House help: Ìgbà márùn ún rèé tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ti gé ẹ̀mí ọgá wọn kúrú

Eko

Oríṣun àwòrán, others

Lati ayebaye ni awọn eeyan ti maa n gba ọmọ ọdọ, to le jẹ ẹbi tabi ara ita.

Bi ọdun si ṣe n gun ori ọdun, ti ọpọlọpọ iyawo ile si n ṣiṣẹ, ni iwulo awọn ọmọ ọdọ, tabi oṣiṣẹ abani ṣisẹ ile n pọ si.

Wọn maa n ṣe awọn iṣẹ aṣọ fifọ, ounjẹ sise, itọju awọn ọmọ, ọkọ wiwa, oko riro, eto aabo, ati bẹẹbẹ lọ.

Awọn kan lara wọn maa n gba ile wọn wa a ṣiṣẹ, ti awọn miran si maa n gbe pẹlu idile to ba gba wọn siṣẹ.

Ṣugbọn o sẹni laanu pe ole, ajinigbe, ati oriṣiriṣi ọdaran ti n dibọn gẹgẹ bi ọmọ ọdọ tabi abaniṣiṣẹ ile.

To si jẹ pe nigba ti wọn ba gba wọn siṣẹ tan, ni wọn to n fi iwa wọn han.

Àkọlé fídíò, akeugbagold video

Ọkan lara iru iṣẹlẹ bẹ ẹ to ti waye ni bi ọdun mẹta sẹyin, lasiko ti ọmọ ọdọ kan ji ọmọ mẹta ti awọn ọga rẹ bi lẹyin wakati mẹrinlelogun ti wọn gba a siṣẹ.

Yatọ si pe o parọ orukọ rẹ, o tun parọ ọjọ ori rẹ.

Ọjọ mẹẹrin ni awọn ọmọ naa fi wa ni akata rẹ, ki oun ati ikọ ajinigbe rẹ to gba miliọnu meji Naira, owo itusilẹ.

Ọjọ keji ti wọn tu awọn ọmọ naa silẹ ni ọwọ tẹ wọn.

Ọmọilẹ Cameroon pa ọga rẹ ni Park View Estate

Eko

Oríṣun àwòrán, others

Ọkan lara awọn iṣẹlẹ to tun jẹ ibanujẹ ni eyi to waye logunjọ, oṣu Kejila, ọdun 2019 ni Parkview Estate, nilu Eko.

Ọmọ orilẹ-ede Cameroon kan to jẹ ọmọ ọdọ, Leujoe Koyemen Joel, lo gun ọga rẹ pa, nitori pe wọn jẹ ẹ lowo oṣu.

Ọga rẹ, Temidayo Adeleke, ṣẹṣẹ de pada sorilẹ-ede Naijiria ni lati ilẹ okeere to ti lọ kawe, to si n mura silẹ fun igbeyawo rẹ lasiko ti ọmọ ọdọ rẹ pa a.

Koju oṣu meji ti Leujoe bẹrẹ isẹ, lo lọ ba ọga rẹ pe ko fun oun lara owo oṣu oun fun oṣu Kejila. Ṣugbọn ti obinrin naa bẹ ẹ pe ko mu suuru fun oun di ọjọ keji, ki oun fi ṣẹ owo ilẹ okeere to wa lọwọ oun si Naira.

Ṣugbọn niṣe ni Leujoe yari, to si wọ ile idana lọ lati mu ọbẹ to fi gun Temidayo pa.

Ariwo to si pa lo mu ki awọn oṣiṣẹ ile to ku sa wọle, ti ọwọ fi tẹ ẹ. Ṣugbọn, Temidayo pada ku u.

Agbofinro

Ile ẹjọ kan nilu Eko si ti dajọ iku fun oun naa.

Tanko Abdullateefpa ọga rẹ ni VGC

Omiran tun ni ti obinrin oniṣowo kan, Mabel Okafor, ti aṣọgba rẹ pa ni adugbo VGC l'Eko.

Tanko Abdullateef

Oríṣun àwòrán, others

Aṣọgba yii, Tanko Abdullateef nikan ni ọmọ ọdọ ti obinrin ẹni aadọta ọdun naa ni ninu ile rẹ.

Ọrọ owo oṣu naa lo fa wahala laarin wọn. Iroyin sọ pe Tanko n fẹ ẹkunwo owo oṣu lọwọ ọga rẹ ni, ko to o gun-un pa.

Ọjọ meji lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye ni awọn ara ṣọọṣi obinrin naa wa wa sile, ti wọn ba ilẹkun ile naa ni titi lati ita.

Aigbe ipe si ori ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ lo tun mu ifura dani. Eyi lo si mu ki wọn o wọ inu ọgba ile naa, ṣugbọn oorun buruku lo ki wọn kaabọ.

Wọn si ba oku obinrin naa ni ilẹ yaara igbalejo rẹ.

Ọsẹ meji lẹyin naa ni ọwọ tẹ Tanko ni ipinlẹ Taraba.

Àkọlé fídíò, Ẹni ti ko riran to nlọ'ta ni Mushin

Ọmọ ọdọOloye Opeyemi Bademosi dẹmi rẹ legbodo ni Parkview Estate

Ile alakọpọ Parkview Estate naa ni isẹlẹ miran tun ti waye.

Oloye Opeyemi Bademosi

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Oloogbe naa ni Alaga ileeṣẹ Credit Switch Technology.

Ọmọ ọdọ kan lo tun pa ọga rẹ, Oloye Opeyemi Bademosi, ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2018.

Oloogbe naa ni Alaga ileeṣẹ Credit Switch Technology.

Ọmọ ilu Ondo ni oloogbe naa, nibẹ lo si ti mu ọmọ orilẹ-ede Togo naa wa si Eko, lati maa dana ounjẹ fun idile rẹ.

Ṣugbọn ko pẹ si asiko ti wọn gba a sisẹ ni o pa ọga ọra rẹ laarọ ọjọ kan.

Koda, iroyin sọ pe Sunday Adefonou yi ẹrọ rẹdio inu ile naa soke ki awọn aladugbo ma ba gbo bi o ṣe n gba ẹmi ọga rẹ ọhun.

Ọjọ meji lẹyin iṣẹlẹ naa ni ọwọ ọlọpaa tẹ ọdaran naa ni Yaba, to wa ni ilu Ondo. O kọkọ sẹ pe oun ko mọ ohunkohun nipa iku arakunrin ọhun, ṣugbọn lẹyin ti wọn fi fidio ori ẹrọ CCTV inu ile to ti gba ẹmi ọga rẹ ọhun han, o jẹwọ.

Ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Eko ti ran ọdanran naa lẹwọn igbere

Iku ọmọ ogun ori omi ati ololufẹ rẹ ni Port Harcourt

Ọmọ ọdọ mii tun ṣekupa ọga rẹ to jẹ ọmọ ogun ori omi ati ọrẹbinrin kan ni agbegbe Borokini, ni Port Harcourt, ni ipinlẹ Rivers.

Thaddaeus Jaja

Oríṣun àwòrán, others

Iṣẹlẹ naa waye lọjọ kẹrin, oṣu karunnun ọdun 2018.

Nigba ti awọn eeyan kọkọ ri oku ọrẹbinyin ọmọ ologun ọhun, wọn ṣebi ọkunrin naa lo ṣekupa ni lai mọ pe ọmọ ọdọ ọhun ti pa jagunjagun naa ṣaaju.

Àkọlé fídíò, Ifayẹmi Elebuibon: Ọ̀pọ̀ òkú ló ń rìn káàkiri ìlú Èkó, Ìbàdàn, Òṣogbo

Ọmọ ọdọ naa, Thaddaeus Jaja jẹwọ fun awọn ọtẹlẹmuyẹ lẹyin ti ọwọ tẹ tan pe oun dana sun oku oun, lẹyin naa ni oun ta ọkọ rẹ ni miliọnu meji naira dinj diẹ.

Ko tan sibẹ, ọmọ ọdọ ọhun tun fi ẹrọ ibanisọrọ ọga rẹ tẹ atẹjajiṣẹ kan si ọrẹbinrin ọga rẹ ọhun lori ede ayede kan ti wọn ni lọna ati fi ko ba a.

O sọ fun awọn ọtẹlẹmuyẹ pe owo lo fa ede ayede laarin oun ati ọmọ ogun ọhun ti oun fi da ẹmi rẹ legbodo.

O ni oun pa ọrẹbinrin ọga oun nitori obinrin naa lo fa ariyanjiyan laarin awọn memeji lẹyin ti ko jẹ ko fun oun lowo ti oun bere lọwọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: BBC News Yorùbá ní kí ẹ dúró nílé bí ẹ kò bá ní ìdí láti jáde