Zainab Aliyu Joins NDLEA: Bí ọmọbinrin tí wọ́n parọ pé ó gbé òògùn olóró tó sì wọ ẹ̀wọn ní Saudi ti dara pọ̀ mọ́ NDLEA

Zainab Aliyu ninu aṣọ ajọ NDLEA

Oríṣun àwòrán, Zainab Aliyu

Zainab Aliyu ti lo osu diẹ ni ọgba ẹwọn Saudi Arabia fún ẹ̀sẹ̀ tí kò mọ̀dí kí wọ́n tó padà tú u sílẹ̀ ní Ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù kẹrin ọdún 2019.

Ó ti di òṣìsẹ́ àjọ tó n gbógun ti òògùn olóró (NDLEA) báyìí.

Ẹni ọdún márùndínlọ́gbọ̀n ti pari ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Assistant Suprintendedt of Narcotics 15/2021 ní àjọ NDLEA ni Katon Rikkos ni ìpińlẹ̀ Jos.

Àná tíí ṣe ọjọ́ kọkàndílógún, oṣù kọkànlá ọdún 2021 ni eyi waye.

Ó sọ fún BBC pé nǹkan ti ó ṣẹlẹ̀ sí oun lọ́dún 2018 ló yí ayé rẹ padà tí ó sì jẹ́ ìwúrí fún láti dí oṣìṣẹ́ àjọ tó n gbogun ti òoogun olóró.

''Wọn parọ mọ mi ni pe mo gbe oogun oloro, ni bayii ti mo ti bẹrẹ iṣẹ pẹlu ajọ NDLEA bayii, mo maa ri pe iwadii gidi n waye lati mọ ẹni to ṣẹ gan an,'' Zainab lo sọ bẹẹ.

Ọrọ Zainab to kẹkọọ gboye ni fasiti Yusuf Maitama tan kaakiri ni Naijiria lẹyin ti wọn mu un nigba to rinrin lọ si Saudi Arabia lọdun 2018 fun Umrah.

Oṣu mẹrin ni o lo ni ọgba ẹwọn Jeddah nibi ti wọn ti Ka ẹjọ iku fun un ki ijọba Naijiria to dasi ọrọ naa ti o fi mori bọ.

Baba Zainab sọ fun BBC pe oun dupẹ lọwọ Eleduwa fun ayipada to ba aye ọmọ oun lẹyin to darapọ mọ ajọ NDLEA tan.