Baba Suwe: Suwebatu ni òun ni aya àkọ́fẹ́ Babatunde Omidina, kó tó di gbajúmọ̀ lawọn ti fẹ́ra

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Ọpọ eeyan lo mọ Baba Suwe ṣugbọn ti wọn ko mọ ẹni ti Suwe gangan jẹ.
Iyawo akọfẹ Baba Suwe, Ayodele lo n jẹ Suwe, osere tiata ni oun naa, ori itage si ni wọn ti sọ ni Suwebat.
Suwebat naa si ti sọrọ nipa irufẹ ẹni ti oloogbe naa jẹ ati ibasẹpọ to wa laarin awọn mejeji, ki oloogbe ọhun to jade laye.
Obinrin naa sọ pe o pẹ ti awọn mejeji ti n ba ara awọn bọ, ki oloogbe naa to di gbajumọ lawujọ ere tiata Yoruba.
- "Lẹ́yìn ti mo lo ọdún 42 lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n tú mi sílẹ̀ pé ń kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn"
- Bàbá mi máa ń sunkún torí bí kò ṣe le padà ṣeré tíátà mọ́ - Ọmọ Baba Suwe
- Clem Ohameze, òṣèré tíátà ní àìlera, ó ń bẹ̀bẹ̀ àdúrà lórí iṣẹ́ abẹ
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Ẹ màá múra sílẹ̀ láti ra lítà epo kan ní ₦320 sí ₦340 lọ́dún 2022- NNPC
- Tówẹ́ẹ̀lì ni bàbá mi ró mọ́ ìdí nígbà tí àwọn sọ́jà wọlé mu lọ - Ọmọ Akintunde
- Jàndùkú kọlù mi, gé mi lára bíi olè torí mo jẹ́rìí tako ìjọba níbi ìwádìí ìpànìyàn Endsars Lekki''
- Femi Fani-Kayode ṣàlàyé bí ìrìnàjò rẹ̀ sọ́dọ̀ EFCC ṣe jẹ́
- Ẹ lọ san ₦20bn owó ìtanràn fún Sunday Igboho títí January - Iléejọ́ fọnmú fún DSS
Suwe ni "Bi mo ṣe jẹ ni soki si Baba Suwe ni pe, emi ni iyawo rẹ akọfẹ rẹ nigba aye alalumọlẹ."
"Ti ẹ ba n gbọ Suwe lọmọ lati ilẹ, Suwe mi lọsan, papa mi loru... o ti yẹ ko ye yin."
Obinrin naa to jẹ osẹre tiata Yoruba nigba kan ri sọ pe, oun kii ṣe ọmọde nidi iṣẹ tiata, awọn ewe iwoyi nikan lo ṣeeṣe ki wọn ma mọ ohun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, Baba Suwe n ṣaisan ni tootọ, ṣugbọn o ti n gbadun ki iku to ba lalejo.
O ni "Ohun to ṣokunfa iku Baba Suwe ni pe o n ṣaarẹ lati nnkan bii ọjọ melo kan, lootọ o ti n gbadun.. ṣugbọn ẹ jẹ ki a gba pe ọlọjọ lo de."
Nigba to n dahun ibeere lori boya o see see ka ri ọmọ Baba Suwe ti yoo gba ipo rẹ bii alawada ni agbo tiata, osere binrin naa ni iyẹn ku si ọwọ awọn ọmọ Baba Suwe.
Amọ o ni oun yoo se iranwọ fun eyikeyi ọmọ to ba fẹ sisẹ tiata lati goke agba.
Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ awọn ololufẹ agba oṣere naa fun aajo ati idide wọn lẹyin iku rẹ.
Ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla ọdun 20221 yii ni Baba Suwe dagbere faye niluu Eko lẹyin aisan ranpẹ.
Ọpọ awọn awọn ololufeẹ rẹ kaakiri agbaye, to fi mọ awọn oṣere tiata bii tirẹ lo ti bẹrẹ si n ṣedaro iku rẹ.



















