Bobrisky gba ìtúsílẹ̀ ní àhámọ́ EFCC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ EFCC ti agba beeli idris ‘Bobrisky’ Okuneye lẹyin to ni oun ko fun eyikeyi ninu oṣiṣẹ rẹ ni riba owo ti iye rẹ to miliọnu marundinlogun naira.
Inu ọkọ ofurufu to n lọ ilu Amsterdam ni EFCC ti mu afurasi naa ni papakọ ofurufu ilu Eko lọsẹ to kọja, lasiko ti wọn ni o n lọ siluu London.
Ni kete ti EFCC mu tan lo kede fun awọn ololufẹ rẹ pe wọn tun ti mu oun, ati pe oun farapa lasiko ti ajọ to n gbogun nti iwa ajẹbanu naa n mu oun.
O ni “Ẹyin ọmọ Naijiria ẹ gba mi o, EFCC ṣẹṣẹ fi ofin mu mi bayii ni o, mo farapa pupọ.”
Lẹyin naa ni wọn gbe lọ so olu ọọfisi ajọ naa to wa niluu Abuja nibi ti wọn ti fi ọrọ wa lẹnu wo lori ẹsun riba to fi kan awọn oṣiṣẹ ajọ naa.
Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe alẹ ọjọ Ẹti ni wọn fun Bobrisky ni beeli lẹyin to lọ ṣalaye ara rẹ ni ọọfisi wọn.
Iroyin ni Bobrisky sọ fun EFCC ni ọọfisi wọn pe irọ ni pe oun fun awọn oṣiṣẹ rẹ ni riba miliọnu marundinlogun naira.
Lóòótọ́ ni pé a tún ti mú Bobrisky – EFCC

Oríṣun àwòrán, Bobrisky
Ajọ EFCC ti fidi rẹ mulẹ pe awọn tun ti fi ṣikun ofin mu Idris ‘Bobrisky’ Okuneye.
Ṣaaju lawọn iroyin kan ti kọkọ gbode pe EFCC mu Bobrisky ni papakọ ofurufu ilu Eko lasiko to fẹ rinrinajo lọ soke okun.
Wayi o, agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale, ti sọ fun BBC pe lootọ ni awọn ti mu Bobrisky.
O ni “Alẹ Ọjọbọ ni a mu niluu Eko.”
Kilode ti EFCC tun gbe Bobrisky?
Ninu ọrọ ti EFCC sọ, kii ṣe pe wọn kan mọọmọ mu lati tẹ ẹtọ rẹ loju mọlẹ ni, amọ wọn mu nitori o ṣi ni ẹjọ lati jẹ lọdọ awọn.
Wọn ni awọn mu ko le wa kọ akọsilẹ nipa ẹsun gbigba riba to fi kan awọn kan lara oṣiṣẹ awọn.
Agbẹnusọ EFCC ni “A gbe lọ silu Abuja lati lọ koju awọn ọtẹlẹmuyẹ nipa ọrọ to sọ, a si nilo pe ko kọ akọsilẹ nipa ẹsun to fi kan wa.”
Bo tilẹ jẹ pe ko mẹnuba igba ti wọn yoo tu silẹ, Oyewale awọn yoo jọwọ rẹ ni kete to ba ti kọ akọsilẹ nipa ẹsun naa tan.
Lẹnu ọjọ mẹta yii ni ẹnu bẹrẹ si n kun Bobrisky lori oniruru ẹsun ibanilorukọjẹ.
Eyii to milẹ titi julọ ni ti Very Dark Man, lẹyin to gbe fọran ohun Bobrisky jade nibi to ti sọ pe oun fun awọn oṣiṣẹ EFCC ni riba, ati pe oun ko sun ọgba ẹwọn lẹyin idajọ ẹwọn ti ile ẹjọ ṣe fun oun.
Lẹyin ti ọrọ naa lu sita ni minisita fu ọrọ abẹle paṣẹ pe ki wọn bẹrẹ iwadii lori gbogbo ẹsun naa.
Lẹyin iwadii ọhun ni igbimọ oluwadii sọ pe lootọ ni Bobrisky lo akoko to yẹ ko lo lọgba ẹwọn ṣugbọn o jẹ awọn anfani kan ti ko tọ si gẹgẹ bii ẹlẹwọn.















