Femi Falana: Ọwọ́ tí Buhari fi mú mú ọ̀rọ̀ Kanu àti Igboho jọ èyí tí wọ́n fi mú olóṣèlú kan lọ́dún 1984

Femi Falana

Oríṣun àwòrán, Cool FM 96.9 Kano

Ajafẹtọ ọmọniyan ati agbẹjọro agba, Femi Falana ti sọ pe awọn igbesẹ ti Aarẹ Naiijiria n gbe yoo da Naijiria pada si ọdun 1984, ṣugbọn awọn araalu ko ni gba fun.

Falana lo sọ ọrọ naa nibi ijiroro kan lati sami si ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹ́tàdínláàdọ́rùn ún Ọjọgbọn Wole Soyinka loke eepẹ.

Agbẹjọro naa ṣo pe ọwọ ti ijọba Buhari fi mu ọrọ Nnamdi Kanu ati Sunday Igboho farajọ eyii ti wọn lo lati fi ji oloṣelu kan gbe lọdun 1984.

O ni "Ko yẹ ki a gba Buhari laaye lati da wa pada si ọdun 1984 bii igba ti wọn gbiyanju lati ji Umaru Diko gbe ni London."

"Wọn ti ji Diko gbe tan lọdun naa lọhun, ṣugbọn ara adugbo kan lo figbe ta lasiko ti wọn n gbe lọ si papakọ ofurufu."

Àkọlé fídíò, Ibeju Lekki Free Trade Zone: A ti bí ọmọ tó lọ Fásitì tí kò rí iná ọba rí- Olawale Eleto

Falana ṣalaye pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ṣe ni wọn kun Nnamdi Kanu loorun ki wọn to gbe wa si Naijiria nitori ijọba Kenya ko le ṣalaye pe awọn finu-findọ fa Kanu le ijọba Naijiria lọwọ.

O ni irọ ni awọn to sọ pe ọna to ba ofin mu ni wọn fi gbe Kanu wa si Naijiria n pa.

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

Ajafẹtọ naa fikun pe eremọde lasan ni awọn to ni ki awọn araalu má ṣe ifẹhonuhna n sẹ nitori ironu awọn ologun lo wa ninu ọpọlọ wọn.

O sọ siwaju si pe Buhari ti gbagbe pe awọn ti gbe Aarẹ Olusegun Obasanjo lọ sile ẹjọ lọdun 2003 ri, lẹyin ti Obasanjo tu iwọde kan ti Buhari ti kopa ka, ti Buhari si jare lati ile ẹjọ ọhun.

O ni ile ẹjọ naa sọ pe ko ba ofin mu ki eeyan kọkọ lọ gba iwe aṣẹ lọwọ ọlọpaa ko to ṣagbatẹru iwọde tabi kopa ninu iwọde kankan, ati pe awọn eeyan to ti gba ominira ko nilo iwe aṣẹ ọlọpaa kankan ki wọn to ṣe iwọde.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Falana ni eredi ree ti awọn fi gbogun ti ile igbimọ aṣofin lati ṣe ofin tuntun kan to sọ pe awọn araalu ko nilo lati fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti ki wọn to ṣe iwọde, ayafi ki wọn wa pese eto abo fun wọn, kii ṣe lati gba aṣẹ.