Ọlọ́pàá yìnbọn pa ẹ̀gbọ́n tó wá bá àbúrò rẹ̀ yọ àyọ̀ ìkẹ́kọ̀jáde ní fásitì LAUTECH, èèyàn méjì míì farapa

Oríṣun àwòrán, LAUTECH
Awọn akẹkọọ fasiti Ladoke Akintola to wa nilu Ogbomosho, nipinlẹ Oyo ti n pe fun idajọ ododo lẹyin ti wọn ni ọlọpaa dede ṣina ibọn bolẹ nibẹ, eyii to yọri si iku agunbanirọ kan lọjọ Iṣẹgun.
Iroyin ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ SARS, ti ijọba fopin si lọdun meji sẹyin ni ọlọpaa to yinbọ naa, eyii to ṣekupa agunbanirọ ti wọn pe orukọ rẹ ni Iyanda Damilola.
Ibatan oloogbe naa, Oluwafemi Iyanda ṣalaye fun ileeṣe iroyin abẹle Punch pe oun farapa latari ọta ibọn ọhun.
Oluwafemi Iyanda, to ṣẹṣẹ kẹkọọ jade ni LAUTECH sọ fun awọn akọroyin pe niṣe ni oloogbe ọhun wa ba oun ṣe ajọyọ ikẹkọọjade oun ki ibọn ọlọpaa to ba nibi ti wọn ti n ṣe ariya ayẹyẹ naa.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ilu Ibadan ni oloogbe ọhun ti n sinlu ṣaaju iku rẹ.
Bi iṣelẹ naa ṣe waye ree...
O ni “Ana ni a ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade, a si wa ni ile faaji kan lagbegbe Under-G fun ariya ṣugbọn ni nnkan bii aago meji oru ni a gbọ ti awọn kan n ja.
“Nigba ti ọrọ naa fẹ maa di rugudu ni a jade sita ti a si ri awọn ọlọpaa to n gbiyanbju lati tu awọn eeyan ka, ti wọn tun n yinbọn si awọn eeyan.
“Ọta ibọn ṣe mi lẹsẹ ṣugbọn igbọn ba ẹgbọn mi to wa ba mi ṣajọyọ lori, ile iwosan LAUTECH ni awọn dokita ti kede pe o ti ku, wọn si ti gbe lọ sile igbokusi laarọ oni.
“Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, mo wa nile iwosan fun itọju, egbò ara mi jin gan ni, amọ mo gbọdọ gba idajọ ododo fun ẹgbọn mi.”
Oluwafemi ṣalaye pe oun da ọlọpaa to yinbọn naa mọ, ati pe ọwọ kan ṣoṣo lo fi gbe ibọn ọhun dani lasiko iṣẹlẹ naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ oyo, Adewale Osifeso ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.
Ẹwẹ, adari ajọ NYSC nipinlẹ Oyo, Odoba Oche naa ti fidi rẹ mulẹ fun ileeṣẹ iroyin abẹle Punch pe ọkan lara awọn agunbanirọ oun ni oloogbe.
Oloogbe kii ṣe akẹkọọ wa, inu ọgba ile ẹkọ wa kọ ni iṣẹlẹ naa ti waye – LAUTECH
Ẹwẹ, awọn alaṣẹ ile ẹkọ LAUTECH ti ni lootọ ni awọn gbọ pe ẹnikan ba iṣẹlẹ naa lọ amọ kii ṣe akẹkọọ awọn.
Alukoro ile ẹkọ naa, Lekan Fadeyi lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Daily Post.
O ni “Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, nnkan bii aago meji oru ni iṣẹlẹ naa waye, ko si waye ninu ọgba ile ẹkọ wa, ile ijo kan lo ti ṣẹlẹ, LAUTECH ko si ni ile ijo kankan tabi ile itura.
“Niṣe ni wọn ja, ati pe akekọọ ti wọn pa kii ṣe akẹkọọ wa.
“Nitori naa nnkan to ṣẹlẹ ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu LAUTECH, ko si ni nnkankan lati ṣe pẹlu ayẹyẹ ikẹkọọjade wa.














