"Ẹ̀rù máa ń bà wá tẹ́lẹ̀ láti farahàn bíi oníṣẹ̀ṣe l‘Oyo, Ọba Adeyemi ló tì wá lẹ́yìn tí ìṣẹ̀ṣe kò fi di àtẹ̀mẹ́rẹ̀"

Àkọlé fídíò, Ọba Adeyemi: Àwọn oníṣẹ̀ṣe ṣàlàyé ìdí tí wọn fi ń rántí Aláàfin tó papòdà lẹ́yìn ọdún méjì
"Ẹ̀rù máa ń bà wá tẹ́lẹ̀ láti farahàn bíi oníṣẹ̀ṣe l‘Oyo, Ọba Adeyemi ló tì wá lẹ́yìn tí ìṣẹ̀ṣe kò fi di àtẹ̀mẹ́rẹ̀"

Awọn onisẹse nilu Oyo ti n se idaro Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta to waja ni dun meji sẹyin.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejilelogun osu Kẹrin ọdun 2022 ni Ọba Adeyemi dara pọ mọ awọn baba nla rẹ, eyi to pe ọdun meji bayii.

Idi ree ti BBC Yoruba se morile ilu Oyo lati foju se mẹrin bi awọn eeyan ilu naa yoo ti se iranti Alaafin to waye naa.

Amọ lasiko ta wa nibẹ, kikida awọn onisẹse ati awọn mọlẹbi Alaafin, nikan ni wọn seto iranti ọdun meji ti Alaafin papoda naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Jagun Ọlọbatala Alaafin nilu Oyo, Oke Adejare salaye pe awọn onisẹse ko le gbagbe Alaafin nitori bo se gbe ẹsin ibilẹ larugẹ.

Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta

Oríṣun àwòrán, Alaafin of Oyo/Facebook

"Alaafin lo fi ofin lelẹ wipe ki awọn maa se iranti oun lẹyin ti oun ba papoda tan"

“A ti n ni Ọba nilu Oyo, amọ ti Ọba Adeyemi yatọ patapata nitori o jẹ ọba to ko awọn ẹlẹsin mọra pupọ.

Alaafin yii ko si se ẹlẹyamẹya laarin awa ẹlẹsin gbogbo, a si dupẹ pe Alaafin yii ni ko jẹ ki oro run nilu Oyo .

Akoko kan tiẹ wa, to jẹ pe ẹru maa n ba awa onisẹse, ti a ko si le farahan pe ẹlẹsin ibilẹ ni wa, amọ Alaafin lo duro bii oniduro fun wa.”

Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Adejare ni Ọba Adeyemi ni ko jẹ ki awọn ẹlẹsin agbasodi le awọn wọle nilu Oyo.

O ni oriade yii ni ko jẹ ki ẹsin ibilẹ di itẹmẹrẹ, ti kii si fi ọwọ yẹpẹrẹ mu asa isẹse.

Nigba to n salaye idi ti wọn se tẹsiwaju lati maa se iranti iku Alaafin, Adejare ni Alaafin to waja naa lo fi ofin lelẹ wipe ki awọn maa se iranti oun lẹyin ti oun ba papoda tan.