta mọ si LUTH, awa la gbe gbogbo ẹnawo to wa nidi rẹ, oloogbe ko si san kọbọ nibẹ.
A ko le maa pariwo eyi fun araye lori ayelujara ni."
Latin wa sẹ pe irọ nla ni ahesọ ọrọ to n lọ kiri igboro pe TAMPAN ko ran oloogbe naa lọwọ nigba to nilo atilẹyin wọn lasiko ti aisan rẹ le koko.
O ni ẹgbẹ osere tiata naa lo seranwọ bo se yẹ, to fi mọ ọmọ ẹgbẹ kọọkan to sun mọ Baba Suwe, ti ikọọkan wọn si sa ipa to wa nikawọ wọn.
O wa ni awọn osere tiata ati TAMPAN ko le gbagbe Baba Suwe laelae nitori o ko gbogbo eeyan mọra, to si maa n ba ọpọ eeyan se.




















