Wo pàtàkì iṣan tó ń ṣiṣẹ́ bíi ọkàn, mú kí èèyàn fẹsẹ̀ méjì rìn, ó tún ń mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn lára

Aworan iṣan ninu ẹsẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Image

Iṣan kan wa lara awa eeyan ati awọn ẹranko kọọkan to ṣe pataki pupọ, ohun lo n jẹ keeyan le rin, keeyan si le fẹsẹ mejeeji duro. Orukọ rẹ ni ‘Soleus.’

Lati orukun lọ si isalẹ ẹsẹ ni iṣan yii wa.

Ki i ṣe pe o n jẹ keeyan le rin nikan, o tun ni iṣan meji pataki mi-in ninu to n ṣiṣẹ fun bi ẹjẹ ṣe n rin lara.

Eyi lo fa a tọpọ eeyan ṣe n pe iṣan Soleus ni ‘ọkàn keji.’

Dokita Carles Pedret, akọṣẹmọṣẹ lati ileewe to n ri si ilera nipa ere idaraya ni Yunifasiti Barcelona, ṣalaye fun BBC Mundo pe.

“ Lakọọkọ na, o tobi gan-an. O ni ọpọlọpọ iṣan mi-in ninu.

’’Awọn iṣan gidi to da duro lo ni, ki i ṣe awọn ti wọn so mọra wọn.’’

Ìdúró déédé

Iṣan ẹsẹ

Oríṣun àwòrán, Getty image

Iṣẹ jẹjẹ ni awọn iṣan to n ri si ki eeyan le duro deede, awọn bii iṣan to wa lẹyin, to n jẹ ki ogooro ẹyin naro, n ṣe.

Wọn ko si fun lilo ojiji. Wọn ni agbara lati wa bẹẹ fun ọpọlọpọ wakati lai rẹ eeyan to n lo wọn.

Apẹẹrẹ ẹ ni keeyan jokoo loju kan fun igba pipẹ.

Oun naa lo si n fun wa lanfaani lati duro tabi rin fun igba pipẹ.

Agbara wa fun iṣan yii, o si maa n taari rẹ sara eeyan gẹgẹ bi Dokita Pedret ṣe ṣalaye.

Ida kan pere ninu ìwọ̀n eeyan ni iṣan Soleus, ṣugbọn o ni eroja alagbara ju awọn ẹya ara yoku lọ.

Pínpín ẹ̀jẹ̀ kárí ara

Iṣan yii tun ni iṣẹ pataki to n ṣe lara, o n ba ọkan ṣiṣẹ rẹ lati pin ẹjẹ kari ara.

Dokita Hamilton, ṣalaye fun BBC Mundo pe bi Oluwa ṣe da Soleus yatọ sawọn iṣan yooku.

“ Awọn iṣan nla kan wa lẹyin ẹsẹ, iṣẹ nla, iṣẹ daadaa ni wọn n ṣe nibẹ.

Ẹjẹ le kora jọ sibi orukun lọ sisalẹ ẹsẹ, eyi maa n ṣẹlẹ sawọn agbalagba, o si le ṣe ọmọde naa.

“ Ṣugbọn Aṣẹ̀dá ni oye pupọ, o fi awọn iṣan sinu iṣan ta a pe ni Soleus yii.

Nigba ti iṣan ba kan ara wọn, awọn ti Soleus yoo ko ẹjẹ to korajọ si ẹsẹ kuro, wọn yoo da a pada sinu ọkan wa.”

Bi a ṣe n gbẹsẹ nikọọkan la n da ẹjẹ ẹsẹ pada sọkan wa.

Báwo ni iṣan yìí ṣe lè ṣiṣẹ́ dáadáa?

Gẹgẹ bii awọn iṣan yooku ninu ara, iṣan Soleus naa nilo lati maa ṣiṣẹ deede keeyan le wa lalaafia ara.

Gẹgẹ bi Dokita Pedret ṣe wi, ohun to dara ju lati mu iṣan yii ṣiṣe daadaa ni irin rinrin.

O ni beeyan ba naro to si n rin, iṣan rẹ yoo ṣiṣẹ bo ṣe yẹ.

“ Dokita Peret ni ko digba teeyan ba rin ariwọdii, iṣẹ diẹ pẹlu ọpọlọ ni.

" Ti iṣan ara ba duro deede, o maa n jẹ ki gbogbo ara wa nipo to daa. Awọn ẹya ara yoo si ṣiṣẹ daadaa.

"O maa n din ewu aisan ku, ọpọlọ paapaa yoo siṣẹ daadaa.

"Nipa bẹẹ, eeyan ko ni i lugbadi aisan to maa n jẹ keeyan gbagbe nnkan (Dementia).

Alaafia ara ati ọkan yoo pe perepere’’

Bi Dokita Pedret ṣe ṣalaye.