Sunday Igboho: Ẹ̀yin Ọba Aládé, ẹ dáríji Sunday Igboho, ẹ má jẹ kí inúnibíni yii borí rẹ̀- Iba Gani Adams

Ẹ̀yin ọba aládé, ẹ dáríji Sunday Igboho, ẹ má jẹ kí inúnibi yii borí rẹ̀- Iba Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Aarfeonakankanfo

Ààrẹ Ọ̀nàkakanfo ilẹ̀ Yorùbá, Otunba Gani Adams ti rọ gbogbo àwọn Ọba aládé nílẹ̀ káàrọ̀-òjíire tó fi mọ àwọn gọmínà àti àwọn olóṣèlú láti dárí ji Sunday Adeyemo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sunday Igboho.

Gani Adams ninu fọ́ran kan to n jà rànyinrànyin ló ti bẹ̀nu àtẹ́ lu ọ̀nà ti Sunday Igboho ń gbà láti bèèrè fún òmìnirà Yorùbá.

Ó ní kàkà kí ó fí ara balẹ̀ bẹ àwọn orí adé lọ́wẹ̀ kí ó sì rí ìfọ̀wọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn, ariwo lásán lo n pa.

Gani Adams ni: "Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀nà tí Igboho n gbà ṣe ìjàgbara rẹ̀ kò bójúmu rárá. Mo sọ fun pé ọ̀nà tọ n tọ kò bójúmu.

" Sùgbọ́n Ọlọrun ti lòó láti jìjàgbara fún ìràn Yorùbá. O tí kó ipá tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì tún se si, kò yẹ kí a fi ààyè sílẹ̀ fún inúnibíní tàbí kí wọ́n paa."

" Bákan náà ló se pàtàkì, ki ó bá àwọn alátẹ̀lé rẹ̀ tó máa n sọ isọkúsọ sọ̀rọ̀, nítori àwọn ní wọn ń fàá sínú wàhálà. Mo sọ fún ni àsìkò kan pé gbogbo àwọn tó yíka jẹ ìràn sẹ a[wọn olóṣèlú ní Eko.

Àkọlé fídíò, TB Joshua Burial: Wolii Synagogue SOAN jẹ́ Akàndá ẹ̀dá- Oba Enitan Ogunwusi, Ooni Ile Ife

Iba ni: "Mó sọ fun kí ó gbáradì fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí ó ba le fọkàn tán, kàkà tí yóò fi maa gbà àwọn ajaguntà tí wọ́n yóò sì tún padà lọ sí ọ̀dọ́ ẹni tí o lówó jùlọ.

"Má dákún ìsòrò ìjìjàgbara yìí. Jẹ́ kí àwọn àgbààgbà dásí, kódà bí ọba kankan bá bẹnu àtẹ́ lu nǹkan tí ó n ṣe, má bú wọn "

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Jẹ́ ki a má a wàásù ìròyìn ayọ tiwa, ó ni òun lọ sí ẹnu ibode láti lọ ṣi. èyi ni ìbẹ̀rẹ̀ ogun , o nílò láti sọ irú nnkan bẹ́ẹ̀, o di danadan yóò lẹ́yìn.

Gani Adams ni Igboho ko ni nnkan ogun ó n fi àwọn ọmọogun ráre, Igboho ni bí àwọn ẹgbẹ̀rún ọlọpàá bá wá sí ilé òun bóyá ni ọgọrun yóò padà láyọ. O ó nílò láti sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

Àkọlé fídíò, Fisayo Amodemaja: Nínú eré 'Children Day' ní Sọ́ọ̀ṣì ni Abebi ti bẹ̀rẹ̀ eré ṣisṣe- Bukola

"Ariwo lásan ni kò si bi yóò se ran ìjàgbara lọ́wọ́.

Gani Adams fi kun un pé, òun ti bẹ Ọọni ile Ife, Alake Egba àti àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yoruba to kù.

" Bí ọmọ bá ṣe bàbá rẹ̀, bàbá máa n dari ji ọmọ ni, ẹ jẹ́ ki à fi ọwọ́ sowọpọ̀ láti jàjàgbara, sùgbọ́n kìí ṣe irú ìlànà tí Sunday Igboho.

Àkọlé fídíò, Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua

Iba ni: "Gẹ́gẹ́ bi ààrẹ ọ̀nà Kakanfo mò n rọ̀ yín láti dárí ji, ó ti bú èmi náà rí, sùgban gẹ́gẹ́ bi olórí, ìdáríjì ṣe pàtàkì.

" Ní ipò ti mo wà yìí, mi ò lé maa fò sóke, sódò bi ti Igboho, sùgbọ́n àtẹ̀jáde ti mo bá fi síta ó lágbára gidi ju ti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn lọ.