Ọ̀wọ́n oúnjẹ́ gbọ̀nà míràn yọ, Gààrí àti Èlùbọ́ Ànàmọ́ rọ́pò ti Ẹ̀gẹ́ lówó pọ́ọ́kú

Àkọlé fídíò, Inflation: Mo ti já sí Gààrí tí wọn ń fi Ànàmọ́ ṣe, kò sí ìyàtọ̀ sí èyí tí wọn fi Ẹ̀gẹ́ ṣe
Ọ̀wọ́n oúnjẹ́ gbọ̀nà míràn yọ, Gààrí àti Èlùbọ́ Ànàmọ́ rọ́pò ti Ẹ̀gẹ́ lówó pọ́ọ́kú

Oniruuru ọgbọn atinuda ati awari ijinlẹ nipa ounjẹ ni ọpọ eeyan gun le bayi lati wa ọna abayọ si owo ounjẹ to wọn bii oju.

Bẹẹ ba gbagbe, tori ọwọn ounjẹ, awọn eeyan kan n fi eepo ẹgẹ se Elubọ, ti wọn n ro ni amala, lati fi se ounjẹ.

Amọ igbesẹ naa yiwọ fun idile kan nilu Ogbomoso, to si mu ẹmi eeyan kan lọ.

Nibayii, iwadi BBC Yoruba fihan pe awọn araalu tun ti n da ọgbọn miran lati wa ọna abayọ si ọwọn gogo Elubọ ati Gaari, eyi to jẹ ounjẹ fun ọpọ idile nilẹ Yoruba.

A sawari rẹ pe Anamọ, ti a tun mọ si Ọdunkun ni awọn eeyan kan n yipada di Gaari ati Elubọ bayii, ti wọn si fi n rọpo Elubọ ati Gaari Ẹgẹ.

Ki wa ni iyatọ to wa laarin Elubọ ati Gaari Anamọ si ti Ẹgẹ, bawo ni wọn ti n se, bawo si lo se ri lẹnu?

BBC Yoruba ba Agbẹ ati onisowo kan to n gbin Anamọ, to si n sọ di Elubọ ati Gaari sọrọ, ti a si tun kan si onimọ nipa ounjẹ lati mọ ero rẹ lori isẹlẹ yii.

Anamọ

Tori ele owo ounjẹ, ti Gaari si di olookọ ọba, ni emi ti ja si Gaari ti wọn n fi Anamọ se - Olawale Boluwatife

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, onisowo kan to tun jẹ abiyamọ, Olawale Boluwatifẹ, sọ bi Elubọ ati Gaari Anamọ se jẹ itẹwọgba ninu ile rẹ.

"Lati igba ti gbogbo nnkan ti wọn ni Naijiria, ti Gaari ti wọn n fi ẹgẹ se ti di olookọ ọba, ni emi ti ja si Gaari ti wọn n fi Anamọ se.

Ati emi ati ẹbi mi, Gaari Anamọ ni a n jẹ.

A maa n fi Anamọ se Elubo ati Gaari, Gaari yẹn dara ni ara, awọn ọmọ mi gan fẹran lati maa mu gaari Anamọ, wọn ko fẹ gaari ẹgẹ mọ."

 Olawale Boluwatifẹ,

Ninu ọgbin Anamọ, a mu Elubọ ati Gaari jade, ọgbin rẹ ko si gunpa rara - Taiwo Oluwagbemiga

BBc Yoruba kan si agbẹ kan, Taiwo Oluwagbemiga, ẹni to n gbin Anamọ lọpọ yanturu, to si tun n lo ohun ọgbin rẹ lati fi se Gaari ati Elubọ.

O salaye fun BBC Yoruba nipa bi owo Anamọ ko se gunpa lati gbin si oko ati awọn anfaani to wa ninu rẹ.

"Bi orilẹede wa se ri lonii, ọgbin anamọ rọrun, o maa n jẹ ki ounjẹ pọ ninu ile.

Ninu ọgbin Anamọ, a mu Elubọ jade, a mu Gaari jade, gbingbin Anamọ ko gunpa rara.

Kii se owo to pọ, eeyan le gbin anamọ ni ẹẹmẹta, eyi ti yoo mu ki ounjẹ pọ ninu ile.

Awọn eeyan maa n gbe Anamọ wa, ti a maa n sọ di Gaari, Elubọ fun irọrun ara wa."

Taiwo Oluwagbenga – Agbẹ

Bi Gaari ẹgẹ se ri, bẹẹ naa ni Gaari Anamọ se ri, Anamọ jẹ ounjẹ to dara pupọ, ko si ijamba to n se fun ara - Onimọ nipa ounjẹ

Iwadii BBC yoruba tun tẹsiwaju lori ọrọ sisọ Anamọ di iyẹfun yii, ti a si fẹ mọ ewu to seese ko ti idi igbesẹ yii jade.

Idi ree ti a fi kan si onimọ nipa ounjẹ asaraloore kan, Bolanle Babayomi, ẹni to salaye nipa lilo Anamọ lati fi se iyẹfun.

Onimọ naa salaye fun BBC Yoruba pe si ewu ninu sisọ Anamọ di iyẹfun Gaari abi Elubọ fun jijẹ, ẹnikẹni si lo le e jẹ.

"Nigba ti mo ri pe wọn n fi Ọkundun se Gaari, mo sa si lati wo pe bawo lo se maa ri.

Emi funra ara mi ti tọ wo, mo ri pe ko si iyatọ laarin gaari ti wọn fi Ọkundun se, si eyi ti wọn fi gbaguda se.

Bi Gaari ẹgẹ se ri, bẹẹ naa ni Gaari Anamọ se ri.

Anamọ jẹ ounjẹ to dara pupọ lati maa jẹ, ko si ijamba to n se fun ara.

Ọmọde ati agba le jẹ, pẹlu ọkunrin ati obinrin, o si jẹ ounjẹ ti ko wọn pupọ

Mo fẹ rọ awọn onimọ ijinlẹ lawọn ile ẹkọ fasiti wa, pe ki wọb ba wa se ayẹwo siwaju si lati mọ iyatọ to wa laarin Gaari ẹgẹ ati ti Anamọ."

Onimọ nipa ounjẹ, Bolanle Babayomi