Jumoke Oyeleke: Agbẹjọ́rò ẹbí olóògbé ní ₦1m kéré bíi owó gbà máa bínú fún ìyá lórí ikú ọmọ rẹ̀

Ifeoluwa Oyeleke

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

Agbẹjọro fun ẹbi Jumoke Oyeleke to ku lasiko iwọde Yoruba Nation nilu Eko, Taiwo Oyeleke ti koro oju si bi ijọba ipinlẹ Eko ṣe fun mama rẹ, Ifeoluwa Oyeleke ni miliọnu kan naira, ti wọn si tun gba ile fun un.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹjọro Taiwo Olawanle sọ pe ọgbọn alumọkọrọyi ni ijọba lo, to fi fun arabinrin naa lowo, ti o si tun sanwo ọdun mẹta sile merẹnti fun un.

Ọgbẹni Olawanle sọ pe ko tọna fun ijọba ipinlẹ Eko lati ṣe bẹẹ, niwọn igba to jẹ pe ẹjọ naa si wa nile ẹjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Fifi ọwọ ọla gba ni loju ni ohun ti ijọba ipinlẹ Eko ṣe fun mama Jumoke tumọ si.

Miliọnu kan naira ti wọn fun ati ile ti wọn gba fun un ko to ẹmi ọmọ rẹ to di oloogbe.

Ti a ba tun wo o lọna mii, awọn igbimọ oluwadii iwa ipa awọn ọlọpaa lori iṣẹlẹ EndSARS dajọ pe ki wọn fun awọn ẹbi eeyan to ku ni miliọnu marun un si mẹfa.

Àkọlé fídíò, EndSARS Victims: Ìyá méjì nínú mẹ́ta ti kú nínú àwọn ọmọ tí ọlọ́pàá gbé àmọ́ torí ìwọ́de

Ẹyin wa n lọ fun obinrin yii ni miliọnu kan naira ati ile merẹnti, ti owo ile naa ba tan, ta lo maa san omiran?

Awa o gba eleyii wọle, ati pe ẹjọ si wa nile ẹjọ, a ko ti mọ ẹni to ba Jumoke bayii tori awa gbagbọ pe ọlọpaa lo pa a, amọ awọn ni ọlọpaa kọ.

A ko tii ri idi gbogbo ọrọ to wa nilẹ yii, wọn wa gbẹyin wa lọ fun iya oloogbe lowo.

O digba ti a ba mọ ẹni to pa Jumoke ki a to le mọ ohun ti a maa beere lọwọ ijọba ipinlẹ Eko gẹgẹ bi owo gba ma binu.

Ijọba ko tun fi ọrọ naa to awa agbẹjọro ẹbi Jumoke leti nigba ti wọn fẹ gbe igbesẹ yii.

Ṣe miliọnu kan naira to lati ra ẹmi eeyan pada? Igba wo ni wọn maa to na miliọnu kan naira tan?"

Àkọlé fídíò, 'Ẹ má jẹ́ kí òkú ọmọ mi ráre o ìjọba! Ẹ gbée fún mi kí n lọ sin ín - Ìyá ọmọ ti wọ́n pa ní ìwọ́de Yoruba Nation

Bakan naa ni Olawanle salaye pe adẹrinpoṣonu kan, Mr Macarona fun mama ọmọ yii ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrun naira.

O ni ti ẹnikan ba le ṣe iru nkan bayii fun mama ọmọ naa, meloo meloo wa ni ijọba ipinlẹ Eko?

Bakan naa lo fikun pe awọn ko ri miliọnu kan naira gẹgẹ bi owo gba ma binu to yẹ fun ẹni ti wọn yinbọn pa ọmọ rẹ.

Olawanle wa ni awọn tiẹ ni igbagbọ pe kii ṣe ijọba ipinlẹ Eko lo wa nidi igbesẹ yii.

Agbẹjọro naa tun fikun ọrọ rẹ pe, alaanu kan ti ṣeto ile gbigbe fun mama oloogbe yii, eyi to jẹ ki ile ti di meji bayii.

Amọ o ni o ku si ọwọ iya Jumoke lati yan ile ẹni to fẹ lọ gbe, boya ile ti ijọba ipinlẹ Eko rẹnti fun ni abi eyi ti alaanu kan gba fun.

Sugbọn Olawanle ni o di dandan ki owo ile ile kan sofo danu ninu ile mejeeji nitori obinrin naa atawọn ọmọ rẹ ko le gbe ile meji papọ.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀dọ́ opó l'obìnrin sọ ìrírí wọn l'awùjọ