Buhari Kano visit: Aarẹ Muhammadu Buhari yóò gúnlẹ̀ sí Kano láti fi ìpìlẹ̀ ojú ọna irin lélẹ̀

Kano

Oríṣun àwòrán, @Kano Govt

Oju ọna irin tuntun yi ni ireti wa pe yoo tun lọ lati Kaduna si Abuja, ati Abuja si ipinlẹ Eko.

Ipinlẹ Kano jẹ pataki ibi ọrọ aje ni Naijiria, nibi ti awọn eeyan jakejado orilẹ-ede Naijiria ati agbaye ti n ṣe katakara.

Ọjọ ti pẹ ti awọn eeyan kan nipinlẹ naa ti n kùn pé Aarẹ Buhari, ti pa Kano tì lati igba to ti de ipo, botilẹ jẹ pe awọn ṣe atilẹyin nla fun nigba to du ipo aarẹ.

Àmọ́, awọn kan ti woye pe ipilẹ oju ọna irin ti Buhari fẹ ẹ wá ṣe fihan pe ko gbagbe awọn eniyan ipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Okunade Sijuwade: Ìfẹ́ tí Sarun tó súnmọ́ Ooni jù láyé ní sí í ló sọ ọ́ di abọ́bakú- Adeye

Aarẹ Buhari yoo tun sí àwọn akanse isẹ ti Gomina ipinlẹ naa, Abdullahi Umar Ganduje ṣe.

Buhari

Oríṣun àwòrán, femi Adesina

Oríire ńlá ló jẹ́ fún àwọn ọmọ Naijiria pé orílẹ̀-èdè yìí ṣì wà ní ọ̀kan ṣoṣo- Buhari

Gbogbo agbára mi ni mo máa fi sin Naijiria

Buhari pari ọrọ rẹ pe ajọṣepọ laarin gbogbo ẹka ijọba atawọn araalu nikan lo le mu idagbasoke ba Naijiria.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

Aarẹ Muhammada Buhari ti sọ pe oriire nla lo jẹ fun awọn ọmọ Naijiria pe orilẹ-ede naa ṣi wa ni ọkan ṣoṣo bo tilẹ jẹ pe o n dojukọ oniruru iṣoro.Ààrẹ Buhari ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn sẹ́nétọ̀ 109 lálẹ́ ọjọ́ Iṣẹ́gun

Buhari

Oríṣun àwòrán, @Presidency

Buhari lo sọ ọrọ naa lasiko to n tẹwọgba esi apero kan lori eto abo Naijiria nile aṣoju-ṣofin.

Agbẹnusọ ile naa, Femi Gbajabiamila lo ko awọn akẹgbẹ rẹ kan sọdi lati fi esi naa le Aarẹ lọwọ.

Nigba to n sọrọ, Buhari sọ pe oun ti pinnu lati sin Naijiria pẹlu gbogbo okun ati agbara oun, ati pe eredi ree ti oun fi ṣabẹwo si gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria lasiko ipolongo ibo lọdun 2015.

Ẹwẹ, Aarẹ tun ti sọ fun awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin agba pe ijọba oun ti ṣetan lati lo gbogbo agbara ti wa ni ikawọ oun lati fopin si eto aabo to mẹhẹ.

Buhari

Oríṣun àwòrán, Femi adesina

O tun ni oun a fi ṣikun ofin mu gbogbo awọn to wa nidi awọn ikọlu to n waye kaakiri Naijiria.

Aarẹ lo sọ ọrọ naa lasiko wẹjẹ-wẹmu kan pẹlu awọn aṣofin naa nile rẹ niluu Abuja.

Àkọlé fídíò, Ibeju Lekki Free Trade Zone: A ti bí ọmọ tó lọ Fásitì tí kò rí iná ọba rí- Olawale Eleto

Agbẹnusọ Aarẹ, Femi Adesina sọ ninu atẹjade kan pe eto abo to mẹhẹ, ikọlu awọn janduku, ijinigbe atawọn iwa ọdaran mii ni iṣoro ti ijọba to wa lode yii n dojukọ julọ.

O ni eto abo to mẹhẹ ko gba ijọba laaye lati ṣe awọn ohun amayedẹrun to lọkan ni lati ṣe fun awọn araalu.

Buhari sọ pe "Pupọ ninu awọn to n ṣiṣẹ ibi naa n ṣe lati pa owo si apo ara wọn, awọn miii si n ṣe wọn lati fun ijọba ni orukọ buburu."

"Ṣugbọn ko ni ṣe eredi ti wọn fi n da rogbodiyan silẹ laarin ilu, ohun ti a mọ ni pe iwa wọn n mu ifaṣeyin ba orilẹ-ede yii."

"Ojuṣe wa gẹgẹ bii ijọba ni lati ri daju pe a ṣe gbogbo ohun to yẹ ninu agbara wa lati jẹ ki wọn foju wina ofin, ki wọn ma si mu oju wa kuro ni awọn afojusun wa gẹgẹ bii ijọba."

Buhari pari ọrọ rẹ pe ajọṣepọ laarin gbogbo ẹka ijọba atawọn araalu nikan lo le mu idagbasoke ba Naijiria.

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb