"Ìkọlù jàndúkú lórí omi Somalia dàbí ìgbà tí èèyàn gba ọjọ́ ikú"

Ole ori omi Somalia pẹlu ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ole ori omi Somalia pẹlu ibọn lọwọ
    • Author, Mazyar Moshtagh Gohari
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

BBC bawọn awakọ oju omi Pakistan ati Iran sọrọ ti wọn si ṣalaye pe ọkan lawọn maa n fọwọ mu ninu kebi pa ẹbi awọn tabi kawọn ole oju omi Somalia ji awọn gbe lọ.

Awọn ole ori omi n da awọn apẹja laamu lagbami okun 'India Ocean.'

Awọn ti wọn n fi ọkọ oju omi ṣiṣẹ ṣalaye pe ẹgbẹẹgbẹrun owo dọla lawọn maa n san fawọn ẹṣọ lati le daabo bo awọn.

Arabinrin Maryam ati ọkọ rẹ, Gul Mohammad n reti ọdọmọkunrin wọn, Rasool Bakhash, ẹni ogun ọdun lati pada dada de lati okun India to ti lọ ṣiṣẹ.

Maryam ni awọn bẹrẹ si ni beere kaakiri nipa ọmọ awọn, amọ, ko si ẹni to le dawọn lohun.

Lẹyin ọsẹ diẹ ni iroyin kan maryam ati ọkọ rẹ lara pe awọn janduku ori omi Somali lo mu ni igbekun.

Awọn obi Rasool Bakhsh ni abule wọn lorilẹede Iran

Oríṣun àwòrán, Mazyar Moshtagh Gohari

Àkọlé àwòrán, Awọn obi Rasool Bakhsh ni abule wọn lorilẹede Iran

Oṣu n gori oṣu lai gbọ iroyin kankan.

Ṣadeedee ni wọn gba ipe kan, ila ipe naa ko jalẹ daadaa.

Ṣugbọn wọn mọ pe ọmọkunrin wọn Rassol Bakhsh lo n sọrọ.

Rasool bẹrẹ sii sunkun lori ipe pẹlu awọn obi rẹ, o ni apa ti wa ni gbogbo ara oun.

Maryam ni oun sọ fọmọ awọn wi pe awọn ko lowo lọwọ tori awọn o rọwọ họri.

Owo itusilẹ

$12,000 lawọn ole ori omi ti ji Rasool gbe n beere fun, owo ti ẹbi rẹ ko le ri laelae.

Abule kan to jinna lẹkun Chabahar lawọn obi rẹ n gbe lorilẹede Iran.

Ọda to da lera wọn ti jẹ ki ọpọ awọn ọdọ maa lọ fi ẹmi wọn wewu lori okun ''India Ocean.''

Mama Rasool rin lati ẹkun kan si omiran lati wa owo itusilẹ ki ọmọkunrin rẹ le gba ominira lọwọ awọn ajinigbe.

Maryam ta gbogbo nkan ti ẹbi wọn ni lati le kowo jọ gba ọmọkunrin rẹ silẹ lọwọ awọn to ji i gbe.

Ijinigbe tabi ebi

Saleem Khan atawọn ọmọbinrin rẹ ni Karachi
Àkọlé àwòrán, Saleem Khan atawọn ọmọbinrin rẹ ni Karachi

Awọn apẹja ti BBC ba sọrọ ni awọn naa mọ ewu to wa lori omi, ṣugbọn ko si ohun tawọn le ṣe si ọrọ naa.

''Ti mo ba sọ pe ẹru ko bami, irọ ni mo pa, ni sẹ lo dabi ẹni pe eeyan n fẹsẹ ara rẹ rin lọ sibi ti iku yoo ti pa a.

Ebi naa lo maa pa wa mọ'le ti a ko ba lọ,'' Saleem Khan, apẹja ẹni ọdun mejidinlogoji to n gbe ni Karachi lorilẹede Oakistan lo sọ bẹẹ.

Khan ni oun bọ sọwọ awọn ole ori omi Somalia lọdun 2018.

O fikun ọrọ rẹ pe bawọn ajinigbe ori omi yii tun ti pada n jẹ ki ọkan oun poruuru.

O ni wọn gba ọkọ oju omi awọn ti wọn si lo o lati ṣe ikọlu sawọn ọkọ omi nla.

Lẹyin naa ni wọn gbe wọn lọ si asalẹ kan nibi ti wọn wa fun ogunjọ lai fi ounjẹ tabi omi kan ẹnu.

Wọn fi wọn silẹ lẹyin ti wọn ṣe adehun kan pẹlu awọn anjinigbe naa.

Saleem bẹru lati pada sori omi, o wa isẹ mi-in ṣugbọn ko ri.

Awọn akẹgbẹ rẹ sọ fun un wi pe ko sewu lori omi mọ, amọ, o tun moribọ ninu ikọlu kan ti wọn ṣe si i.

O ni bi oun ti awọn ajinigbe ori omi ọhun bi wọn ṣe n bọ loun fa awọn tawọn fi n pẹja ja ti awọn si moribọ.

Awọn ole naa ṣe ikọlu sawọn ọrẹ rẹ, diẹ loku ki wọn ṣeku pa oun gan an.

Alejo ọran

Kii ṣe ọkọ oju omi kekeke gan an lawọn janduku n wa, ṣugbọn wọn maa n lo o lati mawọn ọkọ oju omi nla.

Awọn apẹja sọ pe niṣe lawọn janduku ori omi yii maa n ṣe bii alejo ọran.

Awọn apẹja ni awọn janduku yii maa n gba ounjẹ awọn, bakan naa ni wọn maa n lo awọn awakọ oju omi awọn lati ṣe ikọlu si awọn ọkọ nla.

Ajọ ẹṣọ EUNAVFOR ilẹ Yuroopu to n gbogun tawọn ole ori omi naa fidi rẹ mulẹ.

Aworan awọn ọmogun India nibi ti wọn doju ija kọ awọn janduku to ji ọkọ oju omi gba

Oríṣun àwòrán, Indian Navy

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ọmogun India nibi ti wọn doju ija kọ awọn janduku to ji ọkọ oju omi gba

Ọpọ awọn ọkọ oju omi nla nla lo maa n ori omi okun India ''Ocean'' kọja lati ori omi Somalia lọ si Okun Pupa titi de Suez Canal.

Ọna ori omi yii lo ya julọ lati ilẹ Asia si Yuroopu.

Nkan bii ida 12% owo ori omi lo n ṣẹlẹ lori OKun Pupa, amọ, ko si alaafia lagbegbe naa mọ bayii.

Awọn alajangbila Houthis ti Iran n ṣatilẹyin fun ni Yemen ṣe ikọlu sawọn ọkọ oju omi kan lati le gbaruku ti Gaza.

Ikọlu yii lawọn apẹja gbagbọ pe o ṣokunfa bawọn janduku ori omi ni Somalia ti tun pada bayii.

 Mohammad Ashraf n ṣayẹwo ọkọ oju omi rẹ tuntun
Àkọlé àwòrán, Mohammad Ashraf n ṣayẹwo ọkọ oju omi rẹ tuntun

Okowo to lowo lori

Mohammad Ashraf n duro ni ebute ọkọ oju omi ni Karachi ki iṣẹ fi pari lori ọkọ oju omi rẹ.

Ọdun kan ati abọ ni Ọgbẹni Ashraf fi duro ki iṣẹ fi pari lori ọkọ oju omi ọhun. ati pe $150,000 lo na lori ọkọ oju omi naa lati ibẹrẹ debi ibi to wa bayii.

Ashraf ni ẹru n ba oun tori awọn janduku ori omi le mu mawọn tabi ki yinbọn pa awọn gan an tawọn gbọ si wọn lẹnu.

Maapu to n ṣafihan awọn agbegbe tawọn janduku ori omi ti n ṣọṣẹ julọ lori okun Arabia.
Àkọlé àwòrán, Maapu to n ṣafihan awọn agbegbe tawọn janduku ori omi ti n ṣọṣẹ julọ lori okun Arabia.

Awakọ oju omi Qayoum, ẹni ogoji ọdun lati Baluchistan lorilẹede Iran ti n pẹja lori omi yii fun ọjọ pipẹ.

Amọ, oun naa gẹgẹ bii Ashraf atawọn mi-in n san ẹgbẹẹgbẹrun owo dọla fawọn ẹṣọ alaabo Somalia ti wọn daabo bo wọn lọwọ awọn janduku ori omi.

Aworan awakọ oju omi Qayoum lori ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Mazyar Moshtagh Gohari

Àkọlé àwòrán, Aworan awakọ oju omi Qayoum lori ọkọ rẹ

Awakọ oju omi Qayoum sọ pe awọn ẹṣo yii lo tun maa n fawọn ni iyọnda lati pẹja lori omi Somalia.

O ni awọn mọ pe ayederu naa ni gbogbo rẹ tori wọn maa n kilọ fawọn lati ma fi tikẹẹti tawọn gba han ẹnikẹni tawọn ba de ebute.

Ko si ẹni to mọ bo ya awọn ẹṣọ yii tọna labẹ ofin.

Awọn apẹja ni awọn maa n sun mọ ebute omi kawọn to ri iyọnda lati pẹja gba.

Awọn apẹja Pakistan ati Iran ṣalaye pe awọn kọkọ maa n paarọ owo na ni Iran ki ẹni to bawọ paarọ owo sanwo naa fun ẹlomiran ni Dubai.

Wọn ni ti wọn sanwo naa fun ni Dubai ni yoo pada fi owo naa ranṣẹ si Somalia.

Maapu to n ṣafihan ọna tawọn apẹja maa n gba lọ sanwo fawọn ẹṣọ ori omi.
Àkọlé àwòrán, Maapu to n ṣafihan ọna tawọn apẹja maa n gba lọ sanwo fawọn ẹṣọ ori omi.

Aisun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oriṣiiriṣii iroyin lo maa n jẹyọ ni ibudokọ oju omi Karachi.

Awakọ oju omi Ghulam Rashid sọ awọn janduku ori omi ṣe ikọlu si ọkọ ọrẹ oun lọdun to lọ.

O ni bawọn to wa ninu ọkọ naa ṣe gbiyanju lati salọ ni wọn yinbọn mọ wọn.

Rashid ni awọn janduku ori omi naa ju ẹnikan to ṣeṣe ninu awọn to wa ninu ọkọ naa sinu omi laaye.

Rashid ni gbogbo iru iriri bayii ni kii jẹ kawọn le sun lalẹ.

Lẹyin ọdun kan ni igbekun awọn ajinigbe ori omi, Rasool Bakhsh, gba ominira o si darapọ mọ ẹbi rẹ.

O wa lara awọn awakọ oju omi ti wọn gbominira lẹyin tawọn ẹbi wọn san owo itusilẹ to ju agbara wọn lọ tan.

Karachi Saleem Khan gbe Neemra ọmọdebinrin lọwọ.

Khan mọ pe oun si n pada sori omi laipẹ, ẹbi rẹ naa mọ pe tori awọn lo fi n ṣe gbogbo nnkan to n ṣe.

Alẹ ni akoko to le julọ fawọn apẹja.

Khan ni ki oun to sun lalẹ, oun kọkọ maa n wo fọto mama oun, lẹyin naa fọto iaywo atawọn ọmọ oun.

O ni pẹlu omije loju loun maa n fi awọn fọto yii si aya oun ti orun yoo fi gbe oun lọ.