Lagos Amputee: Mary Daniel di oníle àti ilé iṣẹ́ l'éko

Yorùbá bọ̀ wọ́n ni bí orí bá pẹ́ nílẹ̀ yóò díre, kí ọ̀rọ̀ sì tó dayọ̀ ojú ti rí.
Èyí ni ọ̀rọ̀ Mary Daniel obìnrin ẹlẹsẹ̀ kan tí òkíkí rẹ̀ kan lásìkò tí ẹnikan ya fótò rẹ̀ nibi ti ó ti ń ta omi tutu ni agbègbè Oshodi.
Lósàn òní ni Mary Daniel ṣe ìṣílé àti àfilọlẹ ilé iṣẹ ''Pure water" tó ń kọ́ lọ́wọ́.
- Ènìyàn 80 ló ti d'òkú nítori òjò àrọ̀rọdá tó fa omí yalé agbara ya sọọbù
- Bí ọkọ mi ṣe fi ẹ̀wọ̀n irin dè mí mọ́ bẹ́ẹ̀dí tó fipà bá mi lòpọ̀ títí oyún fi bàjẹ́ lára mi'
- Kí ló fa omijé lójú alàgbà tó kọ orin àkọmọ̀nà NYSC ní Nàìjíríà?
- Akeredolu, NUJ àtàwọn míì ń ṣèdárò Bunmi Afuye tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè lọ l'Ondo
Gẹ́gẹ́ bí Mary ṣe sọ, àlá òun ló wá sí ìmúṣẹ nítorí àṣeyọrí òun láàrín àsìkò ránpẹ́ yìí jẹ́ ìpinu àti ìrònú àwọn ènìyǹ mííràn tó ti n gbá ilú Eko lati ọjọ́ pípẹ́.
Ilé àti ilé iṣẹ́ omi tó wà ni agbègbè Igando ni ìlú Eko ṣàlàyé pé òun dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó jẹ́ kí ìpínnu àti èròngbá òun wá sí ìmúṣẹ́.

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Lásìkò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí BBC ṣe ni Mary Daniel ti ṣàlàyé pé, mílíọ̀nù mẹ́tàdínlogún àti àbọ̀ ni òun ra ilé náà àti pé òun ti ni àwọn olùgbẹ ilé méjì tí òn ń gba owó ilé lọ́wọ́ wọn.
Mary ni bí mílíọ̀nù márùndílọ́gbọ̀n ní ààwọn ọmọ Nàìjíríà dá fún òun .
Nínú ìfọ̀rọ̀wánílẹ́nuwò náà ni obìnrin náà ti fi kún pé òun ti ra àwọn irinṣẹ tí wọ́n fi n ṣe omi inu ọ̀rá.
O fi kún pé àwọn nǹkan tí ó kù tí òun kò ti ni báyìí ni tánkì omi, fífá iná sí inú ilé iṣẹ́ ọ̀hún àti rírẹ́ ilẹ̀ ibẹ̀.
Lórí ọ̀rọ̀ ẹbí rẹ̀, Daniel ṣàlàyé pé òun kò ni ẹbi tàbí ará, àwọn ọmọ Nàìjíríà tó dìde ìrànlọ́wọ́ fún òun ni òun mọ.
Nǹkan mííràn tí Mary Daniel t;ún só ni pé kìí ṣe ibi ìjàmbá ọkọ̀ ni òun ti kán lẹ́sẹ, bákan náà ni ìyá àti bábá òun kò kú nínú ìjamba ọkọ
Mary Daniel ni òun kò lé dáríji bàbá òun nítori kò sí nibẹ̀ lásìkò tí oùn nílò rl, bákan náà si ni ìyá bábá òun kò ni ànfani láti wá gbé pẹ̀lú òun mọ́ lẹ́yìn tó ti ké gbàjare síta pé gbogbo nǹkan ti òun sọ fún àwọn oníròyìn lákọ́kọ́ kìí ṣe òótọ́.
















