EndSARS Panel Report: Kamsiyochukwu Ibe ní láti ìgbà tí èsì ìwádìí ti jáde ni wọ́n ti ń dúnkokò mọ́ àwọn

Oríṣun àwòrán, EPA
Ọkan lara awọn afẹhọnuhan lasiko iwọde Endsars nipinlẹ Eko, Kamsiyochukwu Ibe ti ke gbajare sita pe ori lo ko oun yọ lọwọ awọn apaniyan ti wọn ṣekọlu si oun.
Ibe ni ikọlu naa ko ṣẹyin bi oun ṣe jẹri si ohun ti oju oun ri lasiko ifẹhọnuhan Endsars nipinlẹ Eko.
O ni awọn janduku mẹta to ṣekọlu si oun naa sọ wi pe nitori oun jẹwọ niwaju igbimọ oniwadii ni ipinlẹ Eko ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Kọmísánà ọlọ́pàá tú àṣírí bí ọmọ Rahmon Adedoyin ṣe ju òkú Timothy Adegoke sígbó, tó na pápá bora
- Wọ́n ní ajé wà lárá ọkọ mi ní wọ́n ṣe lò ó - Opó Timothy Adegoke gbarata
- Ẹ lọ san ₦20bn owó ìtanràn fún Sunday Igboho títí January - Iléejọ́ fọnmú fún DSS
- Ṣé lóòtọ́ ni àjọ EFCC mú Femi Fani-Kayode?
- Kò sí ìfẹ̀míṣòfò kankan ní Lekki Too Gate, àlọ́ àpamọ̀ lásán ni èsì ìgbìmọ̀ EndSARS - Lai Mohammed
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- Bí àyẹ̀wò òkú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU tó kú sílé ìtura, ṣe wáyé rèé
- Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho méjì síwájú torí kò sí atúmọ̀ èdè Yorùbá
- Ìjọba Eko fi ọwọ́ ọlà gbá ìyá Jumoke lójú ní ₦1m àti ilé tó hááyà fún - Agbẹjọ́rò
Lasiko to n salaye bi ikọlu naa ṣe waye ninu fidio to fi lede, o ni oun duro si opopona lati wa ọkọ lọ si ile nigba ti awọn janduku naa bẹrẹ si ni lo ohun ija oloro lati fi ge ẹsẹ ati apa rẹ.
O fikun un pe awọn to ṣekọlu si oun naa ni nitori oun beere fun idajọ ododo lọwọ igbimọ to n ṣewadii Endsars, ni awọn se kọlu oun.
''Ni alẹ ni awọn gende mẹta kan ṣekọlu si mi nibi ti mo duro si, ti mo ti fẹ wọ ọkọ ti mo si ro pe awọn to fẹ wọ ọkọ bi temi ni wọn.''
''Mo duro ni ibẹ ni ọkan ninu wọn tan ina si oju mi, to si ni ṣe kii ṣe ọkan ninu awọn ẹlẹri ni iwadii Endsars ree? Iwọ lo sọ pe o mọ ju, ti o ko si fẹ gbẹnu dakẹ?
'' O ni ti awọn ba pa mi, awọn a wo bi mo ṣe fẹ beere fun idajọ ododo. Ọrọ wọn ko kọkọ ye mi, ki wọn to bẹrẹ si ni ge mi ni ara, ọwọ ati ẹsẹ afi bi ole.
''Pẹlu ẹkun kikoro ni arabinrin yiifi sọ wi pe oreọfẹ Ọlọrun lo ko oun yọ.''
Lasiko to n fesi si iṣẹlẹ naa, ọkan gboogi ninu awọn igbimọ iwadi naa, Ebun-Oluwa Adegboruwa (SAN) ni lati igba ti iwadii ti jade ni wọn ti n dunkoko mọ awọn paapaa lati ọdọ awọn eniyan ti wọn tọka si pe wọn wa lati ọdọ ijọba.
''O ke gbajare pe ki wọn fi ẹsun kan ijọba ipinlẹ Eko gẹgẹ bi ẹni to wa ni idi iṣẹlẹ naa ti nkankan ba ṣe oun.''
''Mi o ṣẹ ẹnikẹni ju pe mo gbọ ipe ijọba lati ṣiṣẹ lai si abawọn lori ohun to ṣẹlẹ ni asiko Endsars.''
''Awọn agbẹjọro meji ọtọọtọ to jẹ ti ijọba ni wọn ti lọ si ori ẹrọ telifisọn lati tabuku mi lai ṣe ohunkohun, ti mọ si kọ lati dakẹ lori iṣẹlẹ naa.''
''Mo kesi awọn ọmọ Naijiria lati da si ọrọ yii, nkankan ko gbọdọ ṣe mi nitori ọwọ ijọba ipinlẹ Eko ni ẹmi mi wa''
''Ẹṣẹ mi ni pe mo sọ ododo ninu iwadii ti igbimọ naa gbe jade, to si jẹ pe ọwọ ijọba lo ku si lati ṣe ohun to yẹ lori gbogbo iwadii ti a ṣe naa.''

"Buhari, Sanwo-Olu, ẹ kọ̀wé fipò sílẹ̀ torí àwọn ọ̀dọ́ tó kú lásìkò ìwọ́de EndSARS"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn eeyan kan ti abọ iwadii ipaniyan to waye lasiko iwọde EndSARS ni Lekki kan gbọngbọn, ti ṣe ipade akọroyin lori abọ igbimọ oluwadii naa, ti wọn gbe kalẹ fun ijọba.
Nibi ipade naa ni wọn ti kede pe awọn faramọ abajade iwadii igbimọ EndSARS ọhun, ati pe awọn n fẹ ki ijọba gba abọ iwadii naa wọle.
Awọn eeyan naa, ti ọpọ wọn jẹ agbẹjọro ati adari ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni sọ pe, awọn n fẹ ki Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati Aarẹ Muhammadu Buhari kọwe fi ipo wọn silẹ, lẹyin ti awọn ọmọ ogun fi ẹmi awọn ọmọ Naijiria ṣofo lakata wọn.
- Buhari, fi Sunday Igboho sílẹ̀, kí ìṣọ̀kan le padà sí Naijiria - Oluwo
- Ọ̀pọ̀ òṣèré tíátà ń ṣèdárò Baba Suwe tó jáde láyé
- Ìjọba Eko fi ọwọ́ ọlà gbá ìyá Jumoke lójú ní ₦1m àti ilé tó hááyà fún - Agbẹjọ́rò
- ''Ó burú jáì pé Ramon Adedoyin tí akẹ́kọ̀ọ́ kú sílé ìtura rẹ̀ tún ń sọ̀rọ̀ lákàtà ọlọ́pàá''
- "Davido kò ran èmi gbajúmọ̀ lọ́wọ́, ọmọ òrukàn ló fẹ́ kó ₦250 fún"
- Ìjọba fẹ́ pa mí torí àbọ̀ ìwádìí ìkú olùwọ́de EndSARS ní Lekki - Adegboruwa figbe ta
- "Àgbà Yorùbá dalẹ̀ Sunday Igboho, wọ́n fi sílẹ̀ bíi ọmọ òrukàn"
- Ìyàwó Adedoyin sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe kú sílé ìtura ọkọ rẹ̀ ní Ile Ife
- Ọlọ́pàá dóòlà òṣìṣẹ́ iléèṣẹ́ 'Pure Water' méje tí ajínigbé gbé sálọ ní Kwara
- Rúdurùdu nílé aṣòfin l‘Ogun, Igbákejì olórí ilé ní wọ́n lo ayédèrú ìbuwọ́lù òun láti gbé ₦50m jáde
- Daddy Freeze pe ọmọ David Oyedepo níjà lórí ìdí tó fi ri bíbélì 15 mọ́lẹ̀ sínú ṣọ́ọ̀ṣì Winners l'Amerika
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti ipade akọroyin naa da le lori, olori agbẹjọro fun awọn oluwọde EndSARS, to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, Adesina Ogunlana ni o tun yẹ ki ijọba gba isẹ lọwọ awọn ọlọpaa ati ologun to lọwọ ninu iku awọn ọdọ lasiko iwọde naa.
Ogunlana ni "Ohun ti a fẹnuko si ni pe ki ijọba gba gbogbo ohun ti igbimọ oluwadii EndSARS sọ wọle."
"Lẹyin naa, ki gomina Sanwo-Olu funra rẹ, ati Buhari kọwe fi ipo silẹ... ki gbogbo awọn ọmọ ogun ti wọn lọwọ ninu iku awọn ọdọ, eyii ti igbimọ naa da mọ fi iṣẹ wọn silẹ, ohun ti a fẹ niyẹn."
Ogunlana sọ pe niwọn igba ti ijọba ti le gbe igbimọ kalẹ lati ṣe iwadii ẹsun ifẹmiṣofo nibi iwọde EndSARS, ti igbimọ ọhun si ṣiṣẹ fun ọdun kan gbako, o yẹ ki ijọba le gba abajade igbimọ naa wọle.
Ajafẹtọ naa tẹsiwaju pe, kii ṣe pe awọn n bẹ ijọba lati ṣe ohun ti wọn beere fun, ṣugbọn ohun to tọ fun ijọba lati ṣe labẹ ofin ni awọn beere fun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ijọba to ba ni ojuti yẹ ko ṣe ohun ti igbimọ to ba gbe kalẹ ba gba nimọran lati ṣe.
Ni ti ohun ti wọn yoo ṣe ti ijọba ba kọ lati ṣe ohun ti ẹgbẹ naa n beere fun, Ogunlana ni awọn n duro de ọjọ mẹrinla ti ijọba da lati gbe abajade igbimọ naa yẹwo, ki awọn to kede igbesẹ to kan.
Ọjọ karundinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 yii ni igbimọ ti ijọba gbe dide lati ṣewadii ifẹmiṣofo to waye ni iloro Lekki fi abajade wọn lede.



















