Penis in Padlock: Ọkùnrin tó fi nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sínú àgádágodo torí adùn ìbálòpọ̀ wọ gàù

Oríṣun àwòrán, dailystar.co.uk
Ọrọ buruku t'ohun ti ẹrin. Boya ẹfun ni, tabi eedi ni ka pe, a ko ti ẹ mọ orin ti eeyan i ba kọ si iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ si arakunrin kan.
Niṣe ni ọkunrin naa fi ọwọ ara rẹ se ara rẹ pa, lẹyin ti nkan ọmọkunrin rẹ há sinu agadagodo 'padlock' fun ọsẹ meji gbako.
Ẹyin naa sọ pe ha! Ọrọ to gbẹnu tan, to ya ni lẹnu silẹ dẹẹrẹ-dẹẹrẹ ni ọrọ ọkunrin naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo tún ibojì Funmi Martins ṣe torí ojú ń tì mí nípa ipò ìtìjú tó wà - Ashabi Olorisha
- Àwọn egungun ẹ̀yìn mi lágbo tíátà ní Adebimpe Oyebade fi ọ̀nà ẹ̀bùrú gbà mọ́ mi lọ́wọ́ - Yomi Fabiyi
- Buhari kò jẹ́ kí Yoruba àtàwọn ẹ̀yà míràn gbérí ní Naijiria - Ẹgbẹ́ Yoruba VOR
- Wo àwòrán bí ìrìnàjò Hajj ṣe n lọ ní Mecca lásìkò Covid-19
- Ọmọ Elebuibon tó jẹ́ òṣèré tíátà àti ìyá awo figbe ta lórí ìdẹ́yẹsí tó ń kojú - Oyin Elebuibon
- Ẹ̀yin aṣọ́bodè, ẹ yé ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀ mọ́, agbègbè wa kìí ṣe ibùdó ogun - Olu ti Igboora
- À kò ní le è máa káwọ́ gbera mọ́ nípa àwọn ìkọlù ìgbà gbogbo nílẹ̀ Yorùbá- Gani Adams
- Inú mi dún, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà fún nǹkan ti mo da- Mary Daniel
- Ẹ wo bí àwọn ajínígbé ṣe gbé ọmọ ọdún 12 sí inú pósí láàyè
Iroyin sọ pe niṣe ni arakunrin yii, ki nkan ọmọkunrin rẹ sinu iho agadagodo kan.
Iya ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji naa, sọ fun awọn akọroyin pe ọmọ oun fẹran lati ma a ki nkan ọmọkunrin rẹ si inu iho kekeeke.

Oríṣun àwòrán, dailystar.co.uk
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ, ṣe oju orun lo ti ṣe e ni, tabi o mu ọti yo?
Ọkunrin naa to jẹ àpọn, to si n gbe ni orilẹ-ede Thailand ni iroyin sọ pe, o fi agadagodo onirin naa yii ọrun nnkan ọmọkunrin rẹ ka, lati ni adun ibalopọ, to si ti i pa.
Amọ ọrọ bẹyin yọ fun nigba to fẹ ẹ ṣi, ṣugbọn ti kọkọrọ agadagodo naa ti sọnu.
O gbiyanju titi lati yọ agadagodo kekere naa, ṣugbọn òfo ni igbiyanju rẹ ja si. Lo ba fi silẹ sibẹ fun ọsẹ meji o le.
Kato o wi, ka to o fọ, kokoro aifojuri wọ inu nnkan ọmọkunrin rẹ, ni irora ba bẹrẹ ninu agọ ara rẹ, eyi to mu ko sare lọ sileewosan kan nilu Bangkok.
Iya arakunrin naa ṣalaye fun awọn oṣisẹ eto ilera ṣe itọju rẹ nile pe "ko ni ọrẹbinrin to jẹ ololufẹ rẹ".
"Airikan ṣe kan lo mu ko ṣe nkan to sẹ, nitori pe kii fi bẹẹ jade mọ nitori itankalẹ Covid-19.
- Ọ̀yẹ̀ yóò là fún abẹ́rẹ́ ìfètòsọ́mọbíbí fáwọn ọkùnrin láìpẹ́
- Wo bí ìbálòpọ̀ tó gbóná giri-giri ṣe le ran tọkọtaya lọ́wọ́ láti kojú ìpèníjà
- Wo ìdí méje tí olólùfẹ́ rẹ fi le kọ ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ
- Bó o bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tó o lè kó lójú ara rẹ
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí ìyá mi fi sọ fáráyé pé mo ti kú
"O sọ fun mi pe oun ṣe nkan naa nitori pe oun ko ri nkan ṣe, ati pe oun fẹran lati ma a ki nkan ọmọkunrin oun si inu iho kekeeke.
"Mo binu si fun bo ṣe fi mi ṣe ẹlẹya yii, mo si ti sọ fun pe ko ma ṣe iru rẹ mọ."
Pẹlu iṣẹ abẹ si ni awọn dokita fi ge agadagodo naa kuro lara nkan ọmọkunrin rẹ, ti ipalara to ti mu ba a si lagbara ju nkan ti awọn dokita lero lọ.
Eyi gan-an lo fa a ti wọn fi sare gbe digba-digba lọ sileewosan.
Wọn lo ju ọgbọn iṣẹju lọ lati fi irinṣẹ to n lo ina ijọba lati fi ge agadagodo naa.
Koda, wọn ni lati fi irin pelebe kan si aarin irin agadagodo ati ẹran ara ọkunrin yii, ko ma ba a ni ifarapa.

Oríṣun àwòrán, dailystar.co.uk
Bakan naa ni wọn n fi omi wọn ara rẹ yika ibi ti agadagodo wa.
Ẹnikan lara awọn to doola rẹ, Thongchai Donson sọ pe niṣe lo n pariwo nileewosan, nitori irora to ni.
O ni awọn fi orukọ bo ọkunrin naa laṣiri, ṣugbọn ki awọn eeyan fi ọrọ rẹ kọgbọn.
Botilẹ jẹ pe o ti gba ominira kuro ninu ide afọwọfa, awọn eleto ilera sọ pe o sẹ e ṣe ki akoba ayeraye ti wa lara rẹ, nitori iye asiko ti agadagodo naa lo nibẹ.
Wọn tun sọ pe nkan ọmọkunrin naa ko ri boṣeyẹ ko ri mọ.















