Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Ijọba apapọ ti tu awọn ọmọde to fẹsun iditẹgbajọ kan silẹ nilẹ niluu Abuja

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu paṣẹ pe ki wọn yọ okun lọrun awọn ọmọde naa

Aarọ oni lawọn ọmọde naa foju bale ẹjọ, ti ijọba si sọ pe oun ko ba wọn ṣe ẹjọ mọ

Odidi oṣu mẹta gbako lawọn ọmọde naa lo latimọlẹ lẹyin ti ọlọpaa mu wọn lasiko iwọde ebi n pa wa

Ajọ EFCC ti fi ṣikun ofin mu gomina ana nipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa

Lori ẹsun lilu owo ti iye rẹ le ni tiriliọnu kan naira ni nponpo laarin ọdun 2015 si 2023

Lara ẹsun ti wọn kan ni fifi ogoji biliọn ra afẹfẹ gaasi

Ati fifi owo ijọba ra awọn ilegbe kan niluu Abuja ati Asaba

Oni loni n jẹ, ẹni a bẹ lọwẹ

Eto idibo Aarẹ Amẹrika ti bẹrẹ ni pẹrẹwu o

Agbegbe Vermon ni East Coast ni eto idibo naa ti bẹrẹ ni afẹmọju, ko to ka awọn bii indiana, Kentucky ati New York

Donald Trump ati Kamala Harris ni wọn jọ n forigbari

Ti o ba fẹ mọ si nipa eto idibo naa