Covid-19 3rd wave: Sanwo-Olu ní ọwọ́jà kẹtàa covid-19 ń kan ìlẹ̀kùn ní ìpínlẹ̀ Eko

Sanwo Olu

Oríṣun àwòrán, @SanwoOlu

Ọwọ́jà kẹtàa covid-19 ń kan ìlẹ̀kùn l'Eko, Sanwo-Olu ké gbàjarè

Lẹyin ti wọn ni itankalẹ arun coronavirus ti n lọọlẹ tẹlẹ nipinlẹ Eko, Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ke gbajare pe ọwọja kẹtaa arun naa n kanlẹkun gbọngbọn l'Eko.

Gomina Sanwo-Olu ni awọn ibudo itọju awọn alarun covid-19 tun n kun fọfọ sii lẹnu ọjọ mẹta yii.

Ninu ọrọ gomina lọjọ Aiku, Sanwo-Olu ni akọsilẹ fihan pe arun naa tun ti pọ si pẹlu ida marun un ninu ọgọrun un laarin ọsẹ meji to lọ.

Aworan Gomina Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Twitter/jidesanwoolu

Ofin tuntun wo ni Sanwo Olu gbe kalẹ?

Sanwo-Olu afaimọ ki ọwọja coronavirus kẹtaa maa ti de ipinlẹ Eko bayii.

Gomina ṣalaye pe eeyan to le lẹgbẹrun lọna ọgọta eeyan ni akọsilẹ fihan pe o ti lugbadi covid-19 nipinlẹ Eko.

Sanwo-Olu ṣalaye pe ẹgbẹrun marun un le laadọta ninu awọn yii lo ti ri iwosan gba.

Gomina ni ida ilaji eeyna ni aaye wa fun lati jọsin ni gbogbo ile ijọsin lasiko yii.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Ọta le lẹẹdẹgbẹrin le mẹwaa ninu wọn lo si n gba itọju lọwọ.

Sanwo-Olu fikun ọrọ rẹ pe lati inu oṣu kẹtaa ni ọwọja keji covid-19 ti bẹrẹ si ni lọọlẹ nipinlẹ Eko.

''Eyi lo jẹ ki ijọba paṣẹ ṣiṣi awọ ileeṣẹ pada lẹyin ti arun naa ti ṣọṣẹ fun bi ọdun kan sẹyin.

Àkọlé fídíò, Fisayo Amodemaja: Nínú eré 'Children Day' ní Sọ́ọ̀ṣì ni Abebi ti bẹ̀rẹ̀ eré ṣisṣe- Bukola

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe pẹlu iṣẹ aṣekara ati igbiyanju wa lati ri pe covid-19 di ohun igbagbe laarin oṣu mẹta sẹyin, o dabi ẹni pe ọwọja kẹta ti n bẹrẹ bayii.

Lati ibẹrẹ oṣu keje ni a ti ṣe akiyesi pe awọn to n ko arun coronavirus nipinlẹ Eko ti n pọ si.

Àkọlé fídíò, Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua

Bi awọn eeyan to karun naa laarin ọsẹ kan jẹ ohun to n kọ wa lominu,'' Sanwo-Olu ṣalaye.

Ṣaaju ni ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC kede pe awọn ti ri ẹni to ni irufẹ covid-19 SARS-CoV-2 Delta eleyii ti wọn sọ pe o maa n ran julọ.

Àkọlé fídíò, TB Joshua Burial: Wolii Synagogue SOAN jẹ́ Akàndá ẹ̀dá- Oba Enitan Ogunwusi, Ooni Ile Ife