Àwọn wo ló wà nídìí ikọ̀ agbébọn Lakurawa tó ń ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Sokoto?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Sokoto n kọminu nipa ẹgbẹ agbesunmọmi kan to n ṣọṣẹ ni ijọba ibilẹ marun un nipinlẹ naa.
Igbakeji gomina ipinlẹ Sokoto, Alhaji Idris Muhammad, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu ọrọ rẹ lasiko abẹwo awọn akẹkọọ ileeṣẹ ọmogun si ipinlẹ naa laipẹ yii.
Alhaji Muhammad sọ fun BBC pe awọn ọmọ ẹgbẹ Lakurawa ti wọn ni ohun ija oloro lọwọ n waasu fawọn olugbe ilu bii Tangaza, Gudu, IIIela, Binji atawọn abule kan ni Silame.
Nibo lẹgbẹ Lakurawa ti wa?

Ẹnikan ti ko fẹ ki BBC darukọ oun sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Lakurawa wọ Sokoto lati ẹkun Sahel to de awọn orilẹede bii Mali ati Niger.
Ẹgbẹ alakatakiti ẹsin yii n sọ fawọn eeyan kaakiri ni ipinlẹ Sokoto wi pe ki wọn ma gba awọn ọlọpaa ati ologun laaye, ki wọn si tun tako lilọ ile ẹkọ.
Awọn ẹgbẹ yii ni a gbọ pe oniruuru ede ni wọn fi n ba awọn eeyan sọrọ.
Akọsilẹ fihan pe awọn eeyan yii n waasu, wọn si n kilọ nigba tawọn kan si n ṣe ogbufọ fun wọn lede Hausa, Fulani, Abzinanci, Tubanci, Barbari, ati lede oyinbo gan an.
Awọn ọmọ ẹgbẹ Lakurawa yii ni wọn sọ pe wọn pọ gan an, ẹnikan sọ fun BBC pe o maa n to bii ọkọ mẹwaa si mẹẹdogun ti wọn maa n di mọra ti wọn ba n wọ inu ilu lọ.
Akọsilẹ fidi rẹ mulẹ pe wọn ti ṣe agbekalẹ ofin tawọn eeyan n tẹle fun araalu, bakan naa ni wọn tun n ṣe eto irolagbara pẹlu iranwọ owo Sefa fawọn ọdọ.
Ko tan sibẹ o, awọn eeyan yii tun n gba owo ori ati saka.
Wọn maa n gbe ẹran ọsin ẹnikẹni to ba kọ lati san owo ori ati saka lọ ni titi ẹni naa yoo san an.
Olugbe agbegbe tawọn alakatakiti ẹsin yii ti n ṣọṣẹ kan sọ fun BBC wi pe ijọba ibilẹ meji ni wọn ti n ṣọṣẹ julọ nipinlẹ Sokoto.
O ṣalaye pe ko si ibi tawọn alakatakiti ẹsin yii kii de yatọ si olu ileeṣẹ ijọba ibilẹ Gudu.
Laipẹ yii ni a gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Lakurawa yii ṣe ikọlu sawọn ọmogun Naijiria nibi ti eeyan mẹrin ti ku.















