Ètò ìsìnkú Moses Korede, tí ọ̀pọ̀ mọ sì Bàbá Gbenro, tí bẹrẹ nilu Ogbomoso

Oku Moses Korede Are
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Alagba Moses Korede Are, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Baba Gbenro, ninu sinima ere itage tẹgbẹ Mount Zion ti jade laye.

Ile ijọsin Alagba Moses Korede, House to House to wa ni agbegbe papa Adeyemo nilu Ogbomosho nipinlẹ Oyo, ni eto naa ti waye.

Ṣaaju ni awọn eto asalẹ awọn oṣere sinima ti waye ni ile ijọsin True Worshipers to wa ní agbegbe Oke Anu nilu ogbomoso lana.

 Moses Korede Are

Awọn agba oṣere sinima agbelewo ẹlẹṣin Kristẹni pọ lara awọn to pejọ lati bu ẹyẹ ikẹyin fun oloogbe ọhun.

Lara wọn ni Joseph Adepoju, Adedeji Adekusibe, Segun okeowo, Michael Agboola, Kayode Babalola ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Akọroyin BBC wa nibi eto isinku naa, a maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa fun yin laipẹ.

Awọn ẹbi to peju sibi isinku naa