Ìdí tí mo fi sọ pé APC àtàwọn ọmọ Nàìjíríà ni yóò jọ wàákò nínú ètò ìdìbò ọdún 2027 - Makinde

Aworan Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria ati ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo jọ waako ninu eto idibo ọdun 2027.

Makinde sọrọ yii nibi ifilọlẹ olu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lẹkun iwọ oorun guusu orilẹede Naijiria to waye niluu Ibadan lọjọ Abamẹta ọjọ keji oṣu Kọkanla ọdun 2024 yii.

Nibi to ti n ṣe ifilọlẹ olu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ọhun ti wọn fi orukọ Họnọrebu Soji Adagunodo sọ ni Makinde tun ti sọ pe PDP gbe igbesẹ naa lati da Họnọrebu Adagunodo lọla fun iṣẹ takun takun to ti ṣe ninu eto oṣelu nilẹ Yoruba.

Nibẹ naa tun ni gomina ipinlẹ Oyo ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria ni yoo koju APC ninu ibo ọdun 2027 wi pe kii ṣe ẹgbẹ oṣelu alatako PDP.

Makinde ṣalaye pe ohun to ṣe pataki bayii ni ki PDP ṣiṣẹ to yẹ ki wọn ṣe lati jẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni iṣọkan, ki wọn si jẹ kawọn ọmọ Naijiria sọrọ ninu ibo to n bọ.

‘’Fun awọn to n sọ wi pe ẹgbẹ oṣelu APC n na ọwọja rẹ de inu awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lati le din agbara wọn ku, mo fẹ sọ wi pe awọn nnkan kan wa ti ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba lọwọ ko lagbara lati ṣe ninu ẹgbẹ oṣelu alatako.

Fun apẹẹrẹ, ẹgbẹ oṣelu APC ko le mọ erongba mi ati ti Gomina Ademola Adeleke ipinlẹ Osun.

Ati pe awọn ọmọ Naijiria ati ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn yoo jọ waako ninu eto idibo ọdun 2027.

Kii tiẹ ṣe pẹlu PDP rara, tori idi eyi, ẹ jẹ ki a ṣiṣẹ tiwa to wa ni ikawọ wa lati wa ni iṣọkan.

Awọn ọmọ Naijiria ti sọrọ ninu eto idibo ipinlẹ Oyo ati ti ipinlẹ Osun, wọn si tun maa sọrọ ninu eto idibo Naijiria naa.

Nitori naa, ẹ ma bẹru pe bo ya awọn eeyan kan lati ita le ni ipa lori ohun to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ wa,’’ Makinde lo sọ bẹẹ.

Gomina ipinlẹ Oyo tun sọ pe esi ibo gomina Ondo ti yoo waye ni bii ọsẹ meji si asiko yii ni yoo sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ ninu eto idibo Naijiria lọdun 2027.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post