DSS VS Sunday Igboho: O tó gẹ́, Sunday Igboho kọ̀wé sí adájọ kí DSS tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀

Ajafẹtọ ọmọ Yoruba Oloye Sunday Adeyemo ti awọn eeyan mọ si Sunday Igboho ti gba ile ẹjọ lọ lati beere fun itusilẹ awọn eeyan rẹ ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS mu.
Ni ile rẹ to wa ni adugbo Soka nilu Ibadan ni wọn ti ko awọn eeyan mẹtala lasiko ti wọn ṣe ikọlu si ile rẹ loruganjọ.
Ile ẹjọ giga to wa ni Abuja ni o ti fi iwe ipẹjọ yi lelẹ gẹgẹ bi iwe iroyin Naijiria Punch ṣe jabọ.
- CAN faraya lórí ikọlù agbofinro sàwọn ajàfẹ́tọ̀ bí Sunday Igboho
- Sunday Igboho kọ̀wé sí ìjọba àpapọ̀, o ní dandan kí wọn sàn owó gbà má bínú ₦500m
- Bí Igboho kò bá jáde, àwa yóò jáde fúnra wá, ìyà pọ̀ - Oluwọde Yoruba Nation
- Àwọn daran-daran ní Nàìjíríà ní ẹgbẹ́ wọ́n sì ní olórí ṣùgbọ́n ẹ kọ̀ láti mú olórí wọn - Wole Soyinka
Iwe iroyin yi bakan naa sọ pe agbẹjọro Igboho Yomi Aliyyu(SAN) jẹri si ọrọ yi fawọn to si ni lỌjọbọ ni awọn kọ iwe si ile ẹjọ giga Abuja ki wọn pa DSS laṣẹ lati tu awọn eeyan yi silẹ.
Agbẹjọro ọhun ko sọ pato nkan tawọn n beere fun ṣugbọn o sọ fun Punch pe agbẹnusọ Igboho, Olayomi Koiki ti fi atẹjade sita ṣaaju.
Ninu atẹjade yi, o sọ pe Koiki ni awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ ko gba awọn agbẹjọro Igboho laaye lati ri awọn to wa ni ahamọ.
Ni idahun si ibeere nkan ti wn fẹ ṣe lati ri pe wọn gba itusilẹ,Aliyu sọ pe''A ti kọwe sile ẹjọ gigaAbuja nipa gbigba oniduro wọn.Loni la kọ.''
Bi a ko ba gbagbe, ni ọjọ Kini Oṣu Keje ni awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣe ikọlu si ile Igboho.
Lẹyin ikọlu yi, DSS sọ pe lootọ lawọn yinbọn pa eeyan meji to doju ija kọ awọn tawọn si ri ohun ija oloro gbaati pe awọn tu mu eeyan mẹtala nibẹ.
Igboho ti fesi lati ẹnu agbẹjọro rẹ pe ko si ohun to jọ bẹ.












