Oyún oṣù méje ààbọ̀, tí Dókítà gbé jáde nínú ìyá rẹ̀ ní Gaza, ti jáde láyé

oyún oṣù méje ààbọ̀ to ku

Oríṣun àwòrán, Reuters

Sabreen al-Sakani ni awọn dokita nile iwosan Rafah gba ẹmi rẹ la ni aago mejila oru ọjọ Aiku.

Laarin gbogbo rogbodiyan to wa nilẹ, awọn dokita naa ji oyun naa sile aye, ti wọn si n fi ọwọ fẹ afẹfẹ si ni ọfun.

Amọ niwọn igba to jẹ pe Ọlọrun lo ni ẹmi, ẹlẹmi gba ẹmi ọmọ jojolo naa ni Ọjọbọ ana, ti wọn si ti sin i si ẹgbẹ iya rẹ ẹni ti wọn fi orukọ rẹ sọ ọ.

Awọn ọmọde mẹrindinlogun ni wọn fi ado oloro pa ni Rafah lọsẹ to kọja.

Inu ile ti awọn ọmọde naa wa ni wọn doju ado aṣekupani ọhun kọ.

Gẹgẹ bi ikọ ologun Israel ṣe wi, wọn ni awọn ologun Hamas atawọn nnkan amayedẹrun wọn lawọn dajusọ.

Iya to bi iya ọmọ to pada ku yii, Mirvat al-Sakani, sọ fun BBC pe awọn ẹbi ti ṣetan lati tọju ọmọ naa ka ni ko pada ku ni.

O ni wọn ti ṣeto lati gba a gẹgẹ bii ọmọ wọn ki wọn si wo o dagba.

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe ọmọ ikoko naa pada jade laye.

Ninu eeyan ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn (34,000) to ti ku lati ọjọ keje, oṣu kẹwaa ti ogun ti bẹrẹ, o kere tan, ida meji wọn ni wọn jẹ ọmọde ati awọn obinrin.

Ni bayii, miliọnu kan ati ẹgbẹrun mẹrin eeyan ni wọn kora jọ pọ si Rafah, lẹyin ti wọn ti ni ki wọn sun si apa Guusu fun aabo lọwọ ogun.

Àkọlé fídíò, Israel-Gaza War: Alma Muhammed ní ìgbà mẹ́ta ni ẹbí òun sá fún àdó olóró àmọ́ tó sì pa wọn

Àwọ́n dókítà gbé oyún oṣù méje àbọ̀ jáde nínú ìyá tí àdó olóró Israel pa

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn dokita ti gbe ọmọ tuntun kan jade ninu obinrin alaboyun kan ti ado oloro Israel ṣekupa ni Rafah.

Sabreen ni a gbọ pe o ti gbe oyun ọmọ rẹ fun oṣu meje ati aabọ.

Ọpọ ọjọ ni Sabreen ati ẹbi rẹ n gbe ninu ibẹru-bojo pẹlu ogun to n lọ laarin orilẹede Israel ati Palestine.

Amọ, ireti Sabrean dofo loru ogunjọ oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii nigba ti ado oloro kan bu gbamu.

Awọn ọmogun Israel ju ado oloro si ile al-Sakani ni Rafah nibi ti Sabreen ati ọkọ rẹ pẹlu ọmọdebinrin wọn, Malak ti n sun lọwọ.

Sabreen farapa yanayana nigba ti ọkọ rẹ ati ọmọ wọn Malak ti dero ọrun lẹsẹkẹsẹ.

Amọ, ọmọ to wa ninu alaboyun naa ṣi wa laaye nigba tawọn oṣiṣẹ eleto ilera de ibi iṣẹlẹ ọhun.

Wọn gbe Sabreen digba digba lọ sile iwosan nibi ti wọn ti ṣe iṣẹ abẹ pajawiri ti wọn fi gbe ọmọ kuro ninu rẹ.

Aworan ọmọ tuntun ni Rafah

Ko ni si baba ati iya ti yoo fun ọmọ tuntun naa ni orukọ lọjọ ṣuna rẹ

Awọn dokita gbiyanju lati doola ẹmi Sabreen, amọ, ọwọ ti bọ sori.

Ọmọ ti wọn gbe jade ninu rẹ lawọn dokita tun gbiyanju lati doola ẹmi rẹ lẹyin Sabreen ti ku.

Iroyin ayọ ni pe ọmọ jojolo yii to gbe iwọn 1.4kg pada yee.

Awọn dokita ni o yẹ ki ọmọ naa ṣi wa ninu ikun iya rẹ di akoko yii, amọ, ogun to n lọ lọwọ ko fun un lanfani yii.

Awọn dokita ṣalaye pe ọmọ yii ṣi maa wa nile iwosan fun bi oṣu kan ki o to jade.

Awọn dokita sọ pe ohun ibanujẹ to wa nibẹ ni pe bi ọmọ yii ba tiẹ pada ye, o ti di ọmọ orukan.

Ko ni si baba ati iya ti yoo fun ọmọ naa ni orukọ lọjọ ṣuna rẹ.

Ẹgbọn rẹ Malak ti oun naa ba iṣẹlẹ ado oloro naa lọ fẹ sọ ọmọ naa ni Rouh eyi to tumọ si ọkan ni ede Araabu.

Amọ, gbogbo eyi ko le ṣẹlẹ mọ lẹyin ti oun naa ti ba ogun lọ.