Imo state: Àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí tó ń pèsè àdó olóró fún IPOB

Oríṣun àwòrán, IMO POLICE
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo ti nawọ́ gán afurasí ẹni àádọ́ta ọdún kan.
won fẹ́sùn kan an wí pé ó ń ṣe àdó olóró fún ikọ̀ tó ń pè fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra (IPOB) tó ṣe ìkọlù sí àwọn àgọ́ ọlọ́pàá àti àwọn dúkìá ìjọba láìpẹ́ yìí.
Bákan náà ni wọ́n tún fẹ̀sùn kan ọkùnrin náà wí pé ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ikọ̀ Eastern Security Network.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo, Micheal Abattam sọ wí pé ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ ọmọkùnrin náà.
- Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà
- Kéte ti Baba dákẹ́ ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ti bẹ̀rẹ̀ l'Áàfin - Ẹ wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Aafin Oyo
- Kéte ti Baba dákẹ́ ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ti bẹ̀rẹ̀ l'Áàfin - Ẹ wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Aafin Oyo
- Ìdí tí Osinbajo fi ṣèbẹ̀wò sí Olubadan àti ohun tí wọ́n sọ rèé
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ṣí gbogbo ẹ̀ka ilé ẹ̀kọ́ Chrisland padà
- Láì tíì pé ọ̀sẹ̀ kan tó kéde akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun, Man U tún jẹ àjẹranjú ìyà lọ́wọ́ Arsenal pẹ̀lú góòlù Mẹ́ta sí ẹyọkan
- “Àìníṣẹ́ lọ́wọ́ ló mú mi pokùnso”
Abattam ṣàlàyé wí pé afurasí náà ti ń sọ gbogbo ohun tí yóò wúlò fún wọn tó fi mọ́ dídárúkọ àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀.
Báwo ní ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ṣe tẹ̀ ẹ́?
Abattam nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní ọjọ́ Ẹtì ní ọwọ́ tẹ afurasí náà nígbà tí àwọn ṣe ìkọlù sí ibùdó àwọn IPOB kan tó wà ní Uba Umuaka ní ìjọba ìbílẹ̀ Njaba.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Ó ṣàlàyé pé ènìyàn kan ló ta àwọn lólobó lórí ibùdó náà ló mú kí àwọn lọ ṣe ìkọlù síbẹ̀ tí ọwọ́ sì tẹ afurasí náà.
Ó fi kun wí pé nígbà tí àwọn fọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò ló jẹ́wọ́ wí pé òun ló máa ń ṣe àdó olóró fún àwọn IPOB ní ìpínlẹ̀ náà àti àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn.
Bákan náà ló ní ẹ̀ka tó mọ̀ nípa àdó olóró ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Kí tún ni àwọn ọlọ́pàá bá ibùdó náà?
Lára àwọn ohun tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ ní ibùdó Uba Umuaka ni;
- Àdó olóró tí wọ́n ti ṣe kalẹ̀
- Ọ̀pá Cannon Steel méjìdínlọ́gọ́ta
- Hámà
- Báàgì kan àbọ̀ Potassium Nitrate
- Imi ọjọ́ tí ìwọ̀n rẹ̀ tó ọgbọ́n pọ́ùn
- Iyẹ̀pẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ tó ogójì pọ́ùn
- Iyẹ̀pẹ̀ pupa báàgi méjìdínlọ́gọ́ta
- Ẹtù ìbọn tí ìwọ̀n rẹ̀ tó ọgbọ́n pọ́ùn
- Ìdajì àpò èédú
- Bátìrì ọ̀kadà ọgbọ̀n àti
- Irin méje ti gígùn rẹ̀ jẹ́ ogójì mítà

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kíkan ní Imo
Ìkọlù àwọn ọlọ́pàá ní Uba Umuaka yìí ni yóò jẹ́ ìkejì tó gbópọn láàárín ọ̀sẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ Imo.
Ní ọjọ́ Ajé ni àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ àti àwọn agbébọn kọjú oro síra wọn ní Orlu.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun Onyema Nwachukwu ní ọmọ ikọ IPOB kan àti àwọn ọmọ ikọ̀ ESN bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.



















