Lẹ́yìn ọdún méjìdínlọ́gọ́ta, ẹgbẹ́ òṣèlú míì borí ìbò ààrẹ ní Botswana

Awọn ọmọ ẹgbẹ UDC to n yọ ayọ aṣeyọri ẹgbẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn eeyan orilẹede Botswana ti pada lẹyin ẹgbẹ oṣelu Botswana Democratic Party (BDP), to ti n dari wọn lati ọdun 1966 ti wọn ti gba ominira.

Ọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla ọdun 2024 ni ayipada de, nigba ti awọn oludibo kọyin si BDP, ti wọn si dibo fun Umbrella for Democratic Change (UDC).

Koda, Aarẹ Botswana to n fipo silẹ, Mokgweetsi Masisi, ti gba pe oun ti padanu ipo naa.

Masisi ti pe oludije UDC lorii foonu, o si ki i ku oriire.

"Ẹgbẹ wa ti padanu lọtẹ yii, mo maa yẹba, mo si maa darapọ mọ ayipada tuntun yii."Aarẹ Masisi lo sọ bẹẹ.

Bakan naa lo rọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati gba alaafia laaye, ki wọn si duro ti ẹgbẹ UDC to bori.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ìṣẹ́ ati òṣì, airiṣẹ ṣe ati idaamu lo gba ilẹ kan ni gbogbo akoko iṣakoso ẹgbẹ BDP to ṣaa n bori ibo lati ọdun pipẹ sẹyin.

Bo tilẹ jẹ pe ilẹ to kun fun diamọndi alumọni ni Botswana, sibẹ, ọpọ araalu ni wọn ko ri jajẹ bi wọn ṣe sọ.

Aarẹ Masisi to n fipo silẹ yii, bẹrẹ ijọba tiẹ ni 2018

Kí ni àwọn aráàlú ń wí?

Tijo-tayọ lawọn eeyan fi jade ni olu ilu Botswana ti i ṣe Gaborone, wọn n yọ ayọ ayipada ijọba.

Ọkan ninu awọn araalu to ba ẹka iroyin Reuters sọrọ, Mpho Mogorosi, sọ pe:

" Mi o tiẹ ro o pe ayipada yii le ṣoju mi laye. Awọn BDP ti pẹ ju ninu ijọba, inu mi dun pe mo jẹ ọkan lara awọn to yọ wọn danu, ka le ri Botswana tuntun.’’

Bakan naa ni Kgoberego Nkawana, ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo MP ninu ẹgbẹ UDC, ṣalaye fun BBC pe ọpọ ọdọ ni ko niṣẹ lọwọ ni Botswana.

O ni bo tilẹ jẹ pe obitibiti okuta diamondi ati ibudo afẹ to n pawo wọle wa lorilẹede naa .

"Airiṣẹ ṣe pọ gan-an nibi, awọn eeyan n jiya nitori wọn o riṣẹ ṣe. O ba ni lọkan jẹ gan-an.’’ Nkawana lo ṣalaye bẹẹ.

Ààrẹ àdìbòyàn sọ̀rọ̀

Duma Boko ti yoo di aarẹ Botswana tuntun

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Duma Boko ti yoo di aarẹ Botswana tuntun

Aarẹ tuntun lati ẹgbẹ UDC ti ireti wa pe yoo gba ipo ni Botswana bayii, Duma Boko, fi ijọloju rẹ han pe oun jawe olubori.

Duma Boko sọ pe, ’’o jọ mi loju gan-an pẹlu onka ti mo ni.

‘’’Wọn ṣeun ti wọn pọn mi le. Mo ṣeleri fun wọn pe ohun to daa ju la maa ṣe fun wọn.’’

Ẹgbẹ UDC to n lewaju ti waa ṣeleri lati mu ọna ọrọ aje tuntun pọn, eyi ti yoo pese iṣẹ lọpọ yanturu fawọn eeyan orilẹede naa, ti yoo si ro wọn lagbara pẹlu.