Mike Bamiloye àtàwọn àgbà òṣèré míì sọ̀rọ̀ lórí ìbáṣepọ̀ tí wọ́n ní kẹ́yìn pẹ̀lú ‘Baba Gbenro’

Aworan oloogbe Korede Are

Oríṣun àwòrán, Seun Ajetumobi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

"Ẹ dákẹ́ àdúrà, ẹ dúró tì mí, mo fẹ́ẹ́ sinmi"

Ọpọ awọn akẹgbẹ gbajugbaja osere Kristẹni, Korede Moses Are, ẹni ti ọpọ mọ si Baba Gbenro ni awọn ti n se idaro lori iku rẹ, eyi to de ba ọpọ wọn lojiji.

Adewuyi Adegbite loju opo ayelujara Facebook nigba to se idaro oloogbe sọ awọn ọrọ to sọ gbẹyin ko to di pe o jaye laye.

O ni isẹju marun un lẹyin to sọ ọrọ naa lo jẹ ipe Ọlọrun.

“Brọda Niyi, Ẹ jọwọ ẹ dakẹ adura, ẹ duro ti mi, mo fẹ sin mi”

Adegbite ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii eeyan nla, to kopa ipa nla, to si jere ọkan nigba to wa laye.

aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook

Mike Bamiloye naa pẹlu awọn eeyan to ti sọrọ nipa iku oloogbe Korede Moses Are, ẹni to ni o lọ sin mi ni lẹyin ọpọlọpọ iṣẹ .

“Dokita Korede ti lọ si ile lọ sii mi. Ti eeyan se iṣẹ tan, yoo lọ si ile lọ sin mi.”

Bamiloye ni oloogbe si wa pẹlu awọn fun sinima Abattoir ti awọn ko si mọ pe nnkan se rara,

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Nigba ti wọn gbe lọ si ile iwosan, a n sọrọ lori foonu to si ni “Ẹ ba mi ki ọrẹ mi fun mi Pmease Daddy, ara mi yoo ya, ẹ ma jẹ ki eyi da yin duro lati pe mi fun sinima .

“Ko mọ pe o ti se sinima ikẹyin rẹ.”

Adeleke Precoius Oluwadamilola ni oun pada oloogbe naa ni ile iwosan ti oun si n pariwo Baba Gbenro.

“Inu rẹ dun lati ki mi ti n ko si mọ pe Baba n koju ọpọ nnkan.”

Shola Mike Agboola, ni oun ji ni owurọ oni pẹlu ero lati gba adura fun oloogbe, ti oun si ṣe bẹ.

“Ara n sọ fun mi pe ki n pe ẹ, ki n si gbọ ohun rẹ. Mo pe ṣugbọn o ko gbe ipe rẹ. Mo kọ atẹjisẹ ransẹ si ẹ lori opo Whatsapp lai mọ pe nnkan ti sẹlẹ.

“N ko mọ pe atẹjisẹ mi wọle lẹyin wakati kan to dagbere faye.

“O ti sọ ida rẹ silẹ, ti o si pada si ọdọ Ọba to da wa, to nifẹ pupọ.”

Absty Daniels ni ọpọ awọn eeyan bi ti rẹ ni ko mọ oloogbe saaju ko to kopa ninu sinima Abbattoir sugbọn o fọwọ tọ ọkan awọn eeyan pẹlu sinima naa.

“A dupẹ lọwọ fun ẹbun oloogbe, ki o sun ninu agbara.”

Taiwo Olu Osuolale ni Ọlọrun ti jẹ ẹbun eeyan rere, to si kan sara si ipa ti oloogbe ko lasiko to wa laye.

Gbajúgbajà òṣèré tíátà Krìstẹ́nì, Korede Are 'Baba Gbenro' jáde láyé

Aworan Kayode Are 'Baba Gbenjo'

Oríṣun àwòrán, IG/seunadejumobi/

Gbajugbaja osere sinima ti Kristẹni, Moses Korede Are, ẹni ti ọpọ mọ si Baba Gbenro ti Abattoir ti jade laye.

Akẹgbẹ rẹ, Oluwaseun Adejumobi lo kede iroyin naa loju opo ayelujara Instagram lọjọbọ, ọjọ kẹrinla oṣe kọkanla ọdun 2024.

O ni ọọrun ti mu akọni lọ, “Ọga patapata ti lọ si mi.”

Orukọ Baba Gbenro ni ọpọ awọn ololufẹ rẹ ma n pe, to si jẹ ọkan lara awọn oṣere to kopa ninu sinima Kristẹni Mount Zion. to jẹ ọkan to sọ di ilumọka ni ẹka sinima Kristẹni.

O jẹ oludasilẹ ati aarẹ fun ilẹ ẹkọ kan to n kọ nipa ere ori itage niluu Ogbomoso

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ta ni Kayode Are?

Ọjọ Kejila oṣu kẹjọ ọdun 1959 ni wọn bi Kayode Moses Are.

O dagba ni ilu kan niluu Kano, to si lọ si ile ẹkọ nibẹ.

Bakan naa lo ka iwe ni ipinlẹ Plateau ko to pada si guusu orilẹede Naijiia lati tẹsiwaju ẹkọ rẹ.

O ti sisẹ pọ pẹlu awọn eekan ninu ere sinima ẹmi, to si farahan ninu awọn sinima to ni se pẹlu igbagbọ ti awọn Kristẹni.

Are le sọ ọpọ ede bi Gẹẹsi, Yoruba ati Hausa daada.

Lẹyin ọpọ ọdun to fi ṣe aisan kikindirin, Kayode Are jade laye ni ọdun marundinlaadọrin.