Lẹ́yìn fídíò ìbálòpọ̀ ní ọọ́físì tó lu orí ayélujára pa, ẹ wo ìgbésẹ̀ tí Equatorial Guinea gbé

 Baltasar Ebang Engonga

Oríṣun àwòrán, Baltasar Ebang Engonga

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbakeji Aarẹ orilẹede Equatorial Guinea, Teodoro Obiang Mangue, fawọn eeyan orilẹede naa lati yag o fun ibalopọ ni ọfiisi.

Mangue sọ pe ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ yii ba ṣi mọ lori yoo jiya labẹ ofin.

Ikilọ yii waye lẹyin oriṣiiriṣii fọnran ibalopọ to lu ori ayelujara pa lorilẹede naa.

Awọn fidio ibalopọ naa ni iroyin sọ pe o n ṣafihan bi oṣiṣẹ ijọba kan, Baltasar Ebang Engonga, ti n ni ibalopọ pẹlu awọn obinrin to fi mọ iyawo awọn eeyan pataki kan ni ọfiisi rẹ.

Ọgbẹni Engonga ni adari ajọ to n ṣewadii ṣiṣe owo ilu kumọ kumọ, o si tun jẹ ibatan aarẹ orilẹede Equatorial Guinea.

BBC ti ke pe ọkunrin naa lati sọrọ si iroyin naa to ti lu ori ayelujara pa.

Igbakeji Aarẹ ni oṣiṣẹ ijọba ti ọwọ ba tẹ pe o n ni ibalopọ ni ọfiisi, yoo lọ rọkun nile

Ẹwẹ, Ọgbẹni Engonga ti sọ loju opo Facebook rẹ wi pe inu oun ko dun, bakan naa lo fi fọto ara rẹ pẹlu obinrin kan atawọn ọmọ sibẹ.

Engonga kọ ọ sibẹ pe ẹbi oun ṣe pataki ju ohunkohun lọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbakeji Aarẹ Tedoro Obiang Mangue ti sọ pe oṣiṣẹ ijọba ti ọwọ ba tẹ wi pe o n ni ibalopọ ni ọfiisi yoo lọ rọkun nile lẹnu iṣẹ tori o iru iwa yii lodi sofin.

Bakan naa ni igbakeji aarẹ paṣẹ pe ki ẹrọ kamẹra wa ni gbogbo ile ijọba ati ileẹjọ lati le maa tu aṣiri awọn iwa aimọ.

Atẹjade kan ti ọfiisi igbakeji aarẹ fi sita ṣalaye pe igbesẹ yii waye nitori fidio ibalopọ to lu ori ayelujara pa, eyi to si ti ba orukọ orilẹede Equatorial Guinea jẹ.

Ọfiisi Igbakeji Aarẹ tun sọ pe ijọba ti paṣẹ iwadii ohun to ṣokunfa fidio ibalopọ to lu ori ayelujara pa yii.

Awọn fidio yii jade lẹyin ti wọn fọwọ ofin mu Ọgbẹni Engonga lori ẹsun iwa ajẹbanu eyi ti ijọba ṣafihan rẹ lori ẹrọ amohunmaworan TVGE.

Ni ọsẹ to lọ ni Igbakeji Aarẹ Obiang sọ pe fidio ibalopọ ti lu ori ayelujara pa, o si sọ fawọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ wi pe ki wọn wa nnkan ṣe si i.

Gẹgẹ bii adari ajọ NFI, Ọgbẹni Engonga n ṣiṣẹ lori gbigbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọ kumọ.

Lẹyin ti fidio ibalopọ naa jade tan ni olupẹjọ ijọba lorilẹede Equatorial Guinea, Anatolio Nzang Nguema, sọ pe ijọba yoo gbe Ọgbẹni Engonga lọ ileẹjọ ti o ba ti karun ibalopọ.