Kókó méje pàtàkì nípa ìgbé ayé Taoreed Lagbaja àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lásìkò tó wà nípò olúdarí àpapọ̀ iléeṣẹ́ ológun

Oríṣun àwòrán, Defence HQ
Kii se iroyin tuntun mọ pe Oludari agba fun apapọ ileesẹ ologun ilẹ wa, Taoreed Lagbaja ti papoda.
Ọjọ Isẹgun, ọjọ Karun osu Kọkanla ni Lagbaja mi kanlẹ nile iwosan kan nilu Eko lasiko aisan.
Amọ bi onirese Taoreed Lagbaja ko ba fin igba mọ, awọn eyi to ti fin silẹ, ko le parun.
Idi ree ti BBC se se akojọ awọn ohun pataki to yẹ ki ẹ mọ nipa oloogbe naa ati àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lásìkò tó wà nípò olúdarí àpapọ̀ iléeṣẹ́ ológun.
- Ọjọ Kejidinlogun osu keji ọdun 1968 ni wọn bi Ọgagun Taoreed Lagbaja nilu Ilobu nipinlẹ Osun.
- O lọ sile ẹkọ girama St Charles ati ile ẹkọ awọn olukọni onipo keji nilu Osogbo, ko to dara pọ mọ ileesẹ ologun lọdun 1987.
- Akẹkọjade nipa imọ ẹkọ Geography nileesẹ ologun Nigeria Defence Academy ni Taoreed Lagbaja.
- O si gba oye kun oye fun iwe ẹri keji ninu imọ ijinlẹ nipa aato ohun gbogbo (Strategic Studies) lọdun 2014 lati ile ẹkọ ologun nilẹ Amẹrika (US Army War College)
- O bọ sipo ologun second lieutenant nileesẹ ologun ilẹ wa bii ipẹẹrẹ oloogun lẹyin to ti kẹkọ nileesẹ ologun, to si yege lọjọ Kọkandinlogun osu keji ọdun 1992.
- Lagbaja jẹ ara awọn akẹkọ ologun to jade in ọwọ akẹkọ kọkandinlogoji tileesẹ ologun NDA.
- Ologbe naa tun kopa ninu ikọ apẹtusawọ ti ajọ isọkan agbaye lọ si orilẹede Democratic Republic of Congo (MONUC) laarin ọdun 2004 si 2005.
- Laarin osu Kẹfa si ikẹjọ ọdun 2010, Lagbaja dara pọ mọ idanilẹkọ fun ikọ ologun to wa nilẹ ni sẹpẹ labẹ ajọ ECOWAS nibudo ipẹtusaawọ nilu Bamako lorilẹede Mali.
- Bakan naa lo tun kopa ninu gbigbogun ti ikọ Boko Haram, to si se sakaa fun awọn agbesunmọmi naa labẹ ijọba Buhari.
- Ọga ologun to di oloogbe naa tun kopa ninu ikọ ologun to n gbogun ti awọn agbesunmọmi, LAFIYA DOLE fun ọdun mẹta laarin ọdun osu kejila ọdun 2015 si osu kinni ọdun 2018.
- Akoko yii si lo lewaju ikọ ologun amusẹya nilu Manguno lẹba ilu Maiduguri.
- Lati igba ti wọn ti gba Lagbaja sile isẹ ologun, lawọn iroyin kan ti ni o jẹ eeyan ti ilera rẹ jẹ ẹlẹgẹ, to si ti n ba aisan kan to fi pamọ ja eyi to maa n mu ko kuro ni ẹnu isẹ lọpọ igba, nigba miran, aisan naa maa n gbe lọ soke okun fun itọju.
- Lasiko ti Taoreed Lagbaja jẹ Oludari apapọ fun ileesẹ ologun ilẹ wa, se ni ọwọja ikọlu awọn agbebọn Boko Haram n le si paapaa ni ẹkunariwa ati aarin gbungbun Naijiria.
- Isẹlẹ agbayanu to waye lọjọ keje osu kẹta ọdun 2024, lasiko ti Lagbaja wa lori aga oludari ileesẹ ologun ni bi awọn agbebọn se ko awọn akẹkọ to le ni igba kuro nile ẹkọ wọn nilu Kuriga, nijọba ibilẹ Chikun, nipinlẹ Kaduna.
- Bakan naa, awọn agbegbe to wa ni olu ilu ilẹ wa, Abuja foju wina oniruuru ikọlu agbebọn, ti wọn si ji ọpọ mọlẹbi lọ ati awọn ololufẹ wọn.
- Ọpọ ninu wọn awọn mọlẹbi ọhun ni agbebọn naa pa nigba ti awọn miran san owo idoola ẹmi, ki wọn to gba idande.
''A fẹ́ kí Tinubu yọ̀nda okú Lagbaja fún wa kí á lè sin ín ní ìlànà mùsùlùmí nílùú rẹ̀''

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X
Olobu ti Ilobu, Ọba Ashiru Olatoye Olanyan, ti rawọ ẹbẹ si Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati yọnda oku ọga agba ileeṣẹ Naijiria, Taoreed Lagbaja, fawọn araalu naa ki wọn le sin in ni ilana ẹsin musulumi niluu abinibi rẹ.
Olufemi Salako ẹni to gbẹnu sọ fun Olobu lo fidi ọrọ mulẹ fun BBC Yoruba.
Kabiyesi Olobu ṣapejuwe iku Lagbaja gẹgẹ bi adanu nla fun gbogbo ọmọbibi ilu Ilobu ati orilẹede Naijiria lapapọ.
Ori ade naa tun rọ Aarẹ Tinubu ati ileeṣẹ ologun lati jẹ ki wọn gbe oku oloogbe naa wa si ilu Ilobu lati se ayẹyẹ ikẹyin fun un
Tajudeen Lagbaja ẹni to jẹ olori ẹbi ni agboole oloogbe naa ti sọ wi pe, awọn ko fẹ ki wọn sin oku olori awọn ọmọ ologun ni Naijiria si Abuja.
''Iku Lagbaja jẹ iku to fẹ gba ẹmi mi, iku naa si jẹ ibanujẹ fun emi gẹgẹ bii olori ẹbi Lagbaja lapapọ.
Ọpọlọpọ eeyan lo ti ku lagboole wa sugbọn iku Taoreed jẹ iku ibanujẹ ati adanu fun gbogbo ẹbi ati ilu Ilobu,'' Tajudeen Lagbaja.


Mulikatu Lagbaja ẹni to jẹ iyawo olori ẹbi ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to fẹran ẹbi ati ilu rẹ.
O ni Taoreed Lagbaja kii se oni wahala eeyan rara.
Ọ̀gá àgbà fún àpapọ̀ iléeṣẹ́ ológun, Taoreed Lagbaja, jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Defence HQ
Iroyin kan to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti kede pe Ọga agba fun ileesẹ ologun, Taoreed Lagbaja, jade laye
Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, ti kede iku oludari apapọ ileeọ̀ẹ ologun Naijiria, Taoreed Abiodun Lagbaja.
Atẹjade kan to Bayo Onanuga, tii se agbẹnusọ fun aarẹ Bola Tinubu fọwọsi eyi to gbe soju opo X rẹ, lo sisọ loju isẹlẹ naa.
Bẹẹ ba gbagbe, aimọye igba ni awọn eeyan kan ti n kede pe ọgagun Lagbaja ti papo da amọ ti ileesẹ aarẹ ati Ologun n sẹ pe ahesọ ọrọ ni iroyin naa.
Lẹyin ofege iroyin iku Lagbaja yii ni Aarẹ Bola Ahmed Tinubu kede iyansipo adele ọga agba ileeṣẹ ologun Naijiria.
Oluwa rẹ ni Ọgagun Olufemi Olatubosun Oluyede, ti aaẹ ni yoo maa dele, lati gba ipo lọwọ Taoreed Lagbaja tori igba diẹ sẹyin ni Ọgagun Lagbaja ko ti yọju si gbangba.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
"Ọdun merindinlọgọta ni Lagbaja lo loke eepẹ, ko to jade laye lasiko aisan"
Amọ atẹjade ti Onanuga fisita ni alẹ ana ọjọ Isẹgun ni ọga ologun naa jade laye nilu Eko tori aisan kan to se e.
Ọdun merindinlọgọta ni Lagbaja lo loke eepẹ, ko to jade laye.
Ọjọ kejidinlọgbọn osu Keji ọdun 1968 ni wọn bi Taoreed Lagbaja, ti aarẹ Bola Tinubu si yan sipo ọga ologun agba fun apapọ ileesẹ ologun ilẹ wa ni ọjọ kkandinlogun osu Kẹfa ọdun 2023.
Iyawo rẹ, Mariya ati ọmọ meji lo gbẹyin ọgagun Abiodun Lagbaja.
Lt. General Lagbaja is survived by his beloved wife, Mariya, and their two children.
















