South Korea: Èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ajá mọ́

Ẹran aja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Mase jaja mọ

Ile ẹjọ kan ti pase ki wọn ma pa aja fun ẹran jijẹ mọ̀ ni ilu South Korea.

Idajọ̀ naa jẹ ohun to jẹ idunnu fun awọn ajafẹtọ ẹranko.

Wọn ni wi pe eyi yoo sọ ẹran aja jijẹ di ohun itan ni ilu naa.

Ẹran aja je ounjẹ pataki ni South Korea lati ọjọ pipẹ, ti wọn si maa n jẹ to aja milionu kan lọdọọdun.

Alapata ẹran aja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, 'Èèwọ̀ ẹ ò gbudọ̀ jajá mọ́

Saaju asiko idajọ yi, jijẹ ẹran aja ko wọpọ mo ni ilu naa nitori awọn ara ilu naa ti n sọ aja di nkan osin.

Àkọlé fídíò, Coronavirus tips: Kìí ṣe gbogbo ìbòmù ló ń dá coronavirus dúró