'Mà á gba owó kí n tó dìbò tí wọ́n bá fi lọ̀ mí'

Eeyan kan n dibo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ètò ìṣèjọba àwaarawa jẹ́ èyí tó pèsè àǹfàní fáwọn èèyàn láti dìbò fún ẹni tí wọ́n bá fẹ́.

Ṣáájú ìbò ni olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe ìpolongo, tí wọn yóò máa sọ nǹkan tí wọ́n yóò gbéṣe nígbà tí wọ́n bá dé ipò náà fún ará ìlú.

Àsìkò ìpolongo ìbò máa ń jẹ́ èyí tó fún àwọn olùdíje ní àǹfàní láti fi pé ọkàn àwọn ará ìlú àtàwọn olùdìbò sọ́dọ̀ wọn, kí wọ́n le dìbò fún wọn lọ́jọ́ ìbò.

Ẹ̀wẹ̀, ní Nàìjíríà ó jọ wí pé ṣíṣe ìpolongo àti irú èèyàn tí olùdíje jẹ́ kò tó mọ́ lati fi pé àwọn ọkàn àwọn èèyàn sọ́dọ̀ olùdíje ní èyí tó bí títà àti ríra ìbò.

Ìbò rírà túmọ̀ sí fífún olùdìbò ní ẹ̀bùn yálà owó, oúnjẹ, aṣọ tàbí nǹkan míì ṣáájú, lásìkò àti lẹ́yìn ìdìbò nítorí kí olùdìbò náà bá a lè dìbò fún olùdíje tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú kan.

Ọ̀kan lára àwọn ìpèníjà tó ń ṣe àkóbá fún ṣíṣe ètò ìdìbò tí yóò lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀ ni títà àti rír ìbò jẹ́.

Obinrin kan n dibo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Èyí gan ló bí ọ̀rọ̀ ti àwọn máa fi ń dáṣà lásìkò ìbò pé dìbò kí o sebẹ̀.

Abala Kọkànlélọ́gọ́fà ìwé òfin ètò ìdìbò Nàìjíríà tọdún 2022 sọ pé “olùdìbò tó bá gba owó, ẹ̀bùn, ipò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ fún ara rẹ̀ tàbí ẹlòmíràn pẹ̀lú àdéhùn pé òun máa dìbò tàbí láti má dìbò ti ṣẹ̀ sí òfin gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lásìkò ìbò.”

Àjọ tó ń rí sí gbígbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà ìyẹn Economic and Financial Crime Commission, EFCC, láti dènà ìwà títà àti ríra ìbò ti ń da àwọn òṣìṣẹ́ wọn sí ibùdó ìdìbò láti mójútó ìwà yìí.

Níbi ètò ìdìbò gbogbogbò Nàìjíríà ọdún 2023, EFCC kéde pé àwọn mú àwọn afurasí kan tó ń gbìyànjú láti ra ìbò àmọ́ a kò le sọ pé báyìí ni igbẹ́jọ́ wọn ṣe lọ.

Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kọkànlá ni ètò ìdìbò sípò gómìnà Ondo fún sáà ọdún mẹ́rin mìíràn yóò tún wáyé.

Ṣé ìwà dìbò kó sebẹ̀ yóò tún wáyé níbi ètò ìdìbò Ondo?

Àwọn òṣìṣẹ́ INEC tó ń ka ìbò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ìlú Akure, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo, ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú ló ń gbáradì fún ètò ìdìbò náà, táwọn olùdìbò sì ní ìrètí tó ga nínú àwọn olùdíje pàápàá bí nǹkan ṣe rí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lásìkò yìí.

Ebí, ìṣẹ́ àti òṣì wà lára ìpèníjà tó ń bá àwọn ọmọ Nàìjíríà lásìkò yìí.

Ọ̀pọ̀ àwọn olùdìbò tí wọ́n ń gbèrò láti kópa nínú ìdìbò náà sọ̀rọ̀ nípa ìgbáradì wọn láti kópa níbi ètò ìdìbò ọ̀hún.

Adebisi Busayo Damilola tó n gbèrò láti dìbò níbi ètò ìdìbò náà sọ fún BBC pé ó wu òun láti kópa níbi ètò ìdìbò yìí àti pé òun ti ní olùdíje kan lọ́kàn tí òun fẹ́ dìbò fún.

Ó ṣàláyé pé lóòótọ́ ni òun le gba owó lọ́wọ́ olùdíje àmọ́ yóò jẹ́ olùdíje tí òun ní lọ́kàn láti dìbò fún.

“Tó bá jẹ́ èèyàn tí mo ní lọ́kànn láti dìbò fún tẹ́lẹ̀ ló fẹ́ fún mi lówó, lóòótọ́ ni mà á gba owó náà nítorí àléún ló jẹ́ fún mi.

“Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹgbẹ́ mìíràn ló fẹ́ gbìyànjú láti fún mi lówó, mi ò ní gba owó náà nítorí owó ọ̀hún kò lè yí ọkàn mi padà.

Adebisi ní owó tí wọ́n fẹ́ fún òun náà kọ́ ló máa yí àwọn nǹkan tí òun rí nínú ẹni tí òun fẹ́ dìbò fún padà nítorí owó náà kò lè gbé òun fún ọdún mẹ́rin tí ẹni náà yóò lò lórí ipò.

Olasunkanmi Adekunle gbàgbọ́ ní tirẹ̀ pé gbígba owó lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú lásìkò ètò ìdìbò láti dìbò ló mú Nàìjíríà wà ní ipò tó wà báyìí.

Adekunle ní gbogbo ìwà kò tọ́ táwọn olóṣèlú ń wù ní Nàìjíríà kò ṣẹ̀yìn bí àwọn èèyàn máa ń gba owó lọ́wọ́ wọn lásìkò ìbò.

Adekunle ní kò sí iye tí olóṣèlú lè fún òun tó lè mú òun ta ẹ̀rí ọkàn òun nítorí owó náà dàbí pé wọ́n fẹ́ fi ra ọkàn òun ni.

Fún Ayeni Abimbola, ó ní òun máa gba owó bí àwọn olóṣèlú bá fẹ́ fún òun lówó láti dìbò nítorí tí òun kò bá gbà á ó le fa kí irú ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀ fi ojú sí òun lára.

Ó ní gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá fún òun lówó ni òun máa gbà àti pé yóò túnbọ̀ mú òun ní ọkàn le láti má dìbò fún ẹgbẹ́ tí òun kò fẹ́ dìbò fún tẹ́lẹ̀.

Ayeni ní ko sí iye tí ẹnikẹ́ni lé fún òun tó lè mú òun yí ìpinnu òun padà nípa ẹni tí òun ní lọ́kàn láti dìbò fún tẹ́lẹ̀.

“A ò lè máa ṣe nǹkan bákan náà kí a retí èsì tó yàtọ̀.”

Kí ni ipa rírà àti títa ìbò ní Nàìjíríà?

Ẹni tó ń dìbò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onímọ̀ nípa ètò òṣèlú àti ìṣèjọba ní Nàìjíríà, Dókítà Gbade Ojo bí ó ṣe sọ pé àwọn olóṣèlú Nàìjíríà ń mọ̀-ọ́n-mọ̀ sọ àwọn èèyàn Nàìjíríà sínú ìṣẹ́ àti òṣì kí wọ́n ba à lè fi owó péréte tàn wọ́n lásìkò ìbò.

Dókítà Ojo ṣàlàyé pé ìṣòro ńlá ni ìpèníjà yìí nílẹ̀ Áfíríkà lápapọ̀ nítorí owó tí àwọn èèyàn bá ti gbà lásìkò ìbò kìí jẹ́ kí ẹnu wọn le tó ọ̀rọ̀ nígbà tí àwọn olóṣèlú náà kò bá ṣe ìfẹ́ ará ìlú nígbà tí wọ́n bá dé ipò ìjọba tán.

Ó fi kun pé èyí máa ń pọkún ìwà àjẹbánu tó gbilẹ̀ nílẹ̀ Áfíríkà nítorí ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú yìí ló máa fẹ́ kó gbogbo owó tí wọ́n ná lásìkò ìbò náà padà ní ìlọ́po púpọ̀.

Henry Olonimoyo ni tirẹ̀ gbàgbọ́ pé ó ṣòro kí “ìwà dìbò kí o sebẹ̀” le kásẹ̀ nílẹ̀ ní Nàìjíríà lásìkò yìí nítorí “ó ń pé àwọn olóṣèlú pé tí wan bá ti wọlé sípò ìjọba láti má ṣe ohu tó yẹ kí wọ́n ṣe, kí wọ́n jẹ́ kí ilẹ̀ gbẹ dada, kí ebi pa ará ìlú.”

“Òṣì ti di ohun àmúṣagbára fáwọn olóṣèlú tí wọ́n fi ń dìde ìjà sáwọn ará ìlú ló fi jẹ́ pé káràkátà ìbò kò lè tètè tán lásìkò yìí.”

“Ẹni tí ebi ń pa, ṣé tó bá rí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ṣe kò ní gbà á ni? Ṣé ẹni tí kò rí owó ra epo sí ọkọ̀ rẹ̀ láti ìgbà tí epo ti wọ́n ni kò ni gba ẹgbẹ̀rún márùn-ún?

Olonimoyo ní láti ìgbà tí àwọn èèyàn ti ń gba owó lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú ni agbára wọn láti yan àwọn adarí tó pójú òṣùwọ̀n ti dínkù.

Kí ni ọ̀nà àbáyọ sí títà àti ríra ìbò?

Dókítà Ojo ṣàlàyé ètó ẹ̀kọ́ Nàìjíríà gbọdọ̀ múná dóko tí òpin yóò bá débá ìwà títà àti ríra ìbò ní Nàìjíríà.

Ó wòye pé òfin Nàìjíríà kò lágbára tó àti pé àwọn tó ń ṣe òfin yìí náà ni wọ́n máa ń ru ní ọ̀pọ̀ ìgbà tó sì jẹ́ kìí sí ìjìyà fún àwọn arúfin.

Onímọ̀ náà ní ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti mú sẹ́yìn fún ẹ̀sùn rírà tàbí títa ìbò ni kìí sí ìjìyà kankan fún wọn, tí èyí yóò sì túnbọ̀ jẹ́ kí ìwà náà máa tẹ̀síwájú.

Bákan náà ló ní àjọ tó ń rí sí líla àwọn ará ìlú lọ́yẹ̀ ìyẹn National Orientation Agency, NOA nílò láti jí gìrì sí ojúṣe wọn.

“Kí àsìkò ìbò tó dé ló yẹ́ kí àjọ NOA ti máa kéde, kí wọ́n fún àwọn èèyàn ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó wà nínú ewu tó wà nínú títà àti ríra ìbò.”

Olonimoyo ní ó dìgbà tí Nàìjíríà bá ní àwọn adarí tó bá ṣetán láti gbógunti ìwà títà àti rírà ìbò ni ó tó le kásẹ̀ nílẹ̀ ní Nàìjíríà.

Ó ní òfin tó ní ìbò tí èèyàn bá dì kò gbọdọ̀ jẹ́ nǹkan tí ẹlòmíràn yóò rí gbọdọ̀ ri ìfẹsẹ̀múlẹ̀ dáadáa, pé èyí yóò dènà ìbò rírà.

“Tí àwọn èèyàn bá tẹ̀ka tán, wọ́n ní ọ̀nà tí wọ́n fi máa ń han àwọn tí wọ́n fẹ́ gba owó lọ́wọ́ wọn, kí wọ́n lè mọ̀ ẹni tí wan dìbò fún.

“Tí gbogbo èyí kò bá tán, ìbò rírà àti títà kò lè kásẹ̀ nílẹ̀ ní Nàìjíríà.”