Ẹ̀rù ló ń ba ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá pé ọlọ́pàá àpapọ̀ yóò di àtẹ̀mẹ́rẹ̀, ló ṣe tako ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ - Onímọ̀ ètò àbò

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force
Onimọ nipa eto abo kan, Akin Adeyi, ti sọ pe ọga agba ọlọpaa Naijiria, IGP Kayode Egbetokun n bẹru pe araalu yoo yọ ọwọ awọn ọlọpaa lawo, lo jẹ ko sọ pe Naijiria ko tii pegede lati ni ọlọpaa ipinlẹ.
Adeyi lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.
O ni gbogbo awọn ileeṣẹ agbofinro mii ti wọn da silẹ lati ara ileeṣẹ ọlọpaa lo san ju ọlọpaa ode oni lọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, lara awọn ileeṣẹ ti ijọba fa yọ lati ara ileeṣẹ ọlọpaa ni FRCS, DSS, NSCDC, NDLEA, ati bẹe bẹẹ lọ.
Ninu ọrọ rẹ, o ni ti ijọba ba ṣe idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ, o ṣeeṣe ki ẹtanu wa latari pe awọn ọlọpaa ipinlẹ naa yoo maa ṣe iṣẹ ju ọlọpaa ijọba apapọ.
O ṣalaye pe anfani ti ọlọpaa ipinlẹ maa ṣe fun Naijiria pọ, oun si faramọ pẹlu alaye.
Ẹwẹ, ọpọ awọn eeyan bii Akin Adeyi lo gbagbọ pe, ọlọpaa ipinlẹ dara fun Naijiria lasiko yii, nitori oju wọn yoo le to awọn agbegbe ti oju ọlọpaa ijọba apapọ ti wọn gbe wa lati ipinlẹ mii, ko ni to.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force
Ki lo yẹ ki ijọba ṣe ṣaaju idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ?
Adeyi sọ pe ijọba yoo nilo ko ṣe ọpọ idanilẹkọọ ṣaaju idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ nitori awọn ọlọpaa to wa lode lonii ti kuna ojuṣe wọn akọkọ ninu iṣẹ wọn.
O ni “eredi akọkọ ti a fi da ileeṣẹ ọlọpaa silẹ ni ki wọn dena iwa ọdaran, ki wọn ṣawari iwa ọdaran ko to ṣẹlẹ, ki wọn si tun ṣe iwadii iwa ọdaran lẹyin to ba waye tan.
“Ṣugbọn laye ode oni, ni ṣe ni ọlọpaa n ṣe iwadii awọn ọdaran lẹyin ti iwa ọdaran ba ti waye tan, wọn ti kuna ojuṣe meji akọkọ.”
“To ba jẹ pe ọlọpaa iru eleyii ti a ni bayii ti wọn ti pa ojusẹ wọn akọkọ ti ni wọn tun fẹ da silẹ ni, mi o faramọ.. nitori pe nibo lo wa gẹgẹ bii ọlọpaa ki wọn to ge ori eeyan.”
“Ẹẹkankan lo yẹ ki a maa ri pe wọn fi oju awọn ọdaran lede, amọ ni gbogbo igba lo yẹ ki a maa ri esi iṣẹ ọlọpaa nipa didena iwa ọdaran.”
Akin adeyi, to ti fi akoko igba kan jẹ oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS sọ pe, ijọba gbọdọ ri daju pe ọlọpaa ipinlẹ gbọdọ maa ṣe ojuṣe wọn lai wu iwa bii awọn ọlọpaa to wa lode lonii, o si gbọdọ ṣe idanilẹkọọ fun wọn ṣaaju eto igbanisiṣẹ.
O ni bi bẹẹ kọ, yoo kan da bi igba ti eeyan gbe iyawo keji lai tii ni owo ti yoo fi tọju iyawo akọkọ ni.
Nàíjíríà kò tíì pegedé tó láti ní Ọ́lọ́pàá ìpínlẹ̀ - Ọ́gá àgbà ọ́lọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/Facebook
Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria, IGP Kayode Egbetokun ti sọ pe Naijiria ko tii ṣetan lati ni ọlọpaa ipinlẹ, bo tilẹ jẹ wi pe iṣoro eto aabo pọ lọwọ yii.
IGP Egbetokun fidi ọrọ yii mulẹ nibi apero kan to da lori lilo ọlọpaa ipinlẹ gẹgẹ bi ọna lati mu ki alaafia jọba ni Naijiria.
Eto naa waye niluu Abuja lọjọ Aje ọjọ kejilelogun oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii.
Egbetokun ti AIG Ben Okolo ṣoju rẹ nibi apero naa sọ pe ‘’erongba awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni pe a ko tii to ni ọlọpaa ipinlẹ gẹgẹ bi orilẹede.
Ara awọn iṣoro ti yoo koju idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ni pe igbimọ alaṣẹ awọn ipinlẹ eleyii ti gomina jẹ adari rẹ le ṣi agbara lo pẹlu ọlọpaa ipinlẹ.
Awọn gomina le maa lo ọlọpaa ipinlẹ yala fun anfani ara wọn tabi lati tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.
Ati pe rogbodiyan le maa waye lori ẹni tawọn ọlọpaa yoo maa gba aṣẹ lọwọ rẹ.’’
"Tinubu atawọn gomina fẹnu ko nibi ipade naa lati da ọlọpaa ipinlẹ silẹ"
Lẹyin to sọ pe idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ le ma ṣiṣẹ lọwọ yii ni Naijiria, ọga ọlọpaa Naijiria ko ṣai sọ awọn ọna ti ileeṣẹ ọlọpaa fi le lagbara sii lati koju iṣoro eto to mẹhẹ.
‘’Akọkọ ni pe ijọba le da ajọ aabo araẹni laabo ilu(NSCDC) ati ajọ ẹṣọ oju popo(FRSC) pọ ki wọn si jẹ ẹka kan labẹ ileeṣẹ ọlọpaa,’’ Egbetokun lo sọ bẹẹ.
Ọgaagba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria tun ṣalaye pe o yẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa maa gba ẹgbẹrun lọna ọgbọn eeyan siṣẹ ọlọpaa lọdọọdun ni ibamu pẹlu alakalẹ ajọ iṣọkan agbaye, UNO lori ileeṣẹ ọlọpaa awọn orilẹede.
Bakan naa ni o sọ pe idanilẹkọọ loorekoore fawọn ọlọpaa yoo ṣe iranwọ lori ati gbogun ti iṣoro eto aabo to n koju Naijiria lọwọ yii.
Lai ṣe ani-ani, erongba ọgaagba ọlọpaa tako ti Aarẹ Bola Tinubu lẹyin ti o ṣe ipade pọ pẹlu awọn gomina laipẹ yii lori idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ lati le koju eto aabo to mẹhẹ.
Minisita eto iroyin, Mohammed Idris sọ fawọn akọroyin pe Tinubu atawọn gomina fẹnuko nibi ipade naa lati da ọlọpaa ipinlẹ silẹ.
Amọ, o ṣalaye pe ipade mii yoo tun waye lori ọrọ naa.
Ọlọpaa ipinlẹ yoo ṣe iranwọ nla lori aabo ṣe mẹhẹ ni Naijiria - Goodluck Jonathan
Ẹwẹ, aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Goodluck Jonathan toun naa wa nibi apero ọhun sọ pe ọlọpaa ipinlẹ yoo ṣe iranwọ nla pẹlu bi eto aabo ṣe mẹhẹ ni Naijiria bayii, bo tilẹ jẹ pe o ni awọn ipenija rẹ.
Jonathan ni bi iṣẹlẹ ijinigbe ati iwa ọdaran ṣe n gbilẹ sii n fidi rẹ mulẹ pe Naijiria nilo ọlọpaa ipinlẹ.
Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima ti oun naa wa nibi apero ọhun sọ pe Aarẹ Bola Tinubu koni beṣu bẹgba lati ro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lagbara lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ.
Igbakeji aarẹ ni Tinubu ṣetan lati sẹ agbeyẹwo koko to jade nibi apero to waye lori idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ.
















