Obi Cubana: Mọ̀ si nípa olówó yalumọ tó fi ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù sìnkú ìyá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, obi_cubana/Instagram
Lati igba ti Obi Cubana ti ṣe ayẹyẹ oku mọmọ rẹ, eyi ti aye gbọ, ti ọrun si mọ ni awọn eeyan ti sọrọ rẹ lori ayelujara.
Cubana, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta padanu iya rẹ ninu oṣu kejila ọdun 2020.
Cubana ṣe ohun manigbagbe lẹyin to sin iya rẹ pẹlu ẹgba ọrun, ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọrun owo dola, $100,000, eyi to jẹ kí gbogbo aye mọ nipa ilu rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Seyi Makinde, yé dá ìjọba ṣe, wá nǹkan ṣe lórí ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ́"
- Adójútini ni Bíṣọ́bù Kukah lórí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa Buhari l'Ámẹ́ríkà - iléeṣẹ́ Áàrẹ
- Ọkọ Lizzy Anjorin fí ẹ̀bùn ọkọ̀ N20m fi ta lọ́rẹ
- Buhari kò jẹ́ kí Yoruba àtàwọn ẹ̀yà míràn gbérí ní Naijiria - Ẹgbẹ́ Yoruba VOR
- "Mo fi nǹkan ọkùnrin mi sínú àgádádogo fún ọ̀sẹ̀ méjì fún ìbálòpọ̀, wàhálà bá de"
- Àwọn egungun ẹ̀yìn mi lágbo tíátà ní Adebimpe Oyebade fi ọ̀nà ẹ̀bùrú gbà mọ́ mi lọ́wọ́ - Yomi Fabiyi
- Wo àwòrán bí ìrìnàjò Hajj ṣe n lọ ní Mecca lásìkò Covid-19
- Mo tún ibojì Funmi Martins ṣe torí ojú ń tì mí nípa ipò ìtìjú tó wà - Ashabi Olorisha
A bi Cubana ni ọjọ kejila oṣu kẹrin ọdun 1975 ni ilu Oba, ni ijọba ibilẹ Idemili nipinlẹ Anambra.
Obinna Iyiegbu ni orukọ abisọ rẹ, to si jẹ ọmọ kẹrin fawọn obi rẹ, oun naa si lo jẹ abigbẹyin ọkunrin fawọn obi rẹ.

Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Central Primary School ni Cubana ti bẹrẹ ẹkọ rẹ, o tẹsiwaju ẹkọ rẹ nile iwe girama Dennis Memorial Grammar School.
Ẹkọ nipa eto oṣelu ni Cubana gboye ninu rẹ ni fasiti UNN niluu Nsukka lọdun 1998.
Cubana da ile ijo ti o pe orúkọ rẹ ni "Ibiza Club" silẹ niluu Abuja lọdun 2006.
Lẹyin ti idasilẹ Ibiza Club so eso rere, ni Obi da ile itura to pe ni Cubana silẹ lọdun 2009 silẹ, nibi tawọn gbajumọ to gbafẹ ti n gbadun ara wọn.
Ipinlẹ Imo ni Cubana ti kọkọ bẹrẹ.
Ṣugbọn lonii, o ti kaakiri ọpọ ipinlẹ ni Naijiria bíi ipinlẹ Eko, Abia ati Enugu.
Oun ni alaga ile iṣẹ Cubana Group, o ṣi n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn eeyan bii tiẹ.
Ọkan lara awọn eeyan bẹẹ ni Paschal Okechukwu to jẹ adari Cubana to wa niluu Owerri at'awọn ile mii.
O n ṣiṣẹ lọwọ lori idasilẹ Cubana ni Dubai ati owo kara kata ilẹ ati ile.
Ebele Iyiegbu ni aya Cubana, amofin ni, Eledua si fi ọmọkunrin mẹrin t'awọn lọrẹ.
Cubana ti gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ bi "Democracy Heroes 2018" ati ''Ghana-Nigeria Achievers Award 2017."
Cubana ni ile nla nla awo dami ẹnu kaakiri Naijiria pẹlu awọn ọkọ bọginni bii Mercedes Benz 4matic S40, Lexus LX, Bentley at'awọn ọkọ miran.
Gbogbo dukia jẹ ẹẹdẹgbẹta miliọnu owo dọla, $500,000,000.
Ohun ti o maa n sọ julọ ni pe "ilẹ aye yii tirẹ ni."
Awọn ile ijo rẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria to biliọnu meji owo dọla, $2,000,000,000.

Cubana Chief Priest ra màálù 46 fún ìsìnkú ìyá ọ̀gá rẹ̀, àwọn ọmọ Naijiria ń fi èrò wọn hàn

Oríṣun àwòrán, Cubana/Instagram
Oriṣiriṣi ọrọ ni awọn ọmọ Naijiria ti n sọ nitori bi gbajugbaja onile ọtí, Cubana Chief Priest, ṣe ra maalu mẹrindinlaadọta fun ọga rẹ.
Oju opo ayelujara Instagram rẹ ni gbajúmọ naa, ti orúkọ abisọ rẹ n jẹ Chibuike Okechukwu ti safihan àwọn maalu naa.
O ni oun ra maalu to pọ bẹẹ lati fi ṣe atilẹyin fun ọga oun to n ṣe isinku iya rẹ.
Bakan naa lo tun sọ pe iye maalu ti oun ra, ni iye ọjọ ori Obi Cubana to jẹ Ọga rẹ.
Yatọ si maalu 46 yii, Obi Cubana fun'ra rẹ sọ pe o le ni igba maalu ti oun ti ri gba lọwọ awọn ọrẹ òun.
- Mọ̀ si nípa agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Ìwọ́de tí apá ọlapáà ò ní ká ń bọ̀ l'Eko tí wọn bá kọ̀ láti fi àwọn èèyàn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua
- Ṣé ìwọ mọ ìtàn Ọdẹ tó tẹ Ẹ̀pẹ́ dó láti ìgbà ìwásẹ̀?
- 'Restructuring' la fi ta Buhari fún ìran Yorùbá, ṣùgbọ́n ó dùn mi pé irọ́ ni Buhari pa- Olagunsoye Oyinlola
- Títí di bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, èmi gan an kò mọ irú ẹni tí Wole Soyinka jẹ́- Ojọ̀gbọ́n Wole Soyinka
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
- Wo bí o ṣe le fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ tàbí gba ọ̀rọ̀ lórí WhatsApp láì lo fóònù rẹ
Ohun ti awọn ọmọ Naijiria si n sọ ni pe maalu 46 ti pọ ju lati fun ẹni kan.
Sugbọn awọn kan tun n kì í pe o kare lai.
Taa ni Cubana Chief Priest?
Gbajúmọ̀ onisowo ọtí ni Pascal Chibuike Okechukwu.
O si tun jẹ olookowo ni ẹka amuludun ati igbafẹ - òun lo ni ile igbafẹ Club Xhrine to wa nilu Owerri, nipinlẹ Imo.
Ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun 1981,ni wọn bi Cubana Chief Priest ni ilu Umuhu Okabia, nijọba ibilẹ Orsu, ipinlẹ Imo.
Oun ni ọmọkùnrin keji ti awọn obi rẹ bi.
Ìṣẹ bàtà ṣíṣe lo kọ nilu Aba, nipinlẹ Abia.
Lẹyin naa lo lọ si ile ẹ̀kọ́ Federal Polytechnic to wa ni Nekede, Owerri, nibẹ lo ti gba iwe ẹri imọ ijinlẹ akọkọ.
Ni ibẹrẹ ọdun 2021, o gba oye Ọmọwe ninu imọ ijinlẹ nípa amojuto Ayẹyẹ ṣíṣe ati okoowo Igbafẹ, ni European-American University, sugbọn ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin lo fi ikede nipa rẹ sori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Obi Cubana
Ohun to yẹ ki o mọ nipa Obi Cubana to n ṣe òkú iya rẹ
Onisowo igbafẹ ati faaji ni Obinna Iyiegbu, ti inagijẹ rẹ n jẹ Obi Cubana .
Ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ni, lati ijọba ibilẹ Idemili, nipinlẹ Anambra.
Ilu Onitsha lo ti lọ si ile ẹ̀kọ́ girama, ko to o lọ si University of Nigeria, Nsuka, nibi to ti gba iwe ẹri ninu imọ oṣelu lọdun 1998.
Ọdun 2008 lo ṣe igbeyawo, o si bi ọmọ mẹrin.
Obi Cubana n ṣe isinku rẹ, Lady Uche Inyiegbu, to kú ni ẹni ọdun mejindinlọgọrin.
















