Child Violence: Ọgá ọmọ ọdọ tó fí ìbínú dá omi gbóná s'ará ọmọ ọdọ rẹ̀ kò sí pànpẹ ọlọ́pàá

Aworan ọmọde ti wọn da omi gbona si lara

Oríṣun àwòrán, FIDA Rivers State

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers ti mu arabinrin kan lori ẹsun ifiyajẹ ọmọde kan to da omi gbigbona sii lara.

Arabirin Oluchi Chinedu Nkemjika la gbọ pe o da omi gbona sara ọmọ ọdọ rẹ ọmọ ọdun mẹsan lara.

Lọwọlọwọ bayii,ọmọdebinrin naa wa ni ile iwosan to ti n gba itọju lori apa ti omi gbona yi da si ẹyin ati ibadi rẹ.

Àkọlé fídíò, 'Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé lórí 200,000 láìlèfọhùn lórílẹ̀èdè Oman'

Iroyin to tẹwa lọwọ tun sọ pe nitori ti ọmọọdọ yi lu ọmọ ọga rẹ ni o ṣe da omi gbona si ara rẹ.

Sam Chukwuejina to jẹ alabagbe arabinrin yi lo fi ọrọ yi to awọn ọlọpaa leti nigba to ri apa to wa lara ọmọ naa.

O ni odidi ọjọ mẹrin ni arabinrin yi ko fi ṣe nkankan nipa itọju ọmọde yi.

Chukwuejina to jẹ aarẹ ẹgbẹ araadugbo Paradise Avenue ni awọn lati gbogun ti obinrin naa ki o to jọwọ ọmọ naa ati ki awọn ọlọpaa to bẹrẹ iwadii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers sọ pe ẹṣẹ nla leyi jẹ labẹ ofin to de ẹtọ awọn ọmọde.Eyi lo mu ki wọn gbe ẹjọ naa le ẹka iwadii iwa ọdaran lọwọ lati ṣewadii.

Kini ofin ẹtọ ọmọ sọ nipa iṣẹlẹ yi?

Adata Bio-Briggs, FIDA

Oríṣun àwòrán, Adata Bio-Briggs, FIDA

A kan si arabinrin Adata Bio-Briggs to jẹ agbẹjọro labẹ ẹgbẹ agbẹjọro obinrin Naijiria FIDA.

Ninu alaye rẹ, o sọ pe awọm ko ṣẹṣẹ maa ri iru iṣẹlẹ bayi ti awọn ọgabinrin ti maa n hu iwa ipa sawọn ọmọ ọdọ wọn.

O ni bi wọn ṣe n fi ebi pawọn ni wọn a maa lu wn koda ẹlomii a maa fi ata si oju ara awọn ọmọ ọdọ tabi ki wọn fi iron gbona jo wn lara tabi omi gbigbona.

Adata Bio-Briggs sọ pe ofin to n sọ awọn ọmọde lọwọ ijiya lo n mojuto iru iwa bayi.

Àkọlé fídíò, Itunu Babalọla Death:Àgbáyé ẹ gbà mí, mọ fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ mí! ìyà yí tí pọ̀jù

O tẹsiwajupe labẹ ofin yi, ọmọde ti o jẹ ọmọ ọdun mẹsan tabi ti ko pe ọdun mejilelogun ko tọ lati ṣiṣẹ ọmọọdọ labẹ ẹni ti kii ṣe mọlẹbi rẹ.

Ifọmọṣowo ẹru lo sọ pe eleyi jẹ.

Labẹ ofin yi o ni ẹni ba fi iya jẹ ọmọde ti ọwọ ofin ba tẹ, yoo san owo itanran N500,000 tabi ko lọ si ẹwọn tabi ko si san owo ki si tun lọ sẹwọn pẹlu.

Lakotan o ni iṣoro tawọn ni pẹlu fifi ofin yi lelẹ ni pe ọpọ lo maa n fi ẹsẹ ile tọ ọrọ yi ti wọn o si nijẹ kode etigbọ awọn agbofinro.

Police Tok-tok pesin SP Nnamdi Omoni say even though di family of di 9 year old girl dey ask to withdraw di case, di matter now na State offence and dem go charge am go court even if both families settle.