Nnamdi Kanu: Malami ní Ohaneze Ndigbo lẹ́tọ̀ọ́ láti gba agbẹjọ́rò fún Nnamdi Kanu

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami ti sọ pe ẹgbẹ Ohanaeze Ndigbo lẹtọọ lati gba agbẹjọro to ba wu wọn fun olori IPOB, Nnamdi Kanu.

Malami ni ijọba apapọ ko ni le sọ pe ki ẹgbẹ naa maa gba amofin to wu wọn fun Kanu.

Ninu atẹjade ti o fi sita, Malami lu ẹgbẹ Ohanaeze Ndigbo lọgọ ẹnu lori igbesẹ wọn lori bi wọn ti ṣugbaka Kanu.

Lọjọ Aiku, ọjọ kejila oṣu keje ni ẹgbẹ Ohanaeze Ndigbo pe fun idajọ ododo fun Kanu to jẹ ajijagbara fun idasilẹ orilẹede Biafra.

Amọ, alufaa ijọ Aguda to fi ilu Enugu ṣe ibugbe, Rev. Fr. Ejike Mbaka ti pe fun idasilẹ kanu ni tirẹ.

Fada Mbaka kepe ijọba pe ko le agbara to n lo lori ọrọ Kanu lati wa ojutuu si ọrọ eto abo to mẹhẹ, iṣẹ, airiṣẹ ṣe ati awọn darandaran to n da alaafia ilu ru kaakiri.

O ṣalaye pe Kanu ko payan, ijọba ko si ka ibọn mọ lọwọ, Mbaka ni kilode ti wọn fi mu?

Kanu ti kọkọ sa mọ ijọba lọwọ tẹlẹ ki wọn to tun mun un nilkẹ okeere laipẹ yii.

A ti gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè agbẹjọ́rò tó dántọ́ kí Kanu lè rí ìdájọ́ òdodo gbà - Ohaneze Ndigbo

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ Igbo kaakiri agbaye, Ohanaeze Ndigbo Worldwide ti sọrọ fun igba akọkọ lori bi ijọba apapọ ṣe fi pampẹ ofin mu Nnamdi Kanu.

Awọn adari ẹgbẹ naa sọrọ lẹyin ipade kan ti wọn ṣe niluu Enugu nibi ti wọn ti sọ pe awọn n fẹ ki ijọba Najiria ṣe ẹjọ afurasi ọhun gẹgẹ bii ohun ti ofin Naijiria sọ.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede lẹyin ipade wọn, ẹgbẹ naa sọ pe awọn ko ni ki ijọba apapọ ma ṣe ẹjọ kanu, ṣugbọn ki wọn ṣe ni itẹwọgba pẹlu ofin to bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan kaakiri agbaye.

Wọn ni awọn ti gbe igbeṣe lati pese awọn agbẹjọro to dantọ lọna ati ri daju pe Kanu ri idajọ ododo gba.

Wọn sọ pe agbẹjọro gbogbogbo fun ẹgbẹ ọhun ati gbobgo awọn agbagba ẹgbẹ naa yoo bojuto bi igbẹjọ naa yoo ṣe lọ.

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY

Ohanaeze Ndigbo ni "Ẹgbẹ wa ti fi oju ṣunukun wo bi ijọba ṣe fi ṣikun ofin mu ọmọ wa, Nnamdi kanu ati bi igbẹjọ rẹ ṣe n lọ."

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

"Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ wa ko lodi si igbẹjọ Kanu, a fẹ ki wọn ṣe igbẹjọ ọhun gẹgẹ bii alakalẹ ofin Naijiria ati ni ibamu pẹlu ilana ofin to ṣe itẹwọgba kaakiri agbaye."

Ninu atẹjade ọhun ti agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Chiedozie Alex Ogbonnia fi ṣọwọ si BBC, o ni ọmọ awọn ni Kanu, ọrọ rẹ si ka awọn lara.

Nnamdi Kanu ni aṣaaju ẹgbẹ Indigenous People of Biafra, IPOB, to n pe fun iyapa ẹya Igbo kura lara Naijiria lati da wa gẹgẹ bi orilẹ-ede.

Ṣugbọn lẹyin ti ijọba apapọ fi panpẹ ofin Kanu tan, ọpọ eeyan lo n woye pe opin ti de ba ilakaka ẹgbẹ naa.

Kanu maa n ba awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB sọrọ lati ori ẹrọ asọrọmagbesi Radio Biafra ati lori ayelujara nipa afojusun ẹgbẹ naa ati bi ijọba Naijiria ko ṣe naani ẹya Igbo, ṣugbọn awọn ọrọ naa ko dun mọ ijọba Naijiria ninu.

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni ijọba apapọ mu Kanu nilẹ okeere, ti wọn si gbe wa si Naijiria.

Àkọlé fídíò, Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua

Ṣaaju ni ijọba ti kọkọ sọ pe ilẹ Gẹẹsi ni wọn mu Kanu, ṣugbọn ijọba ilẹ naa ni awọn ko mọ ohun kankan nipa bi wọn ṣe mu afurasi naa, ati pe iroyin ofege ni pe awọn lọwọ ninu rẹ.

Lẹyinorẹyin, iroyin lu sita pe orilẹ-ede Kenya ni wọn ti fi tiaptikuuku gbe wa si Naijiria.