WhatsApp: Àwọn èèyàn lè máa lo 'App WhatsApp' láì sí fóònù lọ́wọ́ wọn

Oríṣun àwòrán, Facebook/Whatsapp
Ileesẹ ayelujara WhatsApp ti n dan eto kan wo, eyi ti yoo mu ki awọn eeyan le fi ọrọ ránṣẹ lai lo foonu wọn.
Lọwọ lọwọ, ori foonu nikan ni àṣẹ wa lati lo WhatsApp, to si jẹ pe lai si foonu naa nitosi, ko seese láti lo WhatsApp lori ẹ̀rọ kọmputa.
Sugbọn, pẹlu eto tuntun yii, awọn to n lo WhatsApp yoo le fi ọrọ ránṣẹ tabi gba ọrọ lati ọdọ ẹlòmíràn "koda, ki batiri foonu rẹ ti ku".
- Mọ̀ si nípa agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Ìwọ́de tí apá ọlapáà ò ní ká ń bọ̀ l'Eko tí wọn bá kọ̀ láti fi àwọn èèyàn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua
- Ṣé ìwọ mọ ìtàn Ọdẹ tó tẹ Ẹ̀pẹ́ dó láti ìgbà ìwásẹ̀?
- 'Restructuring' la fi ta Buhari fún ìran Yorùbá, ṣùgbọ́n ó dùn mi pé irọ́ ni Buhari pa- Olagunsoye Oyinlola
- Títí di bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, èmi gan an kò mọ irú ẹni tí Wole Soyinka jẹ́- Ojọ̀gbọ́n Wole Soyinka
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
Eeyan perete ni yoo kọkọ lo eto tuntun naa, diẹ diẹ si ni wọn o ma a mu gbooro si titi gbogbo eniyan yoo fi le lo o.
Bakan naa ni eto basiri mi, End-to-end encryption, eyi to n pese aabo fun awọn to lo WhatsApp, yoo si sisẹ lori eto tuntun naa.
Iroyin sọ pe ọpọlọpọ miliọnu eeyan lo ti n fẹ eto tuntun yii.
Bawo ni eto tuntun ori WhatsApp yoo se lọ?
Ninu ikede ti wọn fi sita, àwọn amoju ẹ̀rọ nileesẹ Facebook sọ pe ayipada yii nilo ki wọn o tun ero pa lori agbekalẹ WhatsApp.
Idi ni pe "smart phone" ni ọna gboogi ti WhatsApp ti n sisẹ, ohun naa si ni atọna fun awọn ẹrọ to ku bi kọmputa.
Eyi tumọ si pe ọna kan ṣoṣo ni o ti le ṣi WhatsApp silẹ lẹyin foonu rẹ. Ti o ba ṣi ni ibòmíràn, ọna keji yoo pa de fúnra rẹ.
"Eto tuntun yii yoo mu ìṣòro yii kuro.
"O ko nilo foonu rẹ lati lo WhatsApp lori kọmputa rẹ."
Gbogbo ẹrọ, foonu, tabi kọmputa ti o fi n lo WhatsApp ni yoo ni ami idanimọ rẹ, botilẹjẹ pe ẹnikan ṣoṣo lo ni wọn.
Sugbọn, Jake Moore, onimọ nipa eto abo fun ileesẹ Eset to n ṣe 'anti virus' sọ pe iru nkan yii le pagidina eto aabo lori foonu.
O ni ọkọ tabi aya to jẹ oníwà ipa ninu ile tabi ẹni to n sọ eeyan, le lo anfaani naa lati tọ pinpin ẹni ti wọn fẹ ẹ mu, nipa ṣíṣí WhatsApp rẹ lori foonu miran.
O sọ pe o ṣe pataki ki awọn eeyan mọ iye foonu, kọmputa tabi awọn ẹrọ ayarabiasa mii to n lo WhatsApp wọn.












