"Mo fi èèpo ẹ̀gẹ́ ṣe èlùbọ́ torí ọ̀dá owó fún àwa méje láti jẹ ọkà, ẹnìkan kú, àwa mẹ́fà dèrò ilé ìwòsàn"
Ọba Oke, mase jẹ ka jẹ ounjẹ ajẹrọrun tabi ka jẹ ohun ti yoo ko ba ilera wa, ni adura ti ọpọ ẹda maa n gba.
Sugbọn fun idile Paul ati Victoria Oyewole nilu Ogbomoso, ounjẹ ti idile wọn jẹ se akoba fun ilera wọn, koda, o tun mu ẹmi ọmọ kan lọ pẹlu.
Isẹlẹ ibanujẹ naa lo waye ni agbegbe Temidire nilu Ogomoso lọjọ Kejidinlọgbọn osu Keji ọdun 2024 yii.
Eyi lo ta BBC Yoruba nidi kan lati mọ nipa ohun to mu ẹmi eeyan kan naa lọ ati ipo ti ẹmi naa wa.
Ninu iwadii BBC Yoruba nigba ta de silu naa, a gbọ pe eepo ẹgẹ ni mọlẹbi naa fi se elubọ, ti wọn si ro o ni amala, eyi to gbodi lọ lara wọn.
Koda, Baale ile naa, Paul Oyeewole ati aya rẹ, Victoria ba wa sọrọ lati salaye ohun ti wọn ri lọbẹ, ti wn se waru sọwọ.

“Ko si owo lọwọ emi ati ọkọ mi, ebi n pa awọn ọmọ ti ko jẹun alẹ ati aarọ, mo se fi eepo ẹgẹ se elubọ”
Ninu alaye rẹ fun BBC Yoruba, Victoria Oyewole sọ pe oun gbọ pe wọn maa n fi ẹgẹ se elubọ, ni oun ba ro pe eepo ẹgẹ naa yoo se elubọ, ni oun se fi ro ọka.
O ni Birikila ni ọkọ oun, ti oun si n ta ọja pẹẹ pẹẹ pẹẹ amọ ọkọ oun ko ri isẹ gba lasiko yii, ti atijẹun si di ọtọtọ ọran.
“Owo ti mo ba pa nidi ọja ni a fi n jẹun, mo si ti ta ọja naa tan, ko si owo kankan lọwọ mi mọ lati fi bọ awọn ọmọ.
Mo maa n lọ bawọn sa ẹgẹ nile ẹgẹ nigba ti ọja tan nigba mi, mo si mọ pe wọn maa n fi ẹgẹ se elubọ.
Ọkọ mi ti rinrinajo, ko si si nile, bẹẹ ni ko si ohun ti a jẹ. Awọn ọmọ mi mẹrin ati ọmọ ọmọ mi meji ko si jẹun alẹ sun.
Bẹẹ ni wọn tun jẹun aarọ ni ọjọ keji, ara wa ta mi, ni mo lọ sa eepo ẹgẹ, mo saa, mo gun, mo si lọ, mo si fi ro amala fun wọn lati jẹun.”
Victoria Oyewole ni oun ati ọmọ oun mẹrin pẹlu ọmọ-ọmọ oun meji, ti apapọ awọn jẹ eeyan meje, ni awọn jẹ amala ti wọn fi eepo ẹgẹ se naa.

“A jẹ amala tan, la ba di ero ile iwosan, n ko mọ pe o le di nnkan nla bayii, ounjẹ ni mo fẹ fun wọn”
Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Victoria salaye pe ko pẹ ti awọn jẹ ounjẹ naa tan, ni ohun gbogbo yi pada.
“Bi a se jẹun naa tan, ni a di ero ile iwosan nitori agọ ara wa to da isẹ silẹ.
Koda, n ko mọ nkankan mọ, mo ti lọ patapata.
N ko mọ pe wọn kii fi eepo ẹgẹ se amala, ọna lati wa ounjẹ fun awọn ọmọ ti ebi n pa ni mo se, n ko si mọ pe yoo di nnkan nla bayii.
Ọkan ninu ọmọ ọmọ mi meji to wa lọdọ mi se alaisi ninu awa meje ta jẹ amala naa, aanu Ọlọrun nikan ni awa yoku ri gba, ti a ko fi jade laye.”

Iku ọmọ ọmọ mi si n dun mi de ọkan – Paul Oyewole
Nigba ti oun naa n ba bbc Yoruba sọrọ, baale ile naa, Paul Oyewole ni ẹni kan lo sadede wa ke si oun nibi ti oun lọ, to si ni awọn ẹbi oun wa nile iwosan.
“Mo de ile mi, mo si ri ọpọ ero nibẹ. Mo beere pe ki lo de, wọnb si ni wọn ti gbe awọn ẹbi mi lọ sile iwosan tori amala ti wọn fi eepo ẹgẹ se, ti wọn jẹ.
Ọmọ ọmọ mi kan ku lati ipasẹ isẹlẹ naa, iku rẹ dun mi de ọkan, koda, ko tii kuro ni ara mi.”
Bakan naa ni Dokita Oyetunji Alabi to setọju idile naa ba BBC Yoruba sọrọ nipa ipo ti awn alaisan naa wa lasiko ti wọn gbe wọn wa sile iwosan.
“Mẹta ninu awọn eeyan meje naa ti daku, ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni wọn wa pẹlu.
Omi ti gbẹ lara wọn, eyi to jẹ ọmọ kekere laarin wọn si ti daku lọ rangbọndan.
Koda, mimi wọn ti kere pupọ, eepo ẹgẹ si la gbọ pe wọn fi se elubọ, ti wọn fi ro amala ti wọn jẹ.
A se itọju wọn, ara wọn si ya bi o tilẹ jẹ pe eyi to kere julọ ninu awn alaisan naa jade laye.”
Dokita Alabi wa rọ awọn eeyan lati dẹkun fifi eepo ẹgẹ se elubọ fun jijẹ nitori pe o le se aleebu fun ara wa.






