Jumoke Oyeleke: Wo ẹ̀bùn ńlá tí ìjọba fi ta ìyá tó pàdánù ọmọ rẹ̀ lásìkò ìwọ́de lọ́rẹ

Iya Jumoke n tẹwọ gba ẹbun ile ati owo lọwọ asoju ijọba Eko

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

Idunnu ti subu lu ayọ fun iya Jumoke Oyeleke, tii se ọmọbinrin to ku lasiko iwọde Yoruba Nation nilu Eko.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti haaya ile oni yara meji ti wọn kọ si adugbo Ikorodu, eyi ti gbogbo ẹsọ inu ile wa ninu rẹ, fun obinrin naa, to si sanwo ile ọdun mẹta.

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Eko tun fi miliọnu kan naira ti ile naa nidi, to si ko wọn fun iya Jumoke Oyeleke.

Atẹjade kan ti akọwe iroyin si gomina ipinlẹ Eko, Gboyega Akosile fisita ni obinrin naa ati awọn ọmọ rẹ ni wọn n gbe ninu ile alapa kan to wa ni adugbo Ogudu nipinlẹ Eko tẹlẹ, ko to di pe ijọba dide iranwọ fun wọn.

Nigba to n ko kọkọrọ ile merẹnti naa le Arabinrin Ifeoluwa Oyeleke, tii se iya Jumoke lọwọ, amugbalẹgbẹ fun gomina ipinlẹ Eko, Titi Oshodi ni ijọba n feti leko lori ọrọ naa lati igba ti asita ibọn ti pa ọmọbinrin naa lasiko iwọde Yoruba Nation.

Ile tuntun ti ijọba Eko kọ fun iya Jumoke

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

"Ilegbe tuntun ti wọn haaya fun awọn idile Jumoke to jalaisi lasiko iwọde Yoruba Nation ni a wa bayii, a ti de ile ti wọn n gbe tẹlẹ lati mọ ipo ọrọ aje arabinrin naa, ti aanu si se wa.

Nibayii, a wa ko kọkọrọ ile tuntun le obinrin naa ati ọmọ rẹ mẹta to ku lọwọ lati maa gbe ibẹ, gomina Sanwo-Olu si lo siju aanu yii wo wọn, bi o tilẹ jẹ pe ko seese mọ lati ji Jumoke pada saye.

Bakan naa ni gomina Sanwo-Olu tun ni ka fun wọn ni miliọnu kan naira, ko le mu adinku ba isoro ọrọ aje ti wọn n koju, ti wọn yoo si tun le bẹrẹ igbe aye ọtun."

Oshodi ni niwọn igba ti ẹnikẹni ko mọ tẹlẹ pe irufẹ isẹlẹ aburu yii le sẹlẹ, ni gomina Sanwo-Olu se tete seto fun idile naa tẹlẹ.

O ni gomina naa haya ilegbe fun wọn lati maa gbe nigba to n gbe igbesẹ akọtun fun wọn lọjọ iwaju, ki wọn le tẹsiwaju.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ má jẹ́ kí òkú ọmọ mi ráre o ìjọba! Ẹ gbée fún mi kí n lọ sin ín - Ìyá ọmọ ti wọ́n pa ní ìwọ́de Yoruba Nation

Iya Jumoke ni yoo nira lati ri owo ile mii san lẹyin ọdun mẹta ti owo tijọba san ba jo tan:

Nigba to n fesi lori ọwọ ọrẹ ti ijọba Eko na si naa, Iya Jumoke tii se ọmọ ọdọ to n bawọn eeyan tun ile se, to si tun n tọju ayika ile dupẹ lọwọ ijọba Eko.

Iya ọlọmọ mẹta naa wa tun n fi omije rawọ ẹbẹ si gomina Babajide Sanwo-Olu lati se iranwọ fun ipese isẹ oojọ ti yoo pẹ titi, ko le rọrun fun oun lati tọju awọn ọmọ to ku.

"Ile ta n gbe tẹlẹ, a haya rẹ ni amọ wọn le wa kuro nigba ti wsn ta ile naa, ti n ko si ri owo gba ile miran.

Idi ree ta se n ls gbe ile ti wọn fi pako kọ fun odidi ọdun kan, ki Jumoke gan to ku, ọmọ ijọ wa kan si lo seranwọ fun wa lati maa gbe ibẹ.

Jumoke ni akọbi mi, mo wa n dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Eko fun bi wọn se ranti emi ati awọn ọmọ mi. Wọn haya ile yii fun mi ni.

Amọ ko si bi mo se fẹ ri owo ile miran san lẹyin ọdun mẹta ti owo ile yii pa jo tan, mo fẹ ki wọn pese isẹ gidi fun mi, maa si maa se kata kara pẹlu miliọnu kan naira ti wọn fun mi yii"

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: