'Ìdí tí mo fi máa ń sunkún nínú fíìmù nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ eré nìyí'

Oríṣun àwòrán, Lateef Adedimeji/Facebook
Òdú ni gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Lateef Adedimeji kìí ṣe àìmọ̀ fólóko.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, nígbà tí ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ eré fíìmù ṣíṣe, ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ Lateef Adedimeji mọ̀ ni bí ó ṣe máa ń wa omi ẹkún mu bíi gaàrí nínú eré.
Lateef Adedimeji, nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn The Punch ní òun mọ̀ọ́mọ̀ kó ipá ẹlẹ́kún nígbà tí òun bẹ̀rẹ̀ eré láti lè ní ohun ìdánimọ̀ kan pàtó tí àwọn èèyàn yóò mọ òun mọ́.
Ó ní òun ṣe èyí láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn le dá òun yàtọ̀ láàárín àwọn akẹgbẹ́ òun.
Ó sọ pé nígbà tí òun ri pé àwọn èèyàn ti mọ òun, tí òun ti ní orúkọ àti pé ipa náà ti fẹ́ máa sú àwọn èèyàn ní òun tún gba ọ̀nà ara mìíràn yọ nípa ṣíṣe bíi ẹ̀yà Igbo nínú eré.

Oríṣun àwòrán, Lateef Adedimeji/Facebook
"Nígbà tí mò ń wá orúkọ, mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ipa ẹlẹ́kún, mo máa ń sunkún bíi arìndìn. Tí wọ́n bá ní kí n sun ẹkún fún ìṣẹ́jú kan, mà á lo ìṣẹ́jú méjì.
"Ohun tí mo mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ni. Ìgbà kan tó jẹ́ pé tí àwọn èèyàn kò bá rántí orúkọ mi, wọ́n máa sọ pé ọkùnrin tó máa ń sunkún gan yẹn nínú eré.
"Nígbà tí mo sì ri pé ìyẹn ti fẹ́ máa pọ̀jù, mo yí sí ọmọ Igbo tó ń fi agídí sọ èdè Yorùbá. Gbogbo ẹ láti dá yàtọ̀ ni."
Gbajúmọ̀ òṣèré náà ní lẹ́yìn ìgbà náà ni òun ṣe eré fíìmù Ayinla, èyí tó mú kí àwọn èèyàn tún rí àrà mìíràn nípa òun pàápàá lórí bí òun ṣe kọrin nínú eré náà.
"Lẹ́yìn náà ni a ṣe fíìmù Jagunjagun táwọn èèyàn tún rí ipa mìíràn tó yàtọ̀ sí àwọn èyí tí mo máa ń ṣe tẹ́lẹ̀."
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí fíìmù rẹ̀, Lisabi ṣe wà lára àwọn nǹkan táwọn èèyàn ń wá lórí ayélujára lọ́dún 2024, ó ní inú òun dùn púpọ̀ pé àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òun.
Lateef Adedimeji sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn òṣèré ṣe ń ṣe fíìmù tó níṣe pẹ̀lú àwọn èèkàn ilẹ̀ wa tó ti lọ, ó ní ohun tó bá le mú àwọn èèyàn ilẹ̀ wa láti máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèkàn orílẹ̀ èdè mìíràn kò sí ohun tó burú nípa kíkọ eré nípa àwọn èèkàn ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó ti lọ.
"A ní àwọn èèyàn tó jà fún òmìnira ilẹ̀ wa, kí ló dé tí a kò lè máa sọ ìtàn ti wọn náà àti láti mọ rírì wọn."















