Sunday Igboho: Ẹgbẹ́ CAN ké gbànjarè sí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà lórí àwọn Pásítọ̀ tí o wà lọ́wọ́ ajínigbe

Igboho ati aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorileede Naijiria CAN ti bẹnu atẹ lu bi ijọba Naijria ti ṣe n dunkoko mọ ajafẹtọmọniyan ilẹ Yoruba nii, Sunday Igboho.

Ẹgbẹ naa sọrọ yi ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lori bi nkan ti ṣe ri ni Naijiria.

CAN sọ pe o ṣeni laanu bi awọn agbofinro ti ṣe n ṣe ikọlu sawọn to n ṣe iwọde alaafia bi Sunday Igboho to si ni bi awọn to n bọ lẹyin ba gbọ iru nkan bayi, yoo jẹ iyalẹnu nla fun wọn.

Àkọlé fídíò, 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua, kàyéfì ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mi báyìí'
Àkọlé fídíò, 'Ẹ má jẹ́ kí òkú ọmọ mi ráre o ìjọba! Ẹ gbée fún mi kí n lọ sin ín - Ìyá ọmọ ti wọ́n pa ní ìwọ́de Yoruba Nation

Akọwe apapọ ẹgbẹ naa Daramola Bade ni isọkan Naijiria n mi jolojolo bayi pẹlu bi ijọba ṣe n fọwọ yẹpẹrẹ mu awọn ọdaran ati awọn mii to n gbẹnusọ fun wọn.

Akọle atẹjade yi ni wọn pe ni 'Aarẹ Buhari gbọdọ́ doola Pasitọ Popoola DAVID lọwọ awọn to ji gbe ko si sapa ki Naijiria ma jin si ọfin''

Ninu rẹ, CAN ni ''Araalu ko ni gbagbe ijọba yi lori aile mu ipinu rẹ to ṣe nipa kikoju ipenija aabo ṣẹ ni Naijiria''

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Iṣẹ́ ẹmí ẹtan ló bàlemi lasikọ tí mọ so aṣọtẹlẹ̀ pé wọn o wọ ipele aṣekágbá.

Lati le ṣe atunṣe eyi, o ni ''Aarẹ ni lati yi bo ṣe n ṣe ijọba pada.2023 kii ṣe ohun to pẹ lọ titi.Aarẹ gbọdọ dẹwọ bi awọn ajinigbe ṣe nn ji awọn pasitọ gbe labẹ ijọba rẹ''

CAN tẹsiwaju pe ki aarẹ paṣẹ fun awọn ọga ileeṣẹ ologun ati ọlọpaa lati ṣawari Rev David Popoola ti ijọ Calvary Baptist Church, Kurmin Mashi ni Kaduna State.

Wọn ni awọn ajinigbe gbe Reverend yi lọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ Kẹfa Osu Keje 2021.

Ẹgbẹ naa ni awọn rawọ ẹbẹ si ijọba lati ri pe wọn ko pa pasitọ yi bi wọn ṣe pa alaga ijọ Church of the Brethren in Nigeria(EYN) ati alaga ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni ijọba ibilẹ Michika ni Adamawa, Rev. Lawan Andimi.

''A ri ijinigbe yi gẹgẹ bi idanwo nla fawọn ọga ileeṣẹ ọmọogun Naijiria paapa ọgagun ọmọ ogun Naijria tuntun Yahaya Farouk ati ọga ọlọpaa Naijiria Usman Alkali Baba nitori gbogbo aye lo n wo bi wọn yoo ti ṣe ṣe iṣẹ wọn.''

CAN fi kun pe ti ijọba Naijiria ba le ṣa gbogbo apa lati mu olori IPOB Nnamdi Kanu,ko yẹ ko le fun wọn lati mu awọn obilẹjẹ to n da omi alaafia Naijiria ru.

Wọn wa parọwa si ijọba ki wọn dide lati koju gbogbo ipenija aabo paapa tawọn ajinigbe ati janduku to fi mọ awọn ọdaran darandaran.