Wo àwọn orílẹ̀èdè márùn ún tí yóò fún ọ lówó tí o bá bí ọmọ tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iye owo ti eeyan yoo na ti oun tabi mọlẹbi rẹ ba n bi ọmọ tuntun ko kere pupọ, eredi ree ti ẹru fi maa n ba awọn mii nilẹ adulawọ ti ọjọ ikunlẹ ba sunmọ etile.
Wayi o, awọn orilẹede kan ti bẹrẹ si n ṣe iranlọwọ fun awọn eeyan wọn lasiko yii nipa fifun awọn obi tuntun lowo.
Oniruru ọna ni iranlọwọn naa n gba wa, fun awọn mii ṣe ni wọn maa n fun wọn lowo na ni kiṣi, nigba mii ẹwẹ, ṣe ni wọn maa n fun wọn lowo ọhun diẹdiẹ.
Iwọnyi lawọn orilẹede to maa n fun awọn eeyan wọn lowo ti wọn ba bi ọmọ tan.
Australia
Awọn obi ni Australia le gba owo to to $5,000 fun akọbi ọmọ wọn, ijọba si le fun wọn to $3,000 fun awọn ọmọ to ba tẹle akọbi naa ṣugbọn diẹdiẹ ni wọn yoo maa san owo naa.
China
Lẹyin ọpọ ọdun ti China sọ pe idile kan ko gbọdọ bi ju ọmọ kan lọ, o ti bẹrẹ si n gba awọn eeyan niyanju lati maa bimọ bayii.
Lawọn ilu bii Lianjiang, $510 ni wọn maa n fun awọn obi to ba bi ọmọ lẹyin oṣu Kẹsan an ọdun 2021, lẹyin ọdun meji abọ, awọn obi naa le gba owo ti iye rẹ to $15,000.
FInland
Ijọba Finland maa n fun obi ni awọn ẹru ọmọ ati owo ti iye rẹ to €170 atawọn nnkan mii.
Japan
Lawon agbegbe bii Nakanoshima, awọn obi le gba owo ti iye rẹ to ¥100,000 fun akọbi ọmọ wọn, wọn si le gba owo ti iye rẹ to ¥1,000,000 fun ọmọ kẹrin.
Estonia
Nilẹ Estonia, ijọba maa n fun awọn obi ni owo ti iye rẹ to €320 ti wọn ba bi ọmọ.
Bi ọmọ eeyan ba ṣe pọ si ni yoo ṣe gba owo si, fun apẹrẹ, ẹni to ba bi ibẹta le gba owo to to le ni €1,000 fun ẹnikọọkan wọn.















