Ogun rape case: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun mú afurasí tó fipá bá èèyàn lòpọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi
Iléeṣẹ́ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ti mu ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdun kan, Ajibola Akindele, to fi ipa ba obìnrin lopọ ninu ṣọọṣi.
Ọwọ tẹ Akindele lọjọ kejidinlogun, oṣù Kẹrin, lẹyin ti iya ọmọbìnrin naa to jẹ ogun ọdún, fi ẹjọ́ sun ni agọ ọlọpaa to wa ni Lafenwa.
Iya naa sọ pe oun ran afurasi, ati ọmọ oun obinrin, lati lọ ṣe ṣọọṣi kan ni ọ̀ṣọ́ igbalode, ládùúgbò Ita Oshin lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022.
- Awakọ̀ ṣekúpa òṣìṣẹ́ LASTMA
- Ẹ̀yà Igbo ni ipò Ààrẹ kàn, tá a ba fẹ́ àlàáfíà àti àìṣègbè - Adebanjo
- "100m tí APC ń bèrè fún owó fọ́ọ̀mù kò ní jẹ́ kí àwọn tó nífẹ́ aráàlù dé ipò ìjọba"
- Rádaràda lẹ̀yin olórin ẹ̀mí tẹ́ẹ̀ ń ṣí ara sílẹ̀, tún kó elégbè mẹ́rin kó máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ onílù - Senwele Jesu
- Wo iye tó san to bá fẹ́ lọ sí Hajj ọdún yìí
- Mo tọrọ àforíjì lórí fídíò tí mo gbé jáde, tó ń mú àwọn èèyàn pè mí - Bukunmi Oluwashina
- Wo bí o ṣe lè so fóònù rẹ pọ̀ mọ́ àwọn ǹkan tí ọmọ rẹ ń wò lórí fóònù rẹ̀
- Ṣé lóòtọ́ ni pé mo leè jẹ́ ''virgin" kí ẹ̀jẹ̀ má sì yọ lálẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó? - Ìwádìí fìhàn
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá sọ ìgbà tí wọ́n ó gbé ọkọ akọrin Osinachi tó dolóògbé lọ sí iléẹjọ́
"Nigba ti wọn de ile ijọsin naa, wọn ba awọn obinrin kan to n gba ilẹ ṣọọṣi, ní imurasilẹ fun isin ọjọ́ Aiku.
" Ṣùgbọ́n ni kete ti awọn obinrin naa lọ, to si ku Akindele ati ọmọbìnrin naa nikan, lo fi ipa balopọ ninu ṣọọṣi naa."
Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ pe ni kia ti awọn ọlọpaa gbọ́, ni wọn dọdẹ rẹ titi ọwọ fi tẹ ẹ.
"O si ti jẹwọ pe lootọ ni oun hu iwa naa."
Bakan naa ni kọmisanna ọlọpaa, Lanre Bankole ti pàṣẹ pe ki ẹka ọtẹlẹmuyẹ tẹsiwaju ninu iwadii ati eto fún gbigbe e lọ sile ẹjọ́.
Wòlíì tó fí àbẹ́là gbígbóná jó ọmọ ọdún mẹ́tàlá lójú ara r'ẹ́wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wolii ijọ alaṣọ funfun kan to da abẹla gbigbona soju ara ọṣọrọ ọmọge kan ti gba idajọ ijiya lọwọ ile ẹjọ.
L'Ọjọbọ ni adajọ ran arakunrin Mishack Aguebere lẹwọn ọdun meji lẹyin ti wọn ri pe o jẹbi ẹsun ifipabanilopọ ati ilokulo ọmọde.
Ile ẹjọ majisireeti to wa ni Port Harcourt to jẹ olu ilu ipinlẹ Rivers ni wọn ti ran lọ sẹwọn.
Gẹgẹ baa ṣe gbọ, ọmọ ọdun mẹtala yi jẹ ọmọ to wa labẹ akoso Aguebere.
Niṣe ni ileeṣẹ ọlọpaa fẹsun kan Aguebere labẹ ofin iwa ọdaran Naijria abala okoolenigba ati meji ti ipinlẹ Rivers.
Wọn fẹsun kan pe o fipa lajọṣepọ pẹlu ọṣọrọ ọlọmọge naa to jẹ ibatan iyawo rẹ.
Ọmọ obinrin yi n gbe pẹlu wọn ninu ile ijọsin ijọ alaṣọ funfun wọn to wa ni adugbo Rumuomasi, Port Harcourt.
- Ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ló le yanjú ìṣòro ètò ààbò tó mẹ́hẹ - Obasanjo
- Awakọ̀ ṣekúpa òṣìṣẹ́ LASTMA
- Rádaràda lẹ̀yin olórin ẹ̀mí tẹ́ẹ̀ ń ṣí ara sílẹ̀, tún kó elégbè mẹ́rin kó máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ onílù - Senwele Jesu
- Ṣé lóòtọ́ ni pé mo leè jẹ́ ''virgin" kí ẹ̀jẹ̀ má sì yọ lálẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó? - Ìwádìí fìhàn
'Wolii ja ibale ọmọdebinrin yi'
Majisireeti agba Felicitas Amanze to gbe idajọ kalẹ lori ọrọ yi sọ pe niṣe ni wọn fipa ja ibale ọmọdebinrin yi.
Eleyi si mu ki adajọ fẹdun ọkan rẹ han lori ọwọja iṣẹlẹ ifipabọmọde lopọ ati ifiyajẹ ọmọde to n waye ni Naijriria.
"Iwe ayẹwo lati ọdọ awọn oniṣegun sọ pe ohun ti wolii yi ṣe lo mu ki ibale ọmọdebinrin yi faya to si tun ni awọn ipalara miran ti ọlọpaa mnu ba ni ile ẹjọ''
Adajọ Amanze sọ pe ọgbẹ kan ti yoo maa wa lọkan ni nkan ti pasitọ yi ṣe fun ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹtala naa.
Ọwọja iṣẹlẹ ifiyajẹ ọmọde ati ifipabọmọde lopọ ni Naijiria
Igba akọkọ kọ ni yi taa ma gbọ iroyin nipa iṣẹlẹ iwa ifipabọmọde lopọ.
Ọpọ igba lawọn to dagba, alagbatọ ati awọn mii to n tọju ọmọde maa n huwa ifiyajẹni si awọn ọmọ to ba wa ni ikapa wọn.
Loṣu Kẹta ọdun 2022 ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria mu pasitọ kan lori ẹsun pe o ba awọn ọmọdekunrin mẹta lopọ gba oju idi wọn.
Afurasi taa n wi yi lolori ijọ kan to wa ni adugbo Ajegunle ni ipinlẹ Eko.
- Mo tọrọ àforíjì lórí fídíò tí mo gbé jáde, tó ń mú àwọn èèyàn pè mí - Bukunmi Oluwashina
- Wo bí o ṣe lè so fóònù rẹ pọ̀ mọ́ àwọn ǹkan tí ọmọ rẹ ń wò lórí fóònù rẹ̀
- Wo ìjìyà tó wà fún pínpín fọ́rán ìbálòpọ̀ ọmọdé lórí ayélujára
- Fídíò Chrisland, ikú Sylvester Oromoni, àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọ gbì tó wáyé láwọn ilẹ ẹ̀kọ́ girama
Awọn ọmọde to fipa ba lopọ yi jẹ ọmọ ọdun mẹẹdogun, mejidinlogun ati ogun ọdun.
Loṣu Kejila ọdun 2021 dokita kan ni ipinlẹ Delta sọ pe oun fipa ba ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹẹdogun to jẹ ọmọ ọdọ rẹ.
Oludasilẹ ajọ ẹlyinjuaanu Behind Bars Human Rights Foundation, Harrison Gwamnishu, sọ pe eeyan kan lo tawọn lolobo pe iru nkan bayi n ṣẹlẹ.
Gwamnishu sọ pe ṣaaju ki dokita yi to fipa ba ọmọde naa lo pọ, o nioun fẹ yẹ oju ara rẹ wo boya ko tii mọ ọkunrin.
Eleyi jẹ ọkan lara awọn iru iṣẹlẹ yi to n waye lemọlemọ ni Naijiria
Adajọ Amanze to gbe idajọ kalẹ ni Port Harcourt sọ pe awọn ọmọdekunrin ati obinrin nilo aabo topeye lọwọ awọn to n gbero lati ẹ aburu si wọn.
















