MURIC ní Shariah ti bẹ̀rẹ̀ n'Ibadan, Eko àti Abeokuta, àjọ CAN, Afenifere àtàwọn oníṣẹ̀ṣe fèsì sọ́rọ̀ Sultan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awuyewuye lori ọrọ ti Sultan ilu Sokoto, Alhaji Muhammad Sa'ad Abubakar, sọ pe ifilọlẹ ile ẹjọ Shari'ah gbọdọ waye nipinlẹ Ekiti ati Oyo tun ti bọna miran yọ.
Ajọ ọmọlẹyìn kristi, CAN, ajọ MURIC to n ri si ẹtọ awọn musulumi, ẹgbẹ Afenifere at'awọn oniṣẹṣe ti fesi sọrọ Sultan lori idasilẹ igbimọ ati ile ẹjọ Shari'ah l'Ekiti ati l'Oyo.
Nigba ti o ba BBC Yoruba sọrọ, alaga ajọ CAN nipinlẹ Oyo, Ẹniọwọ Joshua Akinyemiju sọ pe igbimọ ati ile ẹjọ Shari'ah ko le bẹrẹ nipinlẹ Oyo ati nilẹ Yoruba lapapọ tori kii ṣe ofin ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ṣe agbejalẹ rẹ.
Ẹniọwọ Akinyemiju sọ pe nnkan to yẹ k'awọn to n pe fun ofin Shari'ah ṣe ni pe ki wọn lọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ki ile si fọwọ si.
O ni lẹyin naa nile yoo gbe ofin ọhun lọ siwaju gomina ẹni ti yoo buwọlu u ko to le dofin.
Awọn ọmọlẹyìn Kristi o bẹru ofin Shari'ah amọ... - CAN
Alaga ajọ CAN nipinlẹ Oyo sọ pe kii ṣe pe awọn ọmọlẹyin Kristi n bẹru ofin tabi ile ẹjọ Shari'ah, o ni awọn to n pe fun ile ẹjọ Shari'ah lo ni lati ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe.
"Awọn to n pe fun idasilẹ Shari'ah ko tii ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe.
Ile aṣofin ipinlẹ Oyo ko mọ ohunkohun nipa ofin Shari'ah ti wọn n pe fun, bawo lo ṣe fẹ kẹsẹjari?
Ati pe bawo ni ẹ ṣe fẹ se agbekalẹ ofin ti yoo wa fawọn eeyan lasan?
Nkankan ku diẹ kaato pẹlu ọrọ naa."
Alaga ajọ CAN ni Gomina Seyi Makinde ti fi erongba rẹ han lori ọrọ Shari'ah naa pe iwe ofin orilẹede Naijiria nikan loun mọ nipinle Oyo.
O ni ko si bi ile ẹjọ Shari'ah ṣe maa dajọ ti gomina ko ṣe ni pada ṣe ibuwọlu si idajọ ti ile ẹjọ Shari'ah ba da.
Alaga CAN nipinlẹ Oyo sọ pe gbogbo eeyan lo fẹ ki awọn to n beere fun Shari'ah ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe ti wọn ba fẹ ki ofin naa fẹsẹ mulẹ.
A ti n lo igbimọ Shari'ah n'Ibadan, Eko ati Abeokuta - MURIC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oludasilẹ ajọ MURIC to n ri ẹtọ awọn musulumi, Ọjọgbọn Ishaq Akintola, sọ fun BBC Yoruba wi pe igbimọ Shari'ah l'awọn n beere fun kii ṣe ile ẹjọ Shari'ah nilẹ Yoruba.
Ọjọgbọn Akintola sọ pe ile ẹjọ Shari'ah maa nilo agbekalẹ ofin ki o to le ṣee ṣe.
O ni igbimọ Shari'ah ti bẹrẹ iṣẹ niluu Ibadan lati ọdun 2002.
Oludasilẹ MURIC ni o jẹ iyalẹnu foun pe Makinde n sọ fun gbogbo agbaye wi pe ko si Shari'ah nipinlẹ Oyo nigba ti o ti bẹrẹ lati ọdun 2002.
"Oja Oba ni igbimọ Shari'ah ti n jokoo niluu Ibadan ti wọn ti n gbẹjọ awọn musulumi.
Igbimọ Shari'ah ti n jokoo ni mosalaasi nla niluu Abeokuta, bakan naa ni igbimọ yii ti n jokoo lagbegbe Victoria Island nipinlẹ Eko.
Ko kan awọn ọmọlẹyin Kristi rara.
Igbimọ Shari'ah yii ko le dajọ fun ẹnikan kan.
Awa naa mọ pe a o le ni ile ẹjọ Shari'ah nilẹ Yoruba lai si ofin ti ile igbimọ aṣofin ati gomina ti buwolu.
Sugbọn awọn gomina ilẹ Yoruba n sọrọ Shari'ah lati fi tako awọn musulumi.
Awọn gomina ilẹ Yoruba n sọrọ tako Shari'ah nitori ọmọlẹyìn Kristi ni wọn.
Awọn gomina n tako ẹgbẹlẹgbẹ awọn musulumi to wa nilẹ Yoruba lai nidi."
Ọjọgbọn Akintola ni awọn gomina fẹ da ogun silẹ nilẹ Yoruba ni pẹlu ọwọ ti wọn fi n mu ọrọ Shari'ah.
Ko si nnkan to kan Sultan lori ọrọ ilẹ Yoruba - Afenifere Renewal Group
Eekan ẹgbẹ Afenifere Renewal Group, Họnọrebu Wale Oshun, ti sọ pe ko si ohun to kan Sultan ilu Sokoto lori ọrọ ilẹ Yoruba.
Họnọrebu Oshun sọ pe lati ọjọ to ti pẹ ni musulumi ati kristiẹni to fi mọ awọn ẹlẹṣin abalaye ti jọ n gbe pọ lai si ija.
O ni awọn to n beere fun Shari'ah nilẹ Yoruba fẹ fi pa owo ni.
Họnọrebu Oshun ni "awọn ọmọ Yoruba mọ ohun ti wọn fẹ funra wọn.
Kii ṣe ẹnìkan lati ita lo maa sọ fun wọn ohun to yẹ ki wọn ṣe.
Orilẹede olominira ni Naijiria pẹlu iwe ofin, agbara Sultan ko ju Sokoto lọ.
Sultan ko lagbara lati dasi nnkan to n ṣẹlẹ yaka ni l'Ekiti tabi l"Oyo tabi nilẹ Yoruba kankan.
"Awa oniṣẹṣe o faramọ Shari'ah nilẹ Yoruba"

Oríṣun àwòrán, Sultan Sokoto
Aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe ẹka ti ipinlẹ Osun, Oluomo Ọmọwe Oluseyi Atanda, naa ti sọ pe awọn oniṣẹṣe o faramọ mọ idasilẹ ile ẹjọ Shari'ah nilẹ Yoruba.
Ọmọwe Atanda ni Sultan ilu Sokoto tabuku ilẹ Yoruba lori ọrọ to sọ pe ilẹ Yoruba gbọdọ faye gba ofin Shari'ah.
O ṣalaye pe ilẹ Yoruba ko nilo ile ẹjọ Shari'ah mọ tori ile ẹjọ ti iwe ofin Naijiria fọwọ si wa káàkiri awọn ipinlẹ Yoruba.
Ọmọwe Atanda ni awọn orilẹede tabi ipinlẹ to n lo ofin Shari'ah ni wọn le maa lo ile ẹjọ Shari'ah kii ṣe ilẹ Yoruba.
Aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe fikun ọrọ rẹ pe bi awọn ọmọ Yoruba ṣe tako ọrọ Shari'ah ọhun fi han pe ko le f'ẹsẹ mulẹ.
O ni ilẹ Yoruba kii se ilẹ musulumi bi tilẹ jẹ pe awọn musulumi wa lara awọn Yoruba.
Ọmọwe Atanda wa rọ awọn ọba alaye nilẹ Yoruba lati ṣọ fun Sultan pe Shari'ah ko le f'ẹsẹ mulẹ nilẹ Yoruba.















