Sọ́jà méjì jalè níléeṣẹ́ Dangote, àkàrà tú sépo, Kakí bọ́ lọ́rùn wọn

Oríṣun àwòrán, hqnigerianarmy/Instagram
Ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria ti kede iyọniṣẹ awọn ṣọja meji ti wọn ni wọn jale nibudo ifọpo ileeṣẹ Dangote l’Ekoo.
Awọn ṣoja naa ni Corporal Innocent Joseph ati Lance Corporal Jacob Gani.
Atẹjade ti Adari ikede nileeṣẹ ologun orilẹ-ede yii, Ọgagun Onyema Nwachukwu, fi sita lọjọ Aje, ṣalaye pe ina ọba ni awọn ologun meji naa ji fa lati ibudo ifọpo Dangote.
O ni wọn tun jẹbi ẹsun pe wọn kuro nibi iṣẹ wọn lasiko ti iwadii n lọ lọwọ.
Nwachukwu ṣalaye pe awọn ṣoja yii kuna lati ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ, wọn si tako ofin kẹtadinlọgọta (57) ofin iṣẹ ologun ilẹ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/ X
‘A ti fà wọ́n lé ẹ́ka ìdájọ́ lọ́wọ́’
Ọgagun Nwachukwu sọ pe lẹyin tawọn pari iwadii, ileeṣẹ ologun pinnu lati le awọn ṣoja meji naa danu, awọn si tun fa wọn fun ẹka ti wọn yoo ti lọọ jẹjọ ni kootu lọwọ.
O ni eyi yoo jẹ arikọgbọn fawọn ologun bii tiwọn.
‘’A ti ṣetan lati ṣiṣẹ tiwa fun araalu, lati da aabo bo wọn.
‘’ A rọ awọn araalu lati maa ran wa lọwọ ninu igbiyanju wa lati pese aabo fun wọn, k’alaafia le jọba’’
Bẹẹ ni atẹjade awọn ologun naa wi.

Oríṣun àwòrán, hqnigerianarmy/Instagram
Afẹ́fẹ́ òjò tó lágbára ṣọṣẹ́ l'Ogun, sọ ogójì agbègbè sínú òkùnkùn

Afẹfẹ ojo nla kan to gbilẹ ni agbegbe Sango Otta ni ijọba ibilẹ Afo-Odo/Ota ni ipinlẹ Ogun, ti sọ ogoji agbegbe sinu okunkun bayii.
Iṣẹlẹ naa lo hu opo ina, to si tun ba ọpọlọpọ waya ina, eyi to wo soju titi ijọba, to si fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.
Ileeṣẹ to n rí si ina mọnamọna ni agbegbe naa, Ibadan Electricity Distribution Company tí fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, tí wọn si n rọ awọn olugbe agbegbe naa lati yago fun awọn opo ina ati waya ina to wo soju títí naa.
Ninu ikede ti wọn fi sita, ileeṣẹ to n pina mọnamọna, IBEDC ni "nítorí awọn opo ina to dawo lẹyin ti ojo aroroda to rọ ni agbegbe Sango Otta ati Mowe, awọn onibara wa ni awọn agbegbe wọnyi bi lyana lyesi, Osuke Town, Egan Road, lyana Ilogbo, Ijaba, Ijagba, Itele, Lafenwa, Singer, Joju, Alishiba, Oju Ore, Tollgate, Eledi, Akeja, Abebi, Osi Round About, Ota Town, Ota Industrial Estate, Igberen, lju, Atan, Onipanu, Obasanjo, Lusada, Arigba, Odugbe, Ado-Odo, Igbesa, Owode, Olokuta, Hanushi, Bamtish Camp Lufiwape, Eltees Farm, August Engineering, Spark Cear Soap Ayetoro, Amazing Grace Oil, Christopher University, Royal Garden Estate, Pentagon Estate ati awọn agbegbe mii to sun mọ awọn agbegbe yii ko ni anfani lati lo ina mọnamọna lasiko yii.
Bakan naa ni ileeṣẹ naa rọ awọn olugbe agbegbe yii lati ma ṣe gbiyanju pe wọn fẹ tọwọ bọ ina tabi pe wọn fẹ tun ṣe.
Wọn wa jẹ ko di mimọ pe awọn akọsẹmọsẹ ti balẹ si awọn agbegbe naa lati bẹrẹ atunṣe, lati paarọ awọn opo ina to dawo naa.
"A rọ yín pe ki ẹ yago fun opo ina to dawo ati awọn waya ina to wa ni ibẹ eyi ojo kọlu. Ẹ fi ohun gbogbo to wa leti, ẹ ma ṣe igbiyanju lati tun ohunkohun ṣe fun ara yin.
"Awọn akọsẹmọsẹ ti bẹrẹ ìṣẹ lati paarọ awọn opo ina, ti ṣe atunse ni kiakia kí ina mọnamọna le pada. A tọrọ aforijin."
Ẹwẹ, fọnran kan to tẹ wa lọwọ safihan bí awọn opo ṣe wo lu ọkọ bọọsi akero ile ẹkọ kan ati awọn ọkọ mii.
Ṣugbọn ohun to jẹ idunnu fun ọpọlọpọ ni pe ko si ẹnikẹni to ba iṣẹlẹ naa lọ tabi farapa.




















